Yóò nira fún APC láti borí Makinde ní Oyo àmọ́ … – El-Rufai

Yóò nira fún APC láti borí Makinde ní Oyo àmọ́ … – El-Rufai

Ọrẹ Òtítọ́jù

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kàdúná, Nasir El-Rufai ti ní APC ní láti ṣán ṣòkòtò o wọn le bí wọ́n yóó bá fi ẹ̀yìn-in Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó n tukọ̀ lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP janlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ rẹ̀.

Loju ọpọlọpọ, eyi da bii ki eeyan ni ẹnikan ri ootọ nilẹ ti ko si fi bo rara koda ko pa oun gan lara lọna kan tabi omiiran.

“Yoo nira fun ẹgbẹ oṣelu APC lati bori Gomina Seyi Makinde ni ipinlẹ Ọyọ.”

Nibi akanṣe eto idagbere fun oludari agba ileeṣẹ to n ri si eto ọgbin alarobọ, Nteranya Sangiga eyi to waye nilu Ibadan ni El-Rufai ti sọ ọrọ naa lọjọ Ẹti.

El-Rufai ranti bi oun ati Makinde nibi ipade igbimọ alaṣẹ ṣe n fa ọrọ boya ki wọn fi awọn ipinlẹ sinu isede Covid19.

“Lẹyin itakurọsọ yii, mo pada lọ si ipinlẹ temi mo si lọ kede isede. Seyi pada lọ si ipinlẹ tirẹ o si lọ ṣe nnkan ti o pe ni “isede oniha kan”, ṣugbọn ni ti ara rẹ, o se ara rẹ mọle toripe o lugbadi arun Covid.”

El-Rufai ni ẹwa to wa ninu Naijiria ni oniruuru aṣa ati iṣe eniyan lọtọọtọ, o ni oun ṣe nnkan ti oun lero pe o dara, bẹẹ si ni oun naa ṣe nnkan to dara fun ipinlẹ rẹ.

El-Rufai ṣapejuwe Seyi Makinde ati Akinwumi Adesina ti Banki idagbasoke ilẹ Afirika gẹgẹ akinkanju to n fi ipa rere silẹ to si ni wọn n fun awọn ọmọ Afirika ni ireti pe Afirika lee di ohun to ba fẹ da to ba ṣiṣẹ karakara.

Nigba to n sọrọ Gomina Seyi Makinde ni nnkan aladun ni fun oun lati sisẹ pọ pẹlu ajọ IITA lori oniruuru iṣẹ akanṣe lati mu ọrọ aje ipinlẹ naa buyaari sii nipasẹ awọn iṣẹ akanṣe ati lati gba awọn ọdọ nimọran ki wọn ṣamulo ẹka naa.

Seyi Makinde naa fi lede pe ọpọlọpọ lo jẹ ẹkọ latara akẹgbẹ rẹ Gomina El-Rufai to ṣapejuwe gẹgẹ bii eeyan nla to ni oye ati ifarajin pẹlu ipo adari rẹ.

Lẹyin to sọrọ nipa oniruuru ibadọrẹ ati ajọṣepọ to laami laaka to ti waye laarin oun ati El-Rufai, Seyi bọ sori ọrọ idibo.

“Asiko eto idibo la wa yii, mo si fẹ lo anfani yii lati sọ fun awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ pe bi wọn ba fun mi ni anfani mii si lati sin wọn, a o gbe akanṣe eto “Start Them Early” lọ sawọn ile ẹkọ mii nipinlẹ Ọyọ.”

Lara awọn ilumọọka mii to wa nibi eto ti Makinde ati El-Rufai ti pade yii ni Akinwumi Adesina, Aarẹ Banki idagbasoke ilẹ Afirikav(AFDB); Rashidi Ladoja, gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, ati aṣoju Aarẹ nigbakan ri ,Olusegun Obasanjo

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here