Home Blog Page 91

Mohbad wẹ̀jẹwẹ̀mu láwùjọ ẹni ibi. – Tunde Bakare

Mohbad wẹ̀jẹwẹ̀mu láwùjọ ẹni ibi. – Tunde Bakare

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní àgùtàn tó bá ajá rìn, yóó jẹ imí, bẹ́ẹ̀ wọ́n ní ẹgbẹ́ buúkú ba ìwà rere jẹ́.
Àṣamọ̀ yìí jọ mọ́ n tí
Pásítọ̀ àgbà ìjọ Citadel Global Community Church, Tunde Bakare, sọ pé gbajúgbajà olórin tàkasúùfé tó jáde láyé, Ilerioluwa Aloba ‘Mobad’ bá àwọn ẹni ibi dòwòpọ̀ nígbà ayé rẹ̀.

Bakare ló sọ ọ̀rọ̀ náà níbi ìwàásù rẹ̀ nínú ìjọ The Envoy Nation, tó wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Nínú ìwàásù náà tó wáyé lásìkò àjọ àjọ̀dún ọdún Kejì ìjọ náà ni Bakare ti sọ pé àwọn èèyàn búburú ni Mohbad bá rìn lásìkò tó wà láyé.
Tí ẹ kò bá gbàgbé, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹsan án, ọdún 2023 yìí ni Mohbad dágbéré fáyé, tí wọ́n sì sin òkú rẹ̀ lọ́jọ́ kejì.

Bakare sọ pé “ Mélòó nínú yín ló mọ Mohbad, olórin ọmọ Nàìjíríà tó jáde láyé lẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n?

“ Nígbà tó ń mu ọtí àti sìga, tó sì ń bá àwọn èèyàn búburú rìn, kò mọ̀ pé yóò kérè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ láìpẹ́ tí ẹ̀mí rẹ̀ yóó sì gé kúrú laipẹ ọjọ́.

“Mi ò da lẹ́bi o, mo kàn ń bi yín ni pé ṣé orúkọ ọmọlúàbí ni Mohbad?”

Ẹwẹ, lẹ́yìn tí fídíò ìwàásù náà gbòde lórí ayélujára, ọ̀pọ̀ aráàlú ló ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bu ẹnu àtẹ̀ lu pásítọ̀ náà fún ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Lára àwọn èèyàn tó ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Bakare ni gbajúgbajà òṣèré, Tonto Dikeh àti Femi Fani-Kayode.

Wàyí ò, ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ti ṣe àyẹ̀wò òkú olóògbé náà láti mọ irú ikú tó pa á, ó sì ti ké sí àwọn aráàlú kí wọ́n ní sùúrù títí tí èsì àyẹ̀wò náà yóò fí jáde.

Egbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC,TUC fárígá kéde ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ

Egbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC,TUC fárígá kéde ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó ti pẹ́ tí àwọn èèyàn ti máa n sọ pé èdè kan ṣoṣo tí ìjọba gbọ́ kò ju ìyanṣẹ́lódì lọ, ní báyìí àgbáríjọpọ̀ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nàìjíríà Nigeria Labour Congress, NLC àti Trade Union Congress, TUC ti panupọ̀ kéde pé àwọn yóó gùnlé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ ní Nàìjíríà.

Ìkéde yí wáyé lẹ́yìn ìpàdé tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun tí wọ́n sì fẹnukò pé bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Ìṣẹ́gun ọjọ́ Kẹta oṣù Kẹwàá 2023 àwọn yóó bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì náà.

Ṣaájú ní wọ́n ti fún ìjọba ní gbèdéke ọjọ́ méjìlá àti ìyanṣẹ́lódì ìkìlọ̀ ọlọ́jọ́ méjì láti fi jẹ́ kí ìjọba wá nǹkan ṣe sí ìnira tó dé ba aráàlú lẹ́yìn tí ìjọba yọ ẹ̀kúnwó epo bẹntiróò.

Ààrẹ NLC àti ti TUC Comrade Joe Ajaero àti Comrade Festus Osifo ló jọ buwọ́lu àtẹ̀jáde tó tẹ̀yìn ìpàdé yìí wáyé.

Wọ́n ní ní ìbámu pẹ̀lú àyájọ́ òmìnira Nàìjíríà àwọn náà ṣetán láti rí pé òmìnira tó péye fáwọn aráàlú nípa gbígba arawọn sílẹ̀ àti mímú àyánmọ́ arawọn ṣe fún ara wọn.

Ní báyìí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ láwọn tikésí gbogbo àwọn ẹ̀ka ẹgbẹ́ náà láti bẹ̀rẹ̀ ìpalẹ̀mọ́ láti yan iṣẹ́lódì kí wọn sì gba ìgboro kan pẹlú ìwọ́de títí tí ìjọba yóò fi tẹ́tí sí àwọn ẹ̀dùn ọkàn táwọn fi ṣọwọ́.

Nínú ọ̀rọ̀ tí NLC àti TLC sọ nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi síta, wọn ní kókó pàtàkì ni pé àti àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti ìjọba àríyànjiyàn kò sì lórí pé yíyọ ẹ̀kúnwo epo bẹntiró mú kí ara máa ni aráàlú púpọ̀.

Àmọ́ wọ́n ní ìjọba kọ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ojúṣe wọn èyí tí yóó mú ìnira ẹbi àti òṣì tó kárí yìí dínkù láwùjọ.

”Ìjọba àpapọ̀ kàn dá ọgbọ́n lórísìí láti fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní láti lè mú ìdẹ̀kùn bá aráàlú nítorí ẹ̀dínwó epo tí wọ́nyọ.”

Àwọn ẹgbẹ́ náà tẹ̀síwájú pé ìjọba kó fi ọ̀nà kankan tó bójúmu wá nǹkan ṣe sí àwọn ẹ̀dùn ọkàn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti aráàlú gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú ìlànà àjùmọ̀fẹnukò sí ti yóó mú kí ara dẹ aráàlú.

Torí náà àwọn olórí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ti wá sọ pé gbogbo ọ̀nà ni ìjọba ń gbà láti sọ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lẹ́nu pàápàá lójú òpó ayélujára tí wọ́n sì ń lo agbára wọn láti fún àwọn lọ́rùn dípò kí wọ́n fi agbára ọ̀hún mú ayé dẹrùn fáráràlú.

Ọkùnrin kan pàdánù $2.1 sórí ‘cryptocurency’

Ọkùnrin kan pàdánù $2.1 sórí ‘cryptocurency’

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà bọ wọ́n ní ajé ní-ín bojú ọ̀rẹ́ jẹ́.
Ní báyìí tí ọkùnrin tí wọ́n ń pè ní ‘King of Crypto’ yóó máa jẹ́jọ́ lórí onírúurú ẹ̀sùn jìbìtì, ọkùnrin ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan ti ṣàlàyé bí òun àti ọ̀pọ̀ èèyàn káàkiri àgbáyé ṣe pàdánù òbítíbitì owó sí iléeṣẹ́ Sam Bankman-Fried.

Títí di ìgbà tí iléeṣẹ́ náà fi lulẹ̀, Sunil Kavuri ṣì gbàgbọ́ pé Sam Bankman-Fried ṣì lè wá ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro tí wọ́n dojúkọ.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iléeṣẹ́ King of Cryotp ti ń dàwó, Sunil gbàgbọ́ pé kò sí ewu lóko.

Èyí kò ṣẹ̀yìn àwọn ìrírí rẹ̀ nípa ìdòwòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ ńlá ńlá bíi ilé ìfowópamọ́ àti bó ṣe máa ń ṣòwò crypto ṣaájú.

Ìgbàgbọ́ rẹ̀ pọ̀ nínú Sam Bankman-Fried tó bẹ́ẹ̀ tó fi sọ pé kò sí ewu lóko.

Ẹnu rẹ̀ ló wà títí tó fi rí àtẹ̀jíṣẹ́ pé kò sí ànfààní láti gba owó jáde mọ́.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí iléeṣẹ́ FTX, tó jẹ́ iléeṣẹ́ tó tóbi jùlọ lágbàáyé nípa pàṣípààrọ̀ cryptocurency ṣe lulẹ̀.

Gbogbo òógùn ojú Sunil fun ọjọ́ pípẹ́ ló bá iléeṣẹ́ náà lọ lẹ́yìn tó pàdánù owó tí iye rẹ̀ jẹ́ $2.1 níbẹ̀

Ìròyìn ní ọgbẹni Sunil ni ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó pàdánù owó tó pọ̀ jùlọ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Àmọ́ yàtọ̀ sí Sunil ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn bíi tirẹ̀ ló pàdánù owó nlá sílẹ́eṣẹ́ náà káàkiri àgbáyé, ó sì ti darapọ̀ mọ́ àwọn èèyàn náà láti pe FTX lẹ́jọ́ báyìí.

Sunil ni “ẹnìkan tilẹ̀ wà lórílẹ̀-èdè Turkey tó jẹ́ pé $600 nìkan ló kù lọ́wọ́ rẹ̀ lẹ́yìn tó pàdánù gbogbo owó rẹ̀ ṣọ́wọ́ FTX, nígbà tí ẹlòmíràn ní South Korea ti dèrò ilé ìwòsàn .”

Sunil ti bẹ̀rẹ ìrànlọ́wọ́ fún àwọn èèyàn láti ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Canada, Argentina, Dubai, Turkey, Hong Kong, China àti Singapore lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.

Púpọ̀ nínú wọn ló ti di ẹdun arinlẹ̀, nígbà tí àwọn mìíràn pàdánù owó tó lé ní òbítíbitì mílíọ̀nù.

Gbogbo wọn ló ń dúró de ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀.

Ẹ̀sùn méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó ní ṣe pẹ̀lú ìwà jìbìtì ni àwọn aṣòfin ilẹ̀ Amẹ́ríkà fi kan Sam Bankman Fried.

Ọkùnrin ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n náà, tó dá iléeṣẹ́ FTX ti sọ pé òun jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun, àmọ́ yóò pe ẹjọ́ tako àwọn ẹ̀sùn ọ̀hún.

Yàtọ̀ sí òun, àwọn lọ́gàlọ́gà níléeṣẹ́ rẹ̀ náà ti gbà pé àwọn jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n, wọ́n sì ṣetán láti sọ̀rọ̀ lórí bí iléeṣẹ́ náà ṣe dà wó.

FTX jẹ́ iléeṣẹ́ tí ọ̀pọ̀ gbàgbọ́ pé wọ́n lè kó owó wọn lé lórí fún òwò crypto ṣíṣe.

Lára àwọn kátàkárà tí àwọn èèyàn lè ṣe níléeṣẹ́ náà ni Bitcoin, àtàwọn owó ayélujára mìíràn.

Mílíọ̀nù mẹ́ṣàn-án èèyàn ló bá iléeṣẹ́ náà dòwòpọ̀ láti àwọn orílẹ̀-èdè bíi ọgọ́rùn ún.

Nígbà tí iléeṣẹ́ ọ̀hún dàwó, nǹkan bíi mílíọ̀nù kan èèyàn ni owó wọn bọ́ há nítorí wọn kò tètè gba àwọn owó náà jáde.

Kókó ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Sam Bankman Fried ni pé ó lo owó àwọn tó bá iléeṣẹ́ rẹ̀ dòwòpò fún àwọn òwò mí ìn fún ànfàní ara rẹ̀, àti láti ra àwọn ilé olówó ńlá, wọ́n ní ó tún bùn ún ọ̀pọ̀ olóṣèlú lówó fún ìpolongo ìbò.

Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà jóná, pẹ̀lú àwọn fáílì kan

Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà jóná, pẹ̀lú àwọn fáílì kan

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iná ọmọ ọ̀rara ti sẹ́yọ nílé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé.
Ilé ẹjọ́ náà tó wà ní Three Arms Zone ní olú ìlú Nàìjíríà, Abuja ló jẹ́ ọ́fíìsì àwọn adájọ́ àgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta Nàìjíríà.

Ohun tó ṣokùnfà iná náà ni kò ì tíì yé ẹnikẹ́ni ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́ panápaná ti ń ṣiṣẹ́ láti pa iná náà.

Ìròyìn tó gbòde tí a kò ì tíì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ báyìí ni pé iná ọ̀hún ṣàkóbá fún ọ́fíìsì àwọn adájọ́ àgbà mẹ́ta àmọ́ iye àwọn nǹkan tí iná náà bàjẹ́ kò ì tíì jẹ́ mímọ̀.
Agbẹnusọ ilé ẹjọ́ náà, Dókítà Festus Akande ní àwọn ìwé àti fáílì kan ti jó.

Akande ní iná náà ṣàkóbá fún ọ́fíìsì ọ̀kan nínú àwọn adájọ́ àgbà Nàìjíríà àmọ́ kò dárúkọ èyí tó jẹ́ gan nínú àwọn adájọ́ náà.

Bákan náà ló ní iná mọ̀nàmọ́ná ló ṣokùnfà iná ọ̀hún.

Ó ní àwọn òṣìṣẹ́ àwọn ló ti kọ́kọ́ gbìyànjú láti pa iná náà pẹ̀lú àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń pa iná tó wà ní ọ́fíìsì wọn.

Ó fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn fáílì kan bá iná náà lọ, ó ní àwọn ní ẹ̀dá gbogbo rẹ̀ lórí kọ̀mpútà àwọn.

Emefiele kọ̀wé fipò sílẹ̀ bí Cardoso ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi gómìnà CBN

Emefiele kọ̀wé fipò sílẹ̀ bí Cardoso ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi gómìnà CBN

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN ti kéde pé gómìnà àná ní ilé ìfowópamọ́ náà, Godwin Emefiele ti kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀.

Ìkọ̀wéfipòsílẹ̀ náà ló ń wáyé lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tí Ààrẹ Tinubu ní kí Emefiele lọ rọ́kún nílé fún ìgbà kan ná.

Lẹ́yìn tí Tinubu ní kí Emefiele lọ rọ́kún nílé ni àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS fi sí àhámọ́ tí wọ́n sì gbé lọ sílé ẹjọ́.

Ìjọba àpapọ̀ yàn igbákejì Emefiele láti máa delé, kí ó máa ṣe àkóso ilé ìfowópamọ́ náà.

Àtẹ̀jáde kan láti ọ́fíìsì Agbẹnusọ akọ̀wé ìjọba orílẹ̀ èdè yìí, Willie Bassey ní ìdí tí ìjọba ṣe ni kí Emefiele lọ rọ́kún nílé ni ìwádìí kan tó ń lọ lọ́wọ́ lórí rẹ̀ àti pé ìjọba fẹ́ ṣe àtúntò ẹ̀ka ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà.
Ẹ̀wẹ̀ ní ọjọ́ Kẹẹ̀dógún oṣù Kẹsàn-án ni ìjọba kéde ìyànsípò Olayemi Cardoso bíi gómìnà tuntun tí ilé aṣòfin àgbà bá buwọ́lu ìyànsípò náà.

Àtẹ̀jáde látọwọ́ agbenusọ Tinubu, Ajuri Ngalele ni wọ́n ti kéde ìyànsípò ọlọ́dún márùn-ún náà.

Láti fìdí èyí múlẹ̀, CBN nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi léde lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kejìlélógún oṣù Kẹsàn-án ní Cardoso ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí gómìnà ilé ìfowópamọ́ ọ̀hún.

Agbenusọ CBN, Isa Abdulmumin nínú àtẹ̀jáde náà ní Cardoso yóò máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí adelé títí tí ilé aṣòfin àgbà fi máa buwọ́lu ìyànsípò rẹ̀.

Abdulmumin ní èyí ń wáyé lẹ́yìn tí Godwin Emefiele kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí gómìnà CBN.

Bákan náà ló ní àwọn mẹ́rin tí Tinubu yàn gẹ́gẹ́ bí igbákejì sí Cardoso ni àwọn náà tí wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́yìn tí àwọn igbákejì Emefiele tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ kọ̀wé fipò wọn sílẹ̀.

Cardoso ni alága ilé ìfowópamọ́ Citibank Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ tó sì ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí lẹ́ka ètò ìsúná àti ọrọ̀ ajé Nàìjíríà.

Nítorí à ti lè tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ mi ni mo ṣe lọ ń kọ́ iṣẹ́ irun gígẹ̀’

Nítorí à ti lè tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ mi ni mo ṣe lọ ń kọ́ iṣẹ́ irun gígẹ̀’

Fẹ́mi Akínṣọlá

Akẹ́kọ̀ọ́ ilé gíga Moshood Abiola Polytechnics tó wà ní ìpínlẹ̀ Ogun ni Rukayat Temilorun Akinbola.

Yorùbá ní ọ̀nà kan kò wọ ọjà ló mú Elizabeth, bó ṣe jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga yìí, gbèrò láti wá ìmọ̀ kún ìmọ̀ rẹ̀.

Elizabeth pa èrò pọ̀ pé iṣẹ́ ọwọ́ tí àwọn obìnrin kìí sábà ṣe ló wu òun láti kọ́ kí òun le dá yàtọ̀ ní àwùjọ.

Ìdí nìyí tó fi lọ kọ́ iṣẹ́ irun gígẹ̀ dípò irun dídì tí wọ́n mọ obìnrin mọ́.

Ó ṣàlàyé pé òun wò ó pé òun nílò láti túnbọ̀ ní ìmọ̀ mìíràn yàtọ̀ sí ilé ẹ̀kọ́ tí òun ń lọ ni òun ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ iṣẹ́ irún gígẹ̀.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó nira fún òun láti máa lọ sílé ẹ̀kọ́ àti láti máa kọ́ iṣẹ́ ọwọ́ papọ̀ mọ́ lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga, ó ní òun máa ń ri dájú pé kò dí ara wọn lọ́wọ́.

Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé iṣẹ́ ọwọ́ tí òun ń kọ náà máa jẹ́ aṣínà fún òun láti túnbọ̀ tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ tí òun ń ṣe tẹ́lẹ̀.

Ẹnìkan fẹ́ máa lò fídíò ìhòhò mi gba owó –Lizzy Jay

Ẹnìkan fẹ́ máa lò fídíò ìhòhò mi gba owó –Lizzy Jay

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní èèyàn tó bá dákẹ ,tara rẹ̀ yóò ba dákẹ́ pẹ̀lú,ní bayìí, olókìkí adẹ́rìnínpòṣónú, Adebola Adeyeba tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Lizzy Jay tàbí Omo Ibadan ti ké gbàjarè sí àwọn Nàìjíríà láti gba òun kalẹ̀ lọ́wọ́ ènìyàn kan tó fẹ́ máa fi àwòrán ìhòhò òun gba owó lọ́wọ́ òun.

Nínú fídíò kan tí Lizzy Jay gbé sórí Sítágíràmù rẹ̀ ló ti fẹ̀sùn kàn pé láti bí ọjọ́ mẹ́ta ni ẹnìkan ti ń pe òun, tó sì tún ń tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ sí òun pé òun ní àwọn àwòrán ìhòhò òun lọ́wọ́.

Ọmọ Ibadan ní nǹkan tí ẹni náà ń gbìyànjú láti ṣe ni láti fi fídíò náà gba owó lọ́wọ́ òun àmọ́ òun kò ṣetán láti san kọ́bọ̀ fún ẹnikẹ́ni.

Báwo ni ẹni náà ṣe ní fídíò ìhòhò Lizzy Jay?
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bí ẹni náà ṣe ní fídíò ìhòhò rẹ̀ lọ́wọ́, Lizzy Jay ṣàlàyé pé ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ni òun ri pé ẹnìkan ń gbìyànjú láti wọ inú àwọn àkáǹtì òun lórí ayélujára.

Ó ní èyí ló mú kí òun pàrọ̀ e-mail tí òun ń lò lórí Facebook àti Instagram òun láti ìgbà náà ṣùgbọ́n òun kò yọ ọ́ kúrò lórí Snapchat òun.

Lizzy Jay ní bí oṣù mélòó sẹ́yìn ni ó rẹ òun tí òun sì pe dókítà òun láti ṣàlàyé àwọn nǹkan tó ń ṣe òun fún-un.

Ó ní dókítà kọ ogun àti abẹ́rẹ́ tí òun yóò lò láti fi yanjú àwọn nǹkan tó ń ṣe òun àmọ́ àwọn oògùn tí wọ́n kọ fún òun láti lò gbòsì lára òun.

Ó ní àwọn kòkòrò bẹ̀rẹ̀ sí ní yọ sí òun lára àti ní ojú ara òun àti pé ẹ̀jẹ̀ ń dà ní ojú ara òun.

Ó ṣàlàyé pé èyí ló mú òun ṣe fídíò ojú ara òun láti fi ránṣẹ́ sí dókítà tó kọ oògùn náà fún òun láti mọ bí nǹkan náà ṣe pọ̀ tó.

Ó fi kun pé Snapchat ni òun lò láti ṣe fídíò náà tí òun kò mọ̀ pé ẹnìkan wà tó ti ní àkáǹtì Snapchat òun tí ó sì fi fídíò náà sórí fóònù rẹ̀.

Lizzy Jay tẹ̀síwájú pé onítọ̀hún ti kọ́kọ́ pe òun pé òun ní fídíò ìhòhò òun lọ́wọ́ àti pé òun yóò gbé fídíò náà sórí ayélujára.

Ó ní kò pẹ́ ló tún pe òun pé òun ti gbé fídíò náà sórí Instagram pé kí òun lọ wò ó àmọ́ kò pẹ́ tó fi pa fídíò náà rẹ̀ níbẹ̀.

Ó fi kun pé ẹni náà dúnkokò mọ́ òun pé tí òun kò bá ṣe nǹkan tí òun ń fẹ́, òun máa lọ gbé fídíò náà sórí TikTok fún gbogbo ayé láti wò.

Lizzy Jay ní gbogbo nǹkan tó wà ní ìkáwọ́ òun ni òun máa ṣe láti ri pé ọwọ́ tẹ ẹni náà nítorí àìsàn tó ṣe àkóbá fún àgọ́ ara òun ló fẹ́ lò láti fi gba owó lọ́wọ́ òun.

Ipò Aláàfin kì í ṣe fún jẹhunjẹhun- Seyi Makinde

Ipò Aláàfin kì í ṣe fún jẹhunjẹhun- Seyi Makinde

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà bọ̀,wọ́n ní èèyàn tí kò gbọ́ tẹnu ẹ̀gà ní-ín pè é lẹ́yẹ aláròyé.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Onímọ̀ẹ̀rọ Ṣyí Mákindé ti ké sí àwọn ọmọ ìlú àti àwọn ọmọọba tó ń jìjàdù fún ipò Aláàfin Ọ̀yọ́ láti dẹ́kun ìlépa wọn nítorí ipò náà kìí ṣe ohun tí ẹnikẹ́ni lè fi owó rà.

Mákindé tí ó sọ ọ̀rọ̀ náà níbi ìṣíde òpópónà tuntun Ọ̀yọ́-Ìṣẹ́yìn lọ́jọ́ Ẹtì fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ipò Aláàfin kò sí fún káràkátà.

Ó ní, “Mo ké si àwọn ọmọọba àti àwọn mìíràn tó nífẹ̀ẹ́ sí ipò Aláàfin Ọ̀yọ́ láti jáwọ nínú ìjìjàdù lórí ẹni tí yóó gun orí ìtẹ́ náà.

Ipò ọ̀wọ̀ náà kò ní bọ́ sí ọwọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ fi owó ràá, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbìyànjú láti tà á yóó kan ìdin nínú iyọ̀”.

Ipò Aláàfin Ọ̀yọ́ ṣí sílẹ̀ lẹ́yìn ìpapòdà Ọba Lamidi Olayiwola Adéyẹmí III, ti gbésẹ̀ nínú oṣù kẹrin ọdún 2022.

Lẹ́yìn ìpapòdà Ọba Adéyẹmí sì ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọọba àti ìdílé tó ń fi ọba jẹ ti bẹ̀rẹ̀ ìjìjàdù lórí ẹni tí ó kàn láti dé adé ọba.

Lọ́wọ́lọ́wọ́, ìkéde ti Gómìnà Mákindé ni gbogbo èèyàn ìlú ń retí láti sọ ẹni tí yóò jẹ́ Aláàfin tuntun. A kú ojú lọ́nà

Sùrutù l’Abeokuta níbi ìfẹ̀hónúhàn lórí ikú tó pa Mohbad

Sùrutù l’Abeokuta níbi ìfẹ̀hónúhàn lórí ikú tó pa Mohbad

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kò tọ́ kí màjèṣín tojú òbí rọ̀run.Ìbànújẹ́ ayérayé ni.
Ẹsẹ̀ kò gba èrò lónìí ọjọ́
Ìṣẹ́gun nílùú Abẹ́òkúta nígbà tí àwọn ọ̀dọ́, pàápàá àwọn olólùfẹ́ orin tàkasúfèé jáde lọ́pọ̀ yanturu láti ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn àlàáfíà lórí ikú Ilerioluwa Ọladimeji Alọba tí ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ mọ̀ sí Mohbad.

Gbàgede eré ìdárayá tí wọ́n ń pè ní Skating Ground, èyí tó wà ládojúkọ Post Office, Ibara nílùú Abẹ́òkúta ni ìwọ́de náà ti wáyé.

Ohun tí a gbọ́ ni pé, nǹkan bí aago mẹ́wàá àárọ̀ ni ètò ọ̀hún bẹ̀rẹ̀, níbi tí àwọn ọ̀dọ́ tí ń pè fún ìdájọ́ òdodo lórí ikú Mohbad náà.

Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn olórin ọmọ bíbí ìlú Abẹ́òkúta nní, Adeyinka Adeboye tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Boye Best lo léwájú ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ọ̀hún.

Níbẹ̀ ni wọ́n ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó lábẹ́ Gómìnà Babajide Sanwo-Olu, ọ̀gá ọlọ́pàá orílẹ-èdè Nàìjíríà, Kayọde Ẹgbẹtokun láti má ṣe jẹ́ kí ikú Mohbad lọ lásán.

Boye Best ni gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ikú olóògbé náà ni wọ́n gbọdọ̀ fojú winnà òfin orílẹ-èdè Nàìjíríà, nítorí pé ọ̀kan pàtàkì lára àwọn tí yóó gbé ògo orílẹ-èdè yìí sókè ni wọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò.

Kò dín ní ẹgbẹ̀rún méjì àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n kórajọ láti fẹ̀hónúhàn lónìí, tí àwọn òṣìṣẹ́ agbófinró sì wà níbẹ̀ láti dáàbò bo àwọn èèyàn.

Ojú ù mi rí hèèmọ̀ níléeṣẹ́ Bayowa, mo ta dúkìá san gbèsè– Busola Oke Eleyele

Ojú ù mi rí hèèmọ̀ níléeṣẹ́ Bayowa, mo ta dúkìá san gbèsè– Busola Oke Eleyele

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé yorùbá bọ̀ wọ́n ní ìrírí làgbà. Bẹ́ẹ̀, ó níbi tí èèyàn bá ọ̀rọ̀ dé, kó tó kan ìbéèrè pé, ṣé ó ṣe ọ́ rí?
Ìràwọ̀ olórin ẹ̀mí, Busola Oke tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ẹlẹ́yẹlé ti fẹnu yẹpẹrẹ alágbàtà fíìmù àti orin nígbà kan, Gbenga Adewusi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Bayowa Films and Record International.

Busola Oke nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn tó máa ń gbé àwọn olórin lárugẹ ṣe máa ń lò wọ́n láti fi pa owó sí àpò ara wọn láì fún àwọn olórin náà ní àǹfàní láti jẹ èrè iṣẹ́ wọn.

Nínú fídíò kan tí Busola Oke tó ṣe lórí TikTok rẹ̀ ní ojú òun rí tó lọ́wọ́ Bayowa nítorí òun kò rí àǹfàní kankan jẹ lórí àwọn orin tí òun ṣe lábẹ́ ilé iṣẹ́ rẹ̀.

Ó ní òun ta ilé àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá òun nítorí òun kò ì tíì bọ́ lọ́wọ́ àkóbá tí Bayowa ṣe fún òun nígbà tí òun wà lábẹ́ rẹ̀.

Ó gba àwọn olórin tó bá ń dìde lásìkò yìí láti la ojú wọn sílẹ̀ dáradára kí wọ́n má ba à kósí ọwọ́ àwọn tí wọ́n máa ba ògo wọn jẹ́.

Ó kọminú pé òun kò rí ẹnìkankan ta òun lólobó nígbà tí òun fẹ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Bayowa pé oore ẹ̀dẹ ni òun fẹ́ gbà pé òun kò bá má ti torí bọ̀ ọ́ tàbí kó sí abẹ́ rẹ̀.

Busola Oke ṣàlàyé pé lẹ́yìn tí àwọn ṣe orin ìkẹyìn fún olóògbé Gbenga Adeboye ni Bayowa pe òun pé kí òun wá ṣe orin fún iléeṣẹ́ òun.

Ó tẹ̀síwájú pé ìgbà náà ni òun ṣàlàyé fún pé òun ní orin kan tí òun ń ṣe lọ́wọ́ tó sì ní kí òun wá àwọn orin mìíràn mọ́ tí òun sì ṣe bẹ́ẹ̀.

“Tí wọ́n bá sọ wí pé àwọn nǹkan báyìí ni mo ti kójọ nílé ayé mi níbi tí àwọn àwo orin tí mo ṣe fún Bayowa tà dé, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

“Nǹkan tí àwọn promoter máa ;ń ṣe ni pé wọ́n máa ń sọ ènìyàn di ẹrú títí ayérayé, tí ènìyàn yóò máa sìn wọ́n títí tó máa fi kú.”

“Nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láàárín èmi àti Bayowa nìyí, ó fẹ́ sọ mí di ẹrú ayérayé ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ wà lọ́wọ́ Ọlọ́run.”

Bákan náà ló kọminú pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni ó yẹ kí òun ti gbéṣe ṣùgbọ́n tí òun kò lè ṣe tí àwọn kan sì ń fi òógùn òun jẹ ayé.

Ó ní òun gbà pé Ọlọ́run nìkan ló máa dájọ́ láàárín òun àti Bayowa fún gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn.