Home Blog Page 89

Ipa tèmi náà láwùjo̩ ni owó tí mò ń ná lórí àwo̩n ò̩jè̩wé̩wé̩ olórin – Olamide

Ipa tèmi náà láwùjo̩ ni owó tí mò ń ná lórí àwo̩n ò̩jè̩wé̩wé̩ olórin – Olamide

Mary Fágbohùn

Olorin Naijiria, Olamide Adedeji, ti a mo si Olamide, ti safihan idi to fi da ile ise orin sile.

Oga YBNL naa wi pe oun bere ile ise orin naa nitori ki oun le na owo oun eyi “to ti n po” lori ise orin awon oje wewe olorin.

O safihan eyi ninu iforo-wani-lenu-wo kan pelu Ebro Darden ti Apple Music.

O wi pe, “Mo sese bere si mu owo wole ni sugbon owo naa n di pupo fun mi. Mo wa so pe, bee ni, ko si ohun ti mo fe fi awon owo yi se mo, oya, mo nilo lati gba awon olorin tuntun.

“O je ona kekere temi lati da nnkan pada si awujo.”

Ile ise YBNL Nation ti Olamide je ile fun awon iran olorin takasufe tuntun kaakiri orile ede bii; Fireboy DML ati Asake.

Adekunle Gold, Lil Kesh, Chinko Ekun, Young Jonn, ati Pheelz wa labe ile ise orin naa teleri.

È̩sùn Yvonne Nelson fé̩rè̩ ba ìbásepò̩ èmi àti olólùfé̩ mi jé̩ – Iyanya

È̩sùn Yvonne Nelson fé̩rè̩ ba ìbásepò̩ èmi àti olólùfé̩ mi jé̩ – Iyanya

Olorin Naijiria, Iyanya Onoyom Mbuk, ti a mo si Iyanya, ti safihan pe esun ti orebinrin oun teleri omo Ghana, osere tiata Yvonne Nelson fi kan oun wi pe oun ni ibasepo miran pelu Tonto Dikeh fere je ki oun padanu ibasepo ti oun wa ninu re.

Olorin ‘Kukere’ naa so eyi di mimo nigba to farahan lori eto Tea With Tay laipe yi ti osere tiata, Temisan Emmanuel Ahwieh, ti a mo si Taymesan se atokun re.

E ranti pe Yvonne Nelson ninu iwe re, ‘I Am Not Yvonne Nelson’ to gbe jade ni ojo kejidinlogun osu keje, 2023, salaye nipa bi o se mo pe orekunrin re teleri, Iyanya, ni ibasepo miran pelu osere tiata, Tonto Dikeh.

Iyanya so pe leyin ti iwe naa jade, omobinrin kan ti oun n wa lati fe ko fe gba fun oun.

O wi pe, “Ohun to sele [esun Yvonne Nelson] fe dani lori ri, arakunrin. Isele naa fere mu ki n padanu ibasepo mi. Ibasepo ti mo wa ninu re bayii.

“Saaju iwe yi [iwe Yvonne Nelson], mo n ba omobinrin kan ti ko mo nnkankan ti ko si ni okiki soro sugbon lojiji iwe naa jade, gbogbo nnkan beere si ni gbon. Omobinrin naa wa so pe , ‘Omo, arakunrin yi, o ti yi pada? Se o daa loju pe iru eyi ko ni sele si mi?’”

È̩sùn Yvonne Nelson fé̩rè̩ ba ìbásepò̩ èmi àti olólùfé̩ mi jé̩ – Iyanya

È̩sùn Yvonne Nelson fé̩rè̩ ba ìbásepò̩ èmi àti olólùfé̩ mi jé̩ – Iyanya

Olorin Naijiria, Iyanya Onoyom Mbuk, ti a mo si Iyanya, ti safihan pe esun ti orebinrin oun teleri omo Ghana, osere tiata Yvonne Nelson fi kan oun wi pe oun ni ibasepo miran pelu Tonto Dikeh fere je ki oun padanu ibasepo ti oun wa ninu re.

Olorin ‘Kukere’ naa so eyi di mimo nigba to farahan lori eto Tea With Tay laipe yi ti osere tiata, Temisan Emmanuel Ahwieh, ti a mo si Taymesan se atokun re.

E ranti pe Yvonne Nelson ninu iwe re, ‘I Am Not Yvonne Nelson’ to gbe jade ni ojo kejidinlogun osu keje, 2023, salaye nipa bi o se mo pe orekunrin re teleri, Iyanya, ni ibasepo miran pelu osere tiata, Tonto Dikeh.

Iyanya so pe leyin ti iwe naa jade, omobinrin kan ti oun n wa lati fe ko fe gba fun oun.

O wi pe, “Ohun to sele [esun Yvonne Nelson] fe dani lori ri, arakunrin. Isele naa fere mu ki n padanu ibasepo mi. Ibasepo ti mo wa ninu re bayii.

“Saaju iwe yi [iwe Yvonne Nelson], mo n ba omobinrin kan ti ko mo nnkankan ti ko si ni okiki soro sugbon lojiji iwe naa jade, gbogbo nnkan beere si ni gbon. Omobinrin naa wa so pe , ‘Omo, arakunrin yi, o ti yi pada? Se o daa loju pe iru eyi ko ni sele si mi?’”

Owó yóò tán ló̩wó̩ re̩ tí o bá ń náwó bíi tèmi – DJ Chicken so̩ fún Portable

Owó yóò tán ló̩wó̩ re̩ tí o bá ń náwó bíi tèmi – DJ Chicken so̩ fún Portable

Mary Fágbohùn

DJ Chicken, asakojopo orin ni Naijiria, ti so fun olorin alariyanjiyan, Portable, pe owo yoo tan lowo re ti o ba gbiyanju lati nawo bii ti oun.

O so eyi nigba to n beere bi oro Portable nipa pe o loro se je okodoro to.

Asakojopo orin naa, ninu eto Instagram wo mi ki n wo o kan, da Portable lebi pe ko le e ran oko miran leyin ijamba to sele.

O ni Portable o se ra oko miran leyin isele naa to ba je pe loooto ni owo to n pariwo re wa lowo re.

“Portable, ti o ba na iru owo ti mo n na ni ose, owo yoo tan lowo re. Ko si owo lowo re.

“O ye ki o ti ra oko tuntun leyin ti ijamba oko naa waye to ba je pe loooto ni owo wa lowo re.”

E ranti pe Portable ati awon okunrin re ni a ri ninu fonran kan to n lo kaakiri ti won n bu DJ Chicken nitori esun pe o fi owo ranse si iyawo re.

È̩bùn O̩ló̩run ni wíwá sáyé – Mercy Johnson

È̩bùn O̩ló̩run ni wíwá sáyé – Mercy Johnson

Mary Fágbohùn

Osere tiata Naijiria olugbafe eye, Mercy Johnson Okojie, ti beere fun adura lati odo awon afenifere re bi o se saami ojo ibi odun kokandinlogoji.

Osere naa, eni ti a bi ni ojo kejidinlogbon osu kejo 1984, lo si gbogbo oju opo ayelujara re lati sajoyo ojo ibi re ni ojo Aiku.

Ninu atejade to fi lede ni ojo opo Facebook re, osere naa nigba to n dupe lowo Olorun fun gbogbo awon aseyori re, wi pe “ebun ni aye kii se eto”.

O ko o wi pe, “Itelorun ni mimo pe aye je ebun kii se eto ati pe otito si wa leyin itelorun.

“E jowo, E o nilo lati fi aworan mi lede, e kan so ‘Adura ope ni idake jeje si Olorun fun mi’… Omo Olojo Ibi!”

Òògùn owó ni mo fẹ́ fi àwọn ọ̀rẹ́ méjì tí mo pa ṣe— Ọ̀daràn lahùn

Òògùn owó ni mo fẹ́ fi àwọn ọ̀rẹ́ méjì tí mo pa ṣe— Ọ̀daràn lahùn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bauchi ti mú Ọgbẹni Ibrahim Umar, ẹni ogójì ọdún, tó pa àwọn òṣìṣẹ́ méjì níléeṣẹ́ kan tó wà lágbègbè Gamawa, níjọba ìbílẹ̀ Gamawa, níìpínlẹ̀ Bauchi.

Àwọn méjèèjì ọ̀hún tí wọ́n pàdé ikú òjìji láti ọwọ́ ọ̀daràn náà ni: Kabiru Idi, ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì àti Bato Ali, ẹni ọdún méjìdínlógún.

Òun tí a gbọ́ ni pé Ibrahim tí í ṣe ọmọ ìlú Ungogo, lọ sílùú Taranka, níjọba ìbílẹ̀ Gamawa, láti lọ̀ọ́ hùwà láabi ọ̀hún, tọ́wọ́ sì tẹ̀ ẹ́ lẹ́yìn tó ṣiṣẹ́ ibi ọhún tán.

Ọ̀gbẹ́ni Adamu, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta kan tó ń gbé nílùú Taranka, níjọba ìbílẹ̀ Gamawa yìí kan náà, ló lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́pàá agbègbè ọ̀hún láti lọ fẹjọ́ sùn wọn pé àwọn kò tí ì rí àwọn òṣìṣẹ́ méjèèjì táwọn ń wá láti nǹkan bíi oṣù kan sẹ́yìn .

Àtẹ̀jáde kan tí Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, Ọ̀gbẹ́ni Mohammed Wakili, fi síta lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2023 yìí ni wọ́n ti sọ pé ìwádìí ìjìnlẹ̀ àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kan ló fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ibrahim ló pa àwọn méjèèjì ọ̀hún láti lò wọ́n fún ètùtù ọlà.

‘Lẹ́yìn táwọn ọlọ́pàá gbá a mú tán, wọ́n lọ̀ ọ́ yẹ ilé rẹ̀ wò, wọ́n sì bá gálọ́ọ̀nù ńlá kan tí ẹ̀jẹ̀ kún inú rẹ̀ fọ́fọ́, èyí tí wọ́n gbàgbọ́ pé ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni tó pa ló wà níbẹ̀.

Lójú-ẹsẹ̀ ni wọ́n ti jù ú sáhàámọ, láti lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìwádìí wọn.

Ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá ló ti jẹ́wọ́ pé lóòótọ́, òun lòun pa àwọn èèyàn ọ̀hún láti fi wọ́n ṣòògùn owó. Lẹ́yìn náà ló mú àwọn ọlọ́pàá lọ síbi tó sìnkú wọn sí.

Wọ́n ti hú òkú àwọn èèyàn náà jáde, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti fìdí òótọ̀ múlẹ̀.

Àwọn ọlọ́pàá ti gbé òkú àwọn èèyàn ọhún fáwọn èèyàn wọn, kí wọ́n lè lọ ṣètò ìsìnkú wọn. Bákan náà ni wọ́n láwọn máa fojú ọdaràn náà balé -ẹjọ́ lópin ìwádìí àwọn.

Kò pọndadan ká lo Àmọ̀tẹ́kùn fún ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀yọ́- Àjọ elétò ìdìbò

Kò pọndadan ká lo Àmọ̀tẹ́kùn fún ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀yọ́- Àjọ elétò ìdìbò

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní ẹni tó wẹjú ni ẹ̀rù n bà.
Àjọ elétò ìdìbò ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (OYSIEC), ti sọ pé àwọn kò níí i ṣàmúlò ikọ̀ elétò ààbò ilẹ̀ Yorùbá tá a mọ̀ sí Àmọ̀tẹ́kùn fún ètò ààbò níbi ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tó ń bọ̀.

Alága àjọ náà, Isiaka Ọlagunju, ló fìdí èyí múlẹ̀ lásìkò àbẹwò tó ṣe sí Correspondents’ Chapel), ìyẹn ẹ̀ka ẹgbẹ́ àwọn oníròyìn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (Oyo NUJ), nílé ẹgbẹ́ wọn tó wà ní Òpópónà Àgọ́ Tapa, ní Mọkọla, n’Íbàdàn.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, “ Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lòfin fún ní ojúṣe pàtàkì jù lọ láti pèsè ètò ààbò lásìkò ètò ìdìbò. Síbẹ̀síbẹ̀, a ti bèèrè fún àtìlẹ́yìn àwọn elétò ààbò mí-ìn bíi sífú dìfẹǹsì, àwọn aláàmójútó ọgbà ẹ̀wọ̀òn, àti bẹ́ẹ̀ , bẹ́ẹ̀ lọ.

Ṣùgbọ́n a kò pe àwọn Àmọ̀tẹ́kùn nítorí àwọn èèyàn kò ní nígbàgbọ́ nínú wọn nígbà tó jẹ́ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ló ni wọ́n, a ò sì fẹ́ nǹkan tó máa tàbùkù ètò ìdìbò yìí ”.

Ọkùnrin amòfin àgbà yìí fi kún un pé “a ò lè torí pé ẹgbẹ́ PDP tó ń ṣèjọba ló yàn wá sípò yìí, ká wá sọ pé ẹgbẹ́ PDP ló gbọdọ̀ wọlé ìdìbò. Ààyè pé à ń kọ ìbò fún ẹgbẹ́ òṣèlú kan ti kọjá lọ, ẹgbẹ́ tí àwọn aráàlú bá dìbò fún jù lọ ló máa wọlé ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà yìí.

Ààrẹ Ọlagunju fìdí rẹ̀ múlẹ̀ síwájú pé àwọn èèyàn tí kò dín ní ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) lajọ náà yóò gbà gẹ́gẹ́ bíi àwọn òṣìṣẹ́ tí yóò ṣètò ìdìbò ọ̀hún, àti pé láìpẹ́ làwọn yóó ṣàyẹ̀wò fáwọn olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú kọ̀ọ̀kan.

Tẹ́ ò bá gbàgbé, láìpẹ́ yìí làjọ OYSIEC kéde ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, (27) oṣù Kẹrin, ọdún 2024, gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ìdìbò àwọn ìjọba ìbílẹ̀ gbogbo níìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Díẹ̀ lára àwọn tó kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú alága àjọ elétò ìbò ìpínlẹ̀ yìí ni Ọ̀mọ̀wé Babatunde Adeniyi, Ọ̀gbẹ́ni Kunmi Agboọla àti Emmanueli Ọlanrewaju.

Díhẹ̀ dìhẹ̀ díhẹ̀, gbèsè Nàìjíríà sún wọ tírílíọ̀nù mẹ́tàdínláàdọ̀rún péré (N87tn)

Díhẹ̀ dìhẹ̀ díhẹ̀, gbèsè Nàìjíríà sún wọ tírílíọ̀nù mẹ́tàdínláàdọ̀rún péré (N87tn)

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kò tó nnkan,kò tó nnkan, ó mà ń dòòyì kọ́ní ńlẹ̀ yí.
Wọ́n ní ó ń bọ̀, ó ń bọ̀, lásìkò yìí gbogbo ara ni wọ́n-ọ́n mú tó o .
Ọ̀rọ̀ ti jọ pé ewu ń bẹ lóko Lóńgẹ́, gbèsè tí orílẹ-èdè Nàìjíríà jẹ ti di tírílíọ̀nù mẹ́tàdínláàdọ́rùn-ún láàrin oṣù mẹ́ta péré.

Ẹ̀ka ìjọba tó ń rí sí ọ̀rọ̀ gbèsè Nàìjíríà, DMO ṣàlàyé pé iye owó yìí ni gbèsè Nàìjíríà lẹ́yìn oṣù mẹ́fà nínú ọdún 2023 yìí.

Èyí túmọ̀ sí pé ìdá márùndínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ni gbèsè náà fi lé síi lẹ́yìn tí gbèsè Nàìjíríà jẹ́ N49tn ní ìparí oṣù kẹta.

Iléeṣẹ́ ìjọba tó ń rí sí ọ̀rọ̀ gbèsè Nàìjíríà ní owó yìí jẹ́ àpapọ̀ gbogbo gbèsè tí Nàìjíríà ń jẹ lábẹ́lẹ́ àti lágbàáyé, tó fi mọ́ gbèsè tí ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì àti Àbújá ń jẹ.

Iléeṣẹ́ náà ní àfikún tiriliọnu tírílíọ́nù méjìlélógún(N22.712tn) ni kókó owó tó gorí gbèsè ọ̀hún.

Ọkùnrin kan tó fẹ ìyàwó méje lẹ́ẹ̀kan náà sọ pé kò sí owú láàrin wọn

Ọkùnrin kan tó fẹ ìyàwó méje lẹ́ẹ̀kan náà sọ pé kò sí owú láàrin wọn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ohun tó bá wolówó ní-ín fowó rẹ̀ rà.N tó bá sì wu ọmọ ọ́n jẹ, kì í run ọmọ nínú ni ọ̀rọ̀ Ssaalongo Nsikonenne Habib Ssezzigu tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí gba orí ayélujára lẹ́yìn tó fẹ́ ìyàwó méje ní ọjọ́ kan náà.

Lára obìnrin méje ní a ti rí ẹ̀gbọ́n àti àbúrò, tí ìgbéyàwó ọ̀hún sì wáyé ní Abule Bugerek lórílẹ̀ èdè Uganda lọ́jọ́ kẹwàá oṣù kẹsàn án ọdún 2023.

Orúkọ àwọn ìyàwó náà ni Mariam, Madinah, Aisha, Zainabu, Fatuma, Rashida àti Musanyusa, tó jẹ́ ìyàwó rẹ̀ àkọ́kọ́ tó ti wà pẹ̀lú rẹ̀ fún ọdún méje.

Nínú àtẹ̀jáde kan tó wà lórí ayélujára, sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀ Caleb Canaan ní ayẹyẹ ìgbéyàwó bẹ̀rẹ̀ ní ago mẹ́jọ àárọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gbé àwọn ìyàwó náà lọ ilé oní dìrí.

“Lẹ́yìn tí ọkọ àti àwọn ìyàwó rẹ̀ ṣe ìbúra, Nsikonenne àti àwọn ìyàwó rẹ̀ méje gun kẹ̀ẹ̀kẹ̀ káàkiri abúlé bí Kalagi, Kasana àti Nakifuma kí wọ́n tó lọ ilé wọn ní ago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ .”

Nsikonenne ra ọkọ̀ bọ̀gìnì tuntun fún àwọn ìyàwó náà, tó sì rọ àwọn ìyàwó náà láti fẹ́ ẹ pẹ̀lú òtítọ́ inú.

“Kò sí owú láàrin àwọn ìyàwó mi. Mo mọ wọ́n ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí mò ṣì pinnu láti fẹ ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú wọn ní ẹ̀kanáà láti ní ìdílé aláyọ̀.”

Nsikonenne ní òun yóò tún fẹ́ ìyàwó sí i lọ́jọ́ iwájú

“Ọmọdé sì ni mí àti pé lọ́jọ́ iwájú, tí Ọlọ́run bá fẹ́ máa fẹ́ ìyàwó sí i .”

Bàbá ọkọ, Hajj Abdul Ssemakula ní fífẹ́ ìyàwó púpọ̀ ló jẹ́ nǹkan tó wà nínú ẹ̀jẹ̀ mọ̀lẹ́bi wọn.

“Bàbá tó bí bàbá mi fẹ́ mẹ́fa, Bàbá mi fẹ́ márùn un, èmi gan fẹ́ fẹ́ mẹ́rin tí a jọ ń gbé ilé kan náà.”

Habib ló ti wá fi ìtàn balẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin tó fẹ́ ìyàwó méje lẹ́ẹ̀kanáà lórílẹ̀ èdè Uganda.

Saidi Balogun wà lórí ‘Wheelchair’ ,ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣàdúrà fun un. 

Saidi Balogun wà lórí ‘Wheelchair’ ,ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣàdúrà fun un.

Fẹ́mi Akínṣọlá

Láìpẹ́ yìí ni àwòrán kan gbà orí ayélujára kan, èyí tó ṣe àfihàn gbajúmọ̀ òṣèré tíátà nnì, Saidi Balogun, tó jókòó sórí kẹ̀kẹ́ onírin tó wà fún àwọn èèyàn tí ẹṣẹ̀ ń dùn.

Àwòrán yìí sí lọ da ọkàn àwọn èèyàn tó wòó láàmú, pàápàá àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.

Ọ̀pọ̀ wọn sì lọ ń fi ìtara pèé lórí fóònù tàbí fi àtẹ̀jísẹ́ ránṣẹ́ sì, bí wọ́n ṣe ń béèrè pé kí ló fàá, tí Saidi Balogun ṣe di èrò orí kẹ̀kẹ̀ onírin, náà ni wọ́n ń gbàdúrà fún pé Ọlọ́run yóò fún ní àlàáfíà.

Èrò ọ̀pọ̀ wọn ní pé ìjànbá kan ló wáyé, tí gbajúmọ̀ òṣèré náà kò ṣe leè rìn bó se yẹ, tó sì ń fi kẹ̀kẹ́ onírin ṣe ẹsẹ̀ rìn.

Èyí ló mú kí Saidi Balogun ṣe tètè ṣàlàyé fáwọn olólùfẹ́ rẹ̀ náà, ìdí tó ṣe ń ló kẹ̀kẹ̀ onírin láti rìn.

Saidi Balogun, nínú fídíò tó gbé sójú òpó Sítágíráàmù rẹ̀ ṣàlàyé pé kò sí ìjàmbá kankan tó ṣe òun, ko ko ko sì ni ara òun le.

Ó ní ère sinimá ni àwọn n ya lọ́wọ́ lásìkò tí òun jókòó sínú kẹ̀kẹ̀ onírin ọ̀hún ní ìbámu pẹ̀lú ipa tí òun kò nínú sinimá àgbéléwò náà.

Kódà, ṣe ni Saidi ń fò sókè, tó sì na apá àti ẹsẹ̀ rẹ̀ láti fi dá àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lójú pé sáká ni ara òun dá

Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà náà wá ń kilọ fáwọn èèyàn tó ń gbé ayédèrú ìròyìn kiri lórí ayélujára pé kí wọ́n ṣọ́ra, kí wọn sì dẹ́kun ìwà aláìdára yìí.

Bákan náà lọ wà fi ẹ̀mí ìmoore rẹ̀ hàn sáwọn olólùfẹ́, ẹbí, ara, ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ tó kàn sí lásìkò tí wọn rí àwòrán náà, tí wọ́n sì ń gbàdúrà fún.