Ìjọba bó ẹgba sídìí obìnrin mẹ́ta, ọkùnrin mẹ́sàn-án tí wọ́n ká ẹ̀sùn àgbèrè mọ́ lọ́wọ́

Ìjọba bó ẹgba sídìí obìnrin mẹ́ta, ọkùnrin mẹ́sàn-án tí wọ́n ká ẹ̀sùn àgbèrè mọ́ lọ́wọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé n tí ò dá a ò lórúkọ méjì,bẹ́ ẹ̀ ìlú tí ó bá ń tẹ̀lé òfin, dájú sáká,ẹlẹ́ṣẹ̀ ẹ bẹ̀ kò ní-ín lọ láì jìyà.
Èyí ló díá fún bí obìnrin mẹ́ta àti ọkùnrin mẹ́sàn án kan ṣe rí ìyà he lọ́wọ́ ìjọba Taiban, bí wọ́n ṣe dín dùǹdú ìyà fún wọn níwájú ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó wá wo bọ́ọ̀lù lórí i pápá ní orílẹ̀-èdè Afghanistan.

Iléeṣẹ́ agbófinró ní orílẹ̀-èdè ọ̀hún sọ fún iléeṣẹ́ akọ̀ròyìn pé àwọn ẹgbẹ́ náà jẹ̀bi ẹ̀sùn àgbèrè síse, olè jíjà àti ìbá ọkùnrin lòpọ̀.

Ìgbà kejì rè é tí ìjọba Taliban yóó má a lu àwọn ẹlẹ́sẹ ní ìta gbangba.

Omar Mansoor Mujahid, agbẹnusọ ìjọba ọ̀hún ní àwọn obìnrin tó wà lára àwọn ọ̀daràn ni àwọn ti tú sílẹ̀ lẹ́yìn tì wọ́n jẹ̀yà ẹ̀ṣẹ̀ ẹ wọn sùgbọ́n ,díẹ̀ lára àwọn ọkùnrin ọ̀hún sì wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.

Ó ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹlẹ́sẹ̀ náà jẹ ẹgba tó mọ́kànlélógún sí mọ́kàndínlógójì. Ó ní ẹni tó jẹ jù ni ẹni tó jẹ mọ́kàndínlógójì.

Ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni èèyàn mọ́kàndínlógún mìíràn jẹ irúfẹ́ ìyà yìí ní agbègbè Takhar ní àríwá orílẹ̀-èdè Afghanistan.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here