Adedoyin ló ní kí ń sọ fún ọlọ́pàá pé Timothy Adegoke kò sun sílé ìtura Hilton – Ẹlẹ́rìí

Adedoyin ló ní kí ń sọ fún ọlọ́pàá pé Timothy Adegoke kò sun sílé ìtura Hilton – Ẹlẹ́rìí

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ni bí ọ̀rọ̀ ńlá ò bá tíì tán, èèyàn ńlá ò ní-ín tí ì sinmi àròyé é ṣe.
Ìgbẹ́jọ́ tún tẹ̀síwájú lọ́jọ́ Ẹtì nílé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Ọ̀sun, tó wà nílùú Òṣogbo láti tanná wádìí ikú tó pa Timothy Adégòkè.

Lásìkò ìgbẹ́jọ́ náà sìi ni ikọ̀ olùjẹ́jọ́ ti kó àwọn afurasí jáde láti wá sọ tẹnu wọn lórí ohun tí wọ́n mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.

Nibi igbẹjọ naa si ni afurasi kan to jẹ oṣiṣẹ ile itura naa, arabinrin Adedeji Adesola ti tu kẹkẹ ọrọ silẹ nipa ohun to mọ lori iku Timothy Adegoke.

Adesola ni oludasilẹ ile itura naa, Ọmọọba Rahmon Adedoyin lo sọ fun oun nipa idahun ti oun yoo fun awọn ọlọpaa to wa se iwadii Timothy to di awati.

Obinrin naa, tii se osisẹ nile itura Hilton Hotels nilu Ile Ife, to jẹ ti Adedoyin fikun pe oludasilẹ ile itura naa lo sọ fun oun pe ki oun sọ fawọn ọlọpaa pe Timothy Adegoke ko wa si ile itura naa lọjọ to de si ibẹ.

Nigba to n dahun si ibeere lọwọ awọn agbẹjọro, Adesola sọ fun adajọ pe Rahmon Adedoyin ati ọmọ rẹ Roheem, lo kọ oun ni ọrọ ti oun yoo sọ naa.

O ni awọn mejeeji lo pe oun wa si ilegbe wọn, ti wọn si sọ pe ki oun sọ fun awọn ọlọpaa pe Timothy Adegoke ko de si ile itura naa rara ati rara.

Osisẹ-binrin naa ni Roheem Adedoyin tun fun oun ni iwe miran dipo eyi to wa nilẹ tẹlẹ, ti orukọ Timothy Adegoke wa.

O ni iwe akọsilẹ tuntun to fun oun naa lo ni ki oun fi orukọ ẹlomiran rọpo orukọ Timothy, ki oun si fun awọn ọlọpaa ti wọn ba ti beere iwe akọsilẹ orukọ awọn alejo to sun sile itura naa.
keji ọdun 2023
Wayi o, ile ẹjọ giga naa ti sun igbẹjọ iwadi iku to pa Timothy Adegoke siwaju di ọdun to n bọ.

Adajọ Adepele Ojo to n gbọ ẹjọ ọhun lo kede bẹẹ lẹyin ti awọn agbẹjọro Olupejọ ati Olujẹjọ bere ibeere lọwọ awọn ẹlẹrii to yọju si ileẹjọ lọjọ Ẹti

Adajọ Ojo ni igbẹjọ naa yoo tẹsiwaju lọjọ keji oṣu keji, ọdun 2023.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here