Ìléeṣẹ́ tó ń rí sí ìwé ìrìnnà ní Nàìjíríà ti gbà láti máa ṣí ní Sátidé

Ìléeṣẹ́ tó ń rí sí ìwé ìrìnnà ní Nàìjíríà ti gbà láti máa ṣí ní Sátidé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iléeṣẹ́ tó n ríísí ètò ìwé ìrìnnà lórílẹ̀ èdè yìí Naijiria, NIS ti fún àwọn iléeṣẹ́ wọn ní àṣẹ láti máa ṣí ní Ọjọ́ Sátidé.

Adarí iléeṣẹ́ Nigeria Immigration Service(NIS) ló fi àṣẹ ọ̀hún léde nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi léde.

Níbẹ̀ náà ni wọ́n ti ṣàlàyé pé ìgbéṣẹ̀ ọ̀hún yóó fún àwọn èèyàn ní àǹfààní láti gba ìwé ìrìnnà wọn ní àsìkò.

‘’Ìgbìyànjú wa ni pé kì ìrọọ̀rùn wà fún àwọn ènìyàn láti gba ìwé ìrìnnà wọn tó ti wà ní ìkáwọ́ wa láti ìgbà pípẹ́.

‘’A rí i pé ìdíwọ́ wà láti ìgbà tí àrùn-un ajàmámààlà n nì , kòrónáfairọ̀ọ̀sì ti gbòde kan, eléyìí tó fa ìṣéde nígbà náà lọ́hù-ún, tí a kò sì ráàyè ṣiṣẹ́ dà bí alárà, èyí mú ìdíwọ́ bá àwọn èèyàn tó yẹ kí wọ́n rìrìnàjò tí wọn kò sì rí ìwé ìrìnnà an wọn gbà.’’

‘’Ìdánilójú wà pé tí àwọn òṣìṣẹ́ wa bá bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ ní Sátidé yóó mù-ún ìrrọ̀rùn bá gbígba ìwé ìrìnnà àwọn aráàlú.’’

Bákan náà ni wọ́n kéde pé àwọn ti gbé àwọn adarí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wọn méjì ní ìpínlẹ̀ Ondo àti Èkìtì kí iṣẹ́ lè tẹ̀síwájú ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here