Home Blog Page 90

Davido di olórin Afrika àkó̩kó̩ láti ko̩rin níbi ife e̩ye̩ PFA

Davido di olórin Afrika àkó̩kó̩ láti ko̩rin níbi ife e̩ye̩ PFA

Mary Fágbohùn

Gbajumo olorin Naijiria, David Adeleke, ti a mo si Davido, ni ale ojo Isegun ti di olorin Afrika akoko ti yoo korin nibi ife eye apapo egbe awon agbaboolu (Professional Footballers’ Association) ni England.

Olorin ‘Unavailable’ naa korin saaju ki won to bere ikede ife eye nla naa ni gbongan Lowry Theatre ni Manchester.

O lo si ori Twitter re ni Ojo’ru lati fi adun ere ti o ni itan naa han.

O wi pe, “E se @PFA fun anfaani ti kii se lati wa nibi eto naa nikan sugbon lati korin ni ibi ayeye nla naa. Orin ati ere idaraya ti se opolopo nnkan nla papo ati pe a si fi eyi han ni ale ana! Ibi to kan Dubai @cocacolaarena.”

E ranti pe Davido korin nibi asekagba ife eye agbaye (FIFA World Cup) ni Qatar ni odun to koja.

Fela fún àwo̩n olórin Naijiria ní ojú awé̩ tó dára lágbàáyé – Olorin, 9ice

Fela fún àwo̩n olórin Naijiria ní ojú awé̩ tó dára lágbàáyé – Olorin, 9ice

Mary Fágbohùn

Gbajumo olorin, Alexander Adegbola Akande, ti a mo si 9ice, ti so pe oloogbe ti o da orin takasufe sile, Fela Anikulapo-Kuti fun awon olorin Naijiria ni oju awe lati safihan ebun won si gbogbo agbaye.

Olorin ‘Gongo Aso’ naa so eyi ninu iforo-wani-lenu-wo laipe yi pelu Sis Project Studios.

9ice wi pe, “Fela Anikulapo-Kuti fun wa ni oju awe eyi to gbe orin takasufee goke. A gbiyanju lati se eya orin Afrika. A gbiyanju lati se orin takasufee. A gbiyanju lati se eyi to ni orisiirisii oruko. Sugbon Baba [Fela] ti fun wa ni nnkan tele ti gbogbo aye da mo.

“Orin takasufee ko mi ni opolopo nnkan. King Sunny Ade, Ebenezer Obey, ati Fela Anikulapo-Kuti je baba nla wa. Inu mi si dun lati wa laye lati se bii ti won tabi se nnkan ti won se.”

2Baba sàfihàn ìfé̩ re̩ láti da olùsó̩àgùntàn pè̩lú orúko̩ ilé ìjó̩sìn

2Baba sàfihàn ìfé̩ re̩ láti da olùsó̩àgùntàn pè̩lú orúko̩ ilé ìjó̩sìn

Mary Fágbohùn

Akoni olorin Naijiria, Innocent Ujah Idibia, ti a mo si 2Baba, ti safihan ife lati di alufaa.

Eni odun metadinlaadota naa so pe nigba miran o maa se oun bii pe ki oun da ile ijosin sile.

O ni oruko ile ijosin naa ni oun yoo pe ni Ona taara lo si Orun ti agbaye ijo Olorun (Straight To Heaven International Church of God Nigeria Limited, STHICOGNL).

Baba omo meje naa safihan eyi ninu fonran ifiranse to fi lede ni oju awe Instagram laipe.

O wi pe, “O n se mi bii pe ki n da ile ijosin sile. Ona taara lo si Orun ti agbaye ijo Olorun, (STHICOGNL). Straight To Heaven International Church of God Nigeria Limited”.

Mo paró̩ ní ilé-e̩jó̩ àti àgó̩ o̩ló̩pàá – Burna Boy

Mo paró̩ ní ilé-e̩jó̩ àti àgó̩ o̩ló̩pàá – Burna Boy

Mary Fágbohùn

Olorin Naijiria olugbafe eye Grammy, Damini Ebunoluwa Ogulu, ti a mo si Burna Boy, ti gba pe oun paro ni ile ejo ati ni ago olopaa ni opo igba.

Eni to n pe ara re ni ‘African Giant’ gba eyi nigba to n soro nipa ojo iwaju re ti ko han kedere.

O ni oun ko paro ri yato si “Ile-ejo ati ago olopaa.”

Lori itan Instagram re, Burna Boy ko o pe, “Igba ti mo paro ri ni igba ti mo wa ni ile-ejo ati ago olopaa.

“Ti e o ba feran mi, Mi o feran yin ju bi e o se feran mi lo. E o le bori.”

 

Tekno ló sè̩dá orin tàkasúfèé – Koffi

Tekno ló sè̩dá orin tàkasúfèé – Koffi

Mary Fágbohùn

Aderinposonu Naijiria, Koffi Idowu Nuel, ti a mo si Koffi, ti so pe olorin, Tekno lo seda orin takasufee.

O ni orin takasufee ko le e koja si ile okeere di igba ti Tekno se afikun “apeere ati agbesoke” re, o tenu moo pe o [Tekno] se agbejade orin Davido ti gbogbo eniyan gbo ‘IF’ eyi to je “orin takasufe akoko ti yoo lo kaakiri agbaye”.

Irawo alawada naa so pe amo sa, Tekno, “di apati” nigba ti aisan de ba.

Koffi so eyi ninu iforo-wani-lenu-wo to se laipe pelu mohunmaworan Galaxy TV.

“Tekno ni okunrin to seda orin takasufee. E na mi, e ba mi ja, maa se atileyin re dopin.

“Saaju, orin takasufe ko le koja si ile okeere, gbogbo won [olorin] kan n gbiyanju lati wa [iro ohun to dara]. Sugbon e ri awon apeere iro ohun yii ati agbesoke, Tekno lo se awari re.

“Oun lo mu ‘Pana’ wa ati pe o n se fonran to dara fun won, gbogbo eniyan wa ri pe, ‘O dara.’ Leyin eyi o gbe le Davido lowo. ‘If’ ati ‘Fall’ lati owo Davido, Tekno lo seda re [ilu re], awon ni olorin [takasufer] meji to koko lo si agbaye niyi.

“Leyin naa o [Tekno] ni okunrin kan naa nigba ti ko le se nnkan re, to jowo ‘Buga.’ O ti ni ilowosi labele ni opolopo ona. Sugbon nitori aisan re ti ko le fi ise re si ori ayelujara, won paati,” ni o so.

Ó lágbára o! Wọ́n bá òkú ọ̀gá tó ni òtẹ́ẹ̀lì “Water View”, ninu yara kan n’llọrin

Ó lágbára o! Wọ́n bá òkú ọ̀gá tó ni òtẹ́ẹ̀lì “Water View”, ninu yara kan n’llọrin

Fẹ́mi Akínṣọlá

Hùn! Ògédé ẹni Ọlọ́run bá pamọ́ nìkan ló yọ lọ́wọ́ ewu.
Títí di àsìkò yìí , kò tí ì sẹ́ni tó mọ ohun tó ṣokùnfà ikú Adeniyi Ojo, ọga olotẹẹli kan tí wọ́n ń pè ní Water View, tó wà lágbègbé GRA, nílùú Ìlọrin, ní ìpínlẹ̀ Kwara. Níṣe ni wọ́n kàn bá òkú rẹ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn yàrá òtẹ́ẹ̀lì rẹ̀, láì mọ irú ikú tó pa á.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara fi ṣọwọ́ sáwọn akọ̀ròyìn lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án yìí, ló ti fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, ó ní ọkùnrin kan, Kẹhinde Ọlaṣẹinde, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ òtẹ́ẹ̀lì náà ló mú ẹ̀sùn wá sí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá pé àwọn rí òkú Olùdásílẹ̀ àti alákòóso iléètura Water View, nínú ọ̀kan nínú àwọn yàrá òtẹ́ẹ̀lì ọ̀hún, táwọn kò sì mọ irú ikú tó pa á.

Ajayi ní àwọn ti gbé ọkùnrin náà lọ sí iléèwòsàn, tí wọ́n sì ti fìdí ẹ múlẹ̀ pé ó ti kú. Ó fi kún un pé wọ́n ti gbé òkú olóògbé yìí lọ sí yàrá ìgbókùú-sí fún àyẹ̀wò láti mọ irú ikú tó pa á.

Ó ní Kọmísánnà ọlọ́pàá ní Kwara, CP Victor Ọlaiya, ti pàṣẹ kí ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí ikú òjìji tó pa Adeniyi ní kíá.

Àádọ́ta mílíọ̀nù náírà ni àwọn tó jí akọrin wa gbé n béèrè fún – ìjọ CAC

Àádọ́ta mílíọ̀nù náírà ni àwọn tó jí akọrin wa gbé n béèrè fún – ìjọ CAC

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ní ọ̀kánjúà ń dà
gbà, ọgbọ́n inú rẹ̀ ń rewájú.
Àwọn ọmọ ìjọ CAC Oke Igan nílùú Akure tó jẹ́ olú-ìlú ìpínlẹ̀ Òǹdó ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ádùrá ní kíkan látàrí àwọn akọrin ìjọ ọ̀hún táwọn ajínigbé kó lọ.

Ohun tí a gbọ́ ni pé àwọn ọmọ ìjọ ọ̀hún láàárọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta péjú láti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run lórí ìtúsílẹ̀ àwọn tí wọ́n jí gbé ọ̀hún.

Láti ìta ilé ìjọsìn náà ni ariwo ádùrá náà ti ń dun lákọlákọ.

Adarí ìjọ náà, àlùfáà Benjamin Akanmu, to jẹ alakoso ijọ CAC ni ẹkun Odubanjo wi pe, ilu Ifọn ni awọn akọrin naa n lọ fun aṣalẹ onigbagbọ fun eto isinku baba to bi aladura ijọ wọn to doloogbe.

Ó ṣàlàyé pé ní ọjọ́ Ẹtì ni wọ́n gbéra kúrò nílùú Akure tó sì yẹ kí wọn padà dé lọjọ Àbámẹ́ta lẹyìn ìsìnkú.

“Ní nǹkan bíi aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ẹtì ni ẹnìkan pè mí pé òun rí ọkọ̀ ìjọ wa lẹ́bàá ọ̀nà lágbègbè Ẹlẹgbẹka tí kò sì sí ẹnikẹ́ni nínú rẹ̀.

Ẹ kó ìbọn yín lọ síléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fún àtùngbéyẹ̀wò –Ọ̀gá ọlọ́pàá

Ẹ kó ìbọn yín lọ síléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fún àtùngbéyẹ̀wò –Ọ̀gá ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọn ní tojútìyẹ́ ni àparò fi í ríran.Kómi ó má ba à wá tẹ̀yìn wọ̀gbín lẹ́nu látàrí bí àwọn ẹrúukú ṣe ń kó oríṣìíríṣìí ìbọn àtàwọn ohun ìjà olóró pamọ́ sílé, ọgá àgbà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, CP Adebọla Hamzat, ti kìlọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà láti tètè lọ jọ̀wọ́ àwọn nǹkan ìjà olóró náà sílẹ̀ fáwọn agbófinró tàbí kí òun tẹsẹ̀ bọ ṣòkòtò kan náà pẹ̀lú wọn.

Nígbà tí Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ń lu aago ìkìlọ̀ náà ṣétí àwọn tọ́rọ̀ ọ̀hún kan lórúkọ ọgá àgbà ọlọ́pàá, ló ti sọ pé ọ̀rọ̀ yìí kò yọ àwọn tó ní ìwé àṣẹ fún ìbọn wọn sílẹ̀.

Ìyẹn ni pé bí àwọn tó ń lo ìbọn lọ́nà àìbófin mu gbọdọ̀ ṣe jọ̀wó ẹ̀ sílẹ̀, káwọn tó ń lò ó lọ́nà tó bófin mu náà fi tiwọn pàápàá sílẹ̀ fún àyẹ̀wò àti àtúnṣe ìwé àṣẹ wọn.

Oṣifẹsọ ní èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin ọdún 2004, èyí

tó de àwọn ohun ìjà olóró, ìdí nìyẹn tí òun fi rọ àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí irú ohun ìjà báyìí bá wà níkàáwọ́ wọn láti kó wọn lọ sí téṣàn ọlọ́pàá tó bá wà nítòsí wọn, àti pé ìgbésẹ̀ náà kò ná wọn lówó kankan.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, “Ìkéde tí CP Hamzat ṣe yìí wáyé lẹ́yìn tí Ọgá àgbà ọlọ́pàá lórílẹ̀-èdè yìí, AIGP Kayọde Ẹgbẹtokun, pàṣẹ pé kí àwọn ọlọ́pàá káàkiri ìpínlẹ̀ gbogbo lórílẹ̀-èdè yìí wá gbogbo ọ̀nà láti paná ìwà ọ̀daràn nílẹ̀ yìí, èyí tó ń wáyé látàrí bí àwọn nǹkan ìjà olóró ṣe pọ̀ láwùjọ.

Àtẹ̀jáde ọ̀hún ṣàlàyé pé èyí kò yọ àwọn tó láṣẹ láti ní irú àwọn ohun ìjà yìí lọ́wọ́, kí wọ́n baà lè ṣàtúngbéyẹ̀wò lánsẹ́nsì wọn.

Ó wáá rọ àwọn aráàlú tó bá ní ohunkóhun tí wọ́n fẹ́ ẹ́ fi tó àwọn agbófinró létí láti pe ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá sórí àwọn nọ́mbà wọ̀nyí:0705549513 àti 08081768614 pẹ̀lú nọ́mbà ètò ààbò ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ìyẹn 615.

Ó gbọdọ̀ tọrọ àforíjìn – Afẹ́nifẹ́re sí Ọbásanjọ́

Ó gbọdọ̀ tọrọ àforíjìn – Afẹ́nifẹ́re sí Ọbásanjọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní tẹni n tẹni àkísà ni tààtàn ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re ilẹ̀ Yorùbá ti korò ojú sí Ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí, Olóyè olusegun Obasanjo lórí ìhùwàsí rẹ̀ s’áwọn Orí-adé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Fídíò tó ṣàfihàn bí Obasanjo ṣe peṣẹ́ fáwọn ọba alayé náà pé kí wọ́n dìde kí wọ́n sì tún jókòó lásìkò tí Gómìnà Seyi Makinde dé sí ibi ètò tí wọ́n wà di iṣu ata yán-an yàn-an pàápàá jùlọ lórí ayélujára.

Nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lẹ́yìn ìpàdé rẹ̀ ní Ọjọ́rú nílùú Àkúrẹ́, Afẹ́nifẹ́re sọ pé Obasanjo gbọdọ̀ tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ àwọn Orí-adé tọrọ kàn.

Afẹ́nifẹ́re sọ nínú àtẹ̀jáde tí akọ̀wé ẹgbẹ́ náà, Ọ̀gbẹ́ni Jare Àjàyí kà síta pe “ìyàlẹ́nu ní ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹ̀sán án nílùú Iṣẹyin jẹ́ níbi tí Obasanjo ti pàṣẹ fáwọn ọba alayé tó sì tún sọ fún wọn pé kí wọ́n jókòó padà.

Níṣe ló dàbí ẹni pé ọ̀gágun kan ló ń peṣẹ́ fáwọn ọmọ ogún.

Àwa Yorùbá bọ̀wọ̀ fún àṣà wa àtàwọn tó jẹ́ aṣojú àṣà wa bákan náà eléyìí tí í ṣe àwọn ọba alayé.

Àti wípé kìí ṣe lásán ni Yorùbá máa ń pe àwọn ọba ní igbákejì òrìṣà.

Ìdí èyí ni àwa ẹgbẹ́ Afenifere fi képe Ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ láti tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ àwọn ọba alayé yìí.

A kò gbọdọ̀ fààyè gba ẹnikẹ́ni láti tàbùkù àṣà àti ìṣe wa nílẹ̀ Yorùbá.

Èyí gan an làwọn Ọba kò ṣe máa dìde láwùjọ láti kí ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti káàkiri àgbáyé.”

Ẹ̀wẹ̀, Afenifere tún képe ìjọba àpapọ̀ lórí ètò àbò tó mẹ́hẹ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ẹgbẹ́ náà ní ìjọba gbọdọ̀ ri pé ètò àbò múlẹ̀, àti pé ìjọba gbọdọ̀ wá iṣẹ́ fáwọn ọ̀dọ̀ torí ọwọ́ tó bá dilẹ̀ ni Èṣù máa ń bẹ́ níṣẹ́ k’íṣẹ́.

Afenifere ní ìjọba gbọdọ̀ ri pé àwọn agbésùnmọ̀mí, jàǹdùkú àtàwọn tó ń tì wọ́n lẹ́yìn gbọdọ̀ fojú winá òfin.

Olórí ilé aṣòfin Òǹdó ké gbàjarè,pé wọ́n ń lépa ẹ̀mí òun

Olórí ilé aṣòfin Òǹdó ké gbàjarè,pé wọ́n ń lépa ẹ̀mí òun

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní a kìí dákẹ́ ẹ́ kú.Ó jọ pé ọ̀rọ̀ awuyewuye lórí ìyọninípò igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó tún ti gba ọ̀nà mìíràn yọ pẹlú bí Olórí ilé aṣòfin Òǹdó ṣe ké gbàjare pe káwọn agbófinró ṣàájú òun torí ìdúnkokò ẹ̀mí.
.
Olamide Oladiji tó jẹ́ olórí ilé sọ pé àti òun àti àwọn ọmọ ilé ní ọkàn àwọn ò balẹ̀ mọ́ láti ìgbà tí àwọn bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ láti yọ igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, Lucky Aiyedatiwa kúrò nípò.

Lásìkò tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní Àkúrẹ́ ló ke gbàjarè yìí lọ́jọ́ Ajé.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wí , ó ní ”lówùúrọ̀ yìí ni mo tún bá ẹbọ táwọn èèyàn kan gbé sí iwájú ilé ìgbé ti ìjọba là kalẹ̀ fún mi”

Ó ní ilé ìgbé yi tó nílò àtúnṣe jẹ́ ibi tóun kò sábà máa lò sí.

Ó ní ìpàdé ẹ̀ẹ̀kànkan àwọn ọmọ ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ làwọn máa ń ṣe níbẹ̀.

”Lówùúrọ́ yí ni mo rí ẹbọ tí èèyàn kan gbé sí iwájú ilé yìí. Yàtọ̀ sí eléyìí mo ti ń gba ìpè lórí ago táwọn kan fi ń dúnkookò mọ́ ẹ̀mí mi àti àwọn ọmọ ilé aṣòfin mí-ìn.Ìdààmú yí pọ̀ lórí ẹ̀mí mi”