Ẹ fopìn sí ìpànìyàn lemọ́lemọ́ fún ètùtù ọlà l’Ógùn – Dàpọ̀ Abíọ́dún

Ẹ fopìn sí ìpànìyàn lemọ́lemọ́ fún ètùtù ọlà l’Ógùn – Dàpọ̀ Abíọ́dún

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé ó ní n tí í bá kóówá mu láàgọ́ ara, bẹ́ ẹ̀ olójú ò ní-ín lajú ẹ̀ sílẹ̀,kítàlùbọ̀ ó yí wọ̀ ọ́.
Bí ìpànìyàn láti ṣòògùn owó ní ìpínlẹ̀ Ògùn se ń pọ̀ sí i, Gómìnà Dàpọ̀ Abíọ́dún ti késí àwọn oníṣègùn ìbílẹ̀ láti ran ìjọba lọ́wó fi dẹ́kun ìwà ìbàjẹ́ náà.

Gómìnà Abíọ́dún rawọ́ ẹ̀bẹ̀ yìí níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ẹgbẹ́ àwọn onísègùn ìbílẹ̀ níìpínlẹ̀ Ògùn, Alternate Medicine Board (OGAMB) ṣe pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ iléesẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà lórí ìlanilọ́yẹ tako ìwà ìpànìyàn.

Abíọ́dún wá bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà burúkú tí àwọn apànìyan ṣoògùn ọrọ̀ n se, táwọn èèyàn yókù ní Nàìjíríà sí ń fi ojú àìtọ́ wo ìpínlẹ̀ náà.

Gómìnà ní àsìkò ti tó láti gba ìpínlẹ̀ Ògùn kúrò lọ́wó àwọn olòògùn owó lọ́nà àti fún ìpínlẹ̀ Ògùn ni ojú titun.

Bákan náà ni Abíọ́dún rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn oníṣègùn àbáláyé láti ran ìjọba lọ́wọ́, kí wọ́n lè dẹ́kun ìwà ìbàjẹ náà.

Ó wá ṣèlérí pé òun yóó fọwọ́ sí ìwé-àṣẹ láti dá àyájọ́ ọjọ́ Ìsẹ̀se sílẹ̀ èyí tí yóó máa wáyé lọ́dọọdún gẹ́gẹ́ bí i ọjọ́ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún gbogbo àwọn oníṣẹ̀ṣe ní ìpínlẹ̀ náà.

Gómìnà ọ̀hún tún ṣèlérí pé ìjọba òun pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba tí ọ̀rọ̀ kan láti ṣètò Ilé-ẹ̀kọ́ gíga tí yóó mójútó ìdásílẹ̀ ṣíṣe òògùn ìbílẹ̀ nìpínlẹ̀ Ògùn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here