Ọọ̀ni Ilé Ifẹ̀, Adéyẹyè Ògúnwùsì sọ ìdí tó fi fẹ́ ìyàwó púpọ̀

Ọọ̀ni Ilé Ifẹ̀, Adéyẹyè Ògúnwùsì sọ ìdí tó fi fẹ́ ìyàwó púpọ̀

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ọọ̀ni ìlú Ilé Ifẹ̀, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, Ọ̀jájá kejì sọ pé òun kò dédé fẹ́ ìyàwó púpọ̀ láti kó obìnrin jọ làáfin bí àwọn ẹni ìṣaájú gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe rò.

Ninu ọrọ to sọ nibi eto kan to waye lati fi dupẹ fun awọn oṣiṣẹ aafin rẹ, iyẹn ile Oodua, gẹgẹ bi ara ayẹyẹ fun sisami ọdun rẹ lori itẹ ni Ọọni Ogunwusi ti ṣalaye ọrọ yii.

Ọọni ile ifẹ ni kii ṣe lati figagbaga loun tori ẹ fẹ awọn iyawo pupọ bi ko ṣe lati tubọ mu ki ogo ilẹ adulawọ goke si.
Ọlọrun fi awọn iyawo rere ti wọn jẹ ọrẹ tootọ ati alabarin rere ta mi lọrẹ. Eredi fifẹ ọpọlọpọ Olori kii ṣe nitori orogun tabi figagbaga, bikoṣe lati fi aaye silẹ fun igbeleke ogo adulawọ lọna ati lee ṣiṣẹ pupọ sii lọna ati maa ṣe iranwọ to yẹ fun ọmọniyan nipasẹ awọn olori mi ti awọn pẹlu ko ṣe fi ọwọ rọ sẹyin. Akẹkọjade awọn ile ẹkọ giga fasiti ni Naijiria ati loke okun ni wọn.

“Mo ni dokita niyawo, mo ni agbẹjọro niyawo, mo ni onimọ ẹrọ nipa alumọni inu omi ati aṣaṣọ lẹṣọ niyawo, mo ni akẹkọọjade fasiti Cambridge ati Harvard niyawo, mo ni oluṣiro owo to gba iwe aṣẹ nilẹ Gẹẹsi niyawo ati bẹẹbẹ lọ.

“Yatọ si pe awọn Olori mi rẹwa pupọ pupọ, ọpọlọ wọn gan ji pepe, wọn kawe doju ami, wọn ri ita, wọn si kọ wọn ,wọn si tun gbẹkọ. Ki wa lo de ti emi ko ni dupẹ lọwọ Eledumare?”

Ni oṣu kẹsan an ni Ọọni fẹ akọkọ ninu ohun ti yoo di eto igbeyawo ni ṣisẹ-n-tẹle eyi to ṣi duro lori mẹfa bayii.

Ọpọ lo n woye igbesẹ ti Arole Oodua yoo gbe lẹyin ti Naomi Silẹkunọla kede lori ayelujara loṣu kejila ọdun 2021 pe oun ti fi Ọbalaye naa silẹ.

Amọṣa lọjọ kẹfa oṣu kẹsan an ọdun 2022 ni ọọni gbe Olori Mariam Ogunwusi niyawo gẹgẹ bii yeyelua tuntun. Lẹyin eyi ni Olori Elizabeth Ọpẹoluwa, olori Tobi, Olori Ashley, Olori Ronkẹ ati Temitọpẹ wọle si aafin Oodua ni ṣisẹ-n-tẹle.
Ọọni Ogunwusi ni gbogbo ohun ti o ku fun oun lati maa ṣe bayii ni lati maa ṣeto iranwọ fun awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ.

“Gbogbo ohun ti mo fẹ da nile aye ni mo ti da bayii. Ohun to ku fun mi ko ju lati maa gbe awọn eeyan ga, ki n si maa ṣe iranwọ to yẹ fun awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ wa ati ṣiṣe iranwọ fun awọn ọdọ ilẹ afirika lati maa dagba sii ni koriya. Eduwa si ti fi awọn obinrin to n gbaruku ti iran mi ti mi. Ki lo de ti n o ni dupẹ lọwọ Ọlọrun Ọba?”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here