Ọwọ́ tún tẹ àwọn afurasí ajínigbé ní Kwara náà

Oga Olopaa yan-an-yan-an, Alkali Bba

Ọwọ́ tún tẹ àwọn afurasí ajínigbé ní Kwara náà

Fẹ́mi Akínṣọlá
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ti fi ṣìkún òfin gbé àwọn afurasí ajínigbé mẹ́ta èyí tó ń yọ àwọn agbègbè kan ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Kogi àti Kwara lẹ́nu.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kwara, Paul Odama nígbà tó ń fojú àwọn afurasí náà hàn ní ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kejìlá, ọdún 2022 ṣàlàyé pé ní ìlú Oro-Ago ní ìjọba ìbílẹ̀ Ifelodun ní àwọn ti nawọ́ gán àwọn afurasí náà.

Odama ní ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kọkànlá, ọdún 2022 ni àwọn ènìyàn méjì kan, Shina Luke Abiodun àti ẹnìkan kó sọ́wọ́ àwọn ajínigbé ní agbègbè Eruku ní ìjọba ìbílẹ̀ Ekiti nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti Egbe ní ìpínlẹ̀ Kogi.

Ó ní àwọn ajínigbé náà dáná ìbọn yá àwọn ènìyàn yìí ṣùgbọ́n orí kó wọn yọ tó sì jẹ́ wí pé wọ́n farapa lásán ni tí wọ́n sì fi ẹsẹ̀ fẹ.

Ó fi kun pé nígbà tí àwọn ènìyàn náà sá dé ibi tí àwọn ọlọ́pàá wà ní àwọn lọ sí ibi tí ìkọlù náà ti wáyé tí wọ́n sì rí fóònù Tecno kan nílẹ̀.

“Fóònù yìí ni àwọn ọlọ́pàá lò láti fi ṣèwádìí ohun tó ṣẹlẹ̀ tí wọ́n sì ṣe àwárí rẹ̀ pé Oro-Ago ni àwọn ajínigbé náà wà.”

“Nígbà tí à ń ṣe ìwádìí ni awọn afurasí náà jẹ́wọ́ wípé àwọn ni àwọn ti ń da agbègbè náà láàmú.”

“Ìwádìí tún fi hàn pé àwọn ni wọ́n jí bàbá àti ọmọ kan gbé tí wọ́n sì gba mílíọ̀nù mẹ́fà kí wọ́n tó túwọn sílẹ̀.”

Odama ṣàlàyé pé àwọn afurasí náà jẹ́wọ́ wí pé àwọn ni àwọn pa òṣìṣẹ́ NSCDC kan, Segun Ayegbulu tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Ekiti.

Ó fi kun pé lára àwọn nǹkan tí àwọn rígbá lọ́wọ́ wọn ni ìbọn méjì àti fóònù méjì.

Bákan náà ló ni iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́ láti nawọ́ gán àwọn ènìyàn yòókù tí wọ́n jọ ń ṣe iṣẹ́ ibi wọn.
Yàtọ̀ sí àwọn wọ́nyí, ọwọ́ ṣìnkú òfin ti tẹ àwọn afurasí ajínigbé méjì mìíràn ní agbègbè Oke-Ode, ìjọba Ifolodun ìpínlẹ̀ Kwara.

Paul Odama sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kejìlá ni ìròyìn kan àwọn lára wí pé àwọn ajínigbé jí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún kan gbné ní òpópónà Share sí Oke-Ode.

Ó ní ìwádìí àwọn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Garuba Abubakar tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Elero ti ìlú Lokongoma àti Abubakar Adam ló wà nídìí ìjínigbé ọ̀hún.

Ó ṣàlàyé pé àwọn afurasí náà jẹ́wọ́ ọ̀gá àwọn tó gbà ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀ta náírà owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ ẹbí àwọn ọmọ tí àwọn jí gbé náà ti na pápá bora.

Bákan náà ní wọ́n ní ni ìbọn tí àwọn máa ń lo láti fi ṣọṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá wá sọ àrídájú rẹ̀ pé gbogbo ìgbìyànjú ni àwọn ń sà láti ri dájú pé àwọn nawọ́ gán ọkùnrin náà.

Odama wá ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ọ̀daràn láti pọ̀ sókè rajà nítorí kò sí ààyè fún àwọn oníṣẹ́ ibi ní ìpínlẹ̀ Kwara.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here