Obasanjo àti Adebanjọ ní kò sí gìrì lórí olùdíje táwọn ń tẹ̀lé

Obasanjo àti Adebanjọ ní kò sí gìrì lórí olùdíje táwọn ń tẹ̀lé

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ní èyí wùmí, èyí ò wù ọ́, ni kìí jẹ́ á pawọ́ pọ̀ fẹ́bìnrin. Ààrẹ Orílẹ̀ yìí nígbà kan rí, Olóyè Olúségun Obásanjọ́ tún ti fọwọ́ gbáyà nípa olùdíje sípò Ààrẹ tó ń se àtìlẹyin fún láti borí ìbò lọ́dún 2023.

Obasanjo sisọ loju ọrọ yii ninu fidio to jade sita lasiko to wa ni ibujoko ẹgbẹ Ohaneze Ndigbo to wa ni Enugu.

Oloye Obasanjo ati eekan kan ninu ẹgbẹ Afenifere, Alagba Ayo Adebanjo pẹlu Peter Obi si ni wọn se abẹwo solu ile ẹgbẹ Ohaneze Ndigbo naa.

Obasanjo ati Adebanjo si ni wọn se abẹwo si Enugu lati se abẹwo ibanikẹdun lori iku Minisita feto irina ofurufu ni saa oselu alagbada akọkọ, Mbazulike Amaechi.

Aarẹ tẹlẹ naa, to wọ asọ ibilẹ ẹya igbo, ni ẹnu awọn ọmọ Naijiria ti n kun saaju pe Peter Obi, tii se oludije aarẹ fẹgbẹ iselu Labour, lo n se atilẹyin fun lati bori ibo aarẹ lọdun 2023.

Bẹẹ ni Olusegun Obasanjo wa fọwọ gbaya ninu akọtun fidio to jade sita naa pe ko si ẹnikẹni to le halẹ mọ oun lori oludije aarẹ ti oun n satilẹyin fun.

Obasanjo ni “Mo ti ta ẹjẹ mi silẹ fun isọkan orilẹede Naijiria, ti mo si tun ti se ẹwọn ri, nitori naa, ko si ẹnikẹni to to bẹẹ lati dun mahuru-mahuru mọ oun lori oludije ti oun ba pọn lẹyin rẹ.

“Ki wa ni wọn fẹ maa fi dẹru ba mi? Ohun kan soso ti ẹgbọn mi, Ayo Adebanjo ko tii se ni tiwọn ni pe ki wọn ta ẹjẹ wọn silẹ amọ awọn naa ti lọ se ẹwọn ri, a si fi itan naa silẹ di igba mii.”

Oloye Obasanjo wa woye pe isoro orilẹede yii kọja ti ẹlẹyamẹya, gbogbo Naijiria ni ọrọ yii kan.

Aarẹ Naijiria tẹlẹ naa wa n fi ika hanu pe aisi asaaju to ni iwa rere ti yoo tu ọkọ orilẹede yii gan ni isoro kan gboogi, to n wa ọkọ orilẹede yii sẹyin.

O fikun pe ti oun ba gbe ọwọ le eeyan kan lori, o tumọ si pe oun n se afiwe onitọun pẹlu awọn ẹlomiran ni.

O ni oun ti ri pe ọpọ anfaani wa lara onitọun ni, eyi ti yoo se orilẹede Naijiria loore.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here