Home Blog Page 88

Aiyedatiwa tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Akeredolu, gómìnà fárígá

Aiyedatiwa tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Akeredolu, gómìnà fárígá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ibi tí erin méjì bá ti kọlura kóóko ibẹ̀ ni yóó jìyà.
Gómìnà Akeredolu àti igbákejì rẹ̀, Aiyedatiwa
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Rotimi Akeredolu ti kọ ẹ̀bẹ̀ tí igbákejì rẹ̀, Lucky Aiyedatiwa rawọ́ rẹ̀ sí i lórí làásìgbò tó ń wáyé lórí ètò òṣèlú tó ń wáyé ní ìpínlẹ̀ náà.

Akeredolu tó ń fèsì sí ẹ̀bẹ̀ Aiyedatiwa gba ọwọ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì rẹ̀ lórí àwọn àkànṣe iṣẹ́, Doyin Odebowale ní Aiyedatiwa ní ẹjọ́ láti jẹ́ níwájú ìgbìmọ̀ ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ ọ̀hún.

Ṣáájú ni Aiyedatiwa ti di gbogbo ẹ̀bi àwọn wàhálà tó ń wáyé lágbo òṣèlú ní ìpínlẹ̀ Ondo ru àwọn olóṣèlú bó o ba o pá, bó ò ba, o bù ú lẹ́sẹ̀.

Ó ní gbọingbọin ni òun wà lẹ́yìn gómìnà Akeredolu bíi iké àti pé òun kò lọ́wọ́ nínú ìwọ́de kankan tako Akeredolu.

Igbákejì gómìnà sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí níbi ìpàdé àwọn akọ̀ròyìn tó pè lọ́jọ́bọ̀ láti fi tọrọ àforíjì lọ́wọ́ gómìnà.

Ó ní ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ àti ọgbẹ́ ọkàn fún òun pẹ̀lú gbogbo ìdójútì tí gómìnà Akeredolu ti kojú látara àwọn ìròyìn tí kò dára tí wọ́n ń gbé kiri nípa ìpínlẹ̀ Ondo láti bí oṣù díẹ̀ sẹ́yìn.

Ó ní òun tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Akeredolu gẹ́gẹ́ bí gómìnà àti adarí àwọn ní ìpínlẹ̀ Ondo.

Aiyedatiwa fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìpèníjà ìlera Akeredolu bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àhesọ ọ̀rọ̀ àìgbọ́-ara-ẹni-yé látọwọ́ àwọn olóṣèlú bí ìpínlẹ̀ náà ṣe ti ń múra sílẹ̀ fún ètò ìdìbò sípò gómìnà lọ́dún 2024.

“Ó pọn dandan fún mi láti sọ ní gbangba pé èmi àti Gómìnà Akeredolu kò fìgbà kankan ní gbọ́nmi si omi ò to àti pé kò sí ìgbà kankan tí òun fojú kéré rẹ̀.”

Igbákejì gómìnà wá kan sáárá sí Akeredolu àti adarí àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC fún ipa tí wọ́n kó láti paná aáwọ̀ òṣèlú tó dìde ní ìpínlẹ̀ náà àti ọ̀nà tí gómìnà gbà láti fi bá àwọn ilé aṣòfin sọ̀rọ̀ lórí ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n gbà láti fi paná aáwọ̀ òṣèlú dípò ìyọninípò.

Ẹ̀wẹ̀, Odebowale nínú àtẹ̀jáde tó fi síta tako Aiyedatiwa pé gómìnà Akeredolu kò ní kí ilé aṣòfin má ṣe iṣẹ́ wọn bí wọ́n ṣe fẹ́ ṣe é.

Ó fi kun bákan náà pé irọ́ ni Aiyedatiwa ń pa pé òun kò lọ́wọ́ nínú ìwọ́de kankan tako gómìnà Akeredolu.

Ó ní gómìnà Akeredolu tó jẹ́ àgbà am òfin fúnra rẹ̀ kì í dá sí ọ̀rọ̀ àwọn aṣòfin nítorí ó mọ̀ pé wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti ṣe iṣẹ́ wọn láìsí ìdíwọ́ kankan lábẹ́ òfin àti pé gómìnà kò bẹ àwọn aṣòfin láti dá ìgbésẹ̀ láti yọ Aiyedatiwa dúró.

Ojú òpópó orílẹ̀ yìí tí di pàkúté ikú láse ra ọkọ̀ Land Cruiser – Àwíjàre aṣòfin àgbà

Ojú òpópó orílẹ̀ yìí tí di pàkúté ikú láse ra ọkọ̀ Land Cruiser – Àwíjàre aṣòfin àgbà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iṣẹ́ ìlú kò ṣe é gira ṣe.
Ilé aṣòfin àgbà Nàìjíríà ti ní kò sí ohun tó burú nínú pé àwọn fẹ́ ra ọkọ̀ Toyota Landcruiser tuntun fún àwọn ọmọ ilé aṣòfin àpapọ̀.

Iye tí ọkọ̀ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fẹ́ rà jẹ́ ọgọ́jọ mílíọ̀nù náírà yàtọ̀ sí ọkọ̀ arọ́ta ìbọn dànù tí wọ́n fẹ́ rà fún Ààrẹ ilé aṣòfin àti igbákejì rẹ̀ Godswill Akpabio àti Barau Jibrin.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ àwọn aṣòfin náà pé wọn kò bìkítà bí ìyà ṣe ń bá ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí fínra tí wọ́n fi fẹ́ kó ọ̀bítíbitì owó láti fi ra ọkọ̀.

Àjọ Human Rights Writers Association (HURIWA) ní bí ìgbà pé àwọn aṣòfin náà fẹ́ mọ̀ ọ́n-mọ̀ tigi bọ àwọn ọmọ Nàìjíríà lójú ni èròńgbà láti ra àwọn ọkọ̀ náà lásìkò tí àwọn kan kò rí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀mẹta jẹ ní oòjọ́.

HURIWA ní owó tí wọ́n fẹ́ fi ra àwọn ọkọ̀ náà ló yẹ kí wọ́n fi ṣe àwọn nǹkan amáyédẹrù sí ìlú.

Bákan náà ni àjọ Socio-Economic Rights and Accountability Project (SERAP) ní kí ilé ẹjọ́ gíga kan ní ìpínlẹ̀ dá ilé aṣòfin àpapọ̀ dúró lórí ọkọ̀ tí wọ́n ń gbèrò láti rà náà.

Àmọ́ ilé aṣòfin àgbà ní àwọn aṣòfin nílò àwọn ọkọ̀ ọ̀hún fún iṣẹ́ wọn ni àwọn ṣe fẹ́ ra àwọn ọkọ̀ náà.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, alága ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn aṣòfin Sunday Karimi ní bí àwọn èèyàn ṣe ń bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn kò dára tó.

Karimi ní ọ̀pọ̀ àwọn Mínísítà ló ní ọkọ̀ mẹ́ta tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ àmọ́ àwọn ni àwọn ọmọ Nàìjíríà máa ń dójú ìjà kọ.

Ó ní ó yẹ kí àwọn ọmọ Nàìjíríà máa tọná wádìí àwọn Mínísítà àtàwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ wọn ló ń lo àwọn nǹkan tó dára ju ti àwọn lọ.

“Ọ̀pọ̀ àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ ni àwọn gómìnà ti máa ń ra ọkọ̀ bọ̀gìnì kalẹ̀ fún kí wọ́n tó búra wọlé fún wọn kódà bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀.”

Ó fi kun pé nítorí àwọn ọ̀nà Nàìjíríà tí kò dára ni àwọn ṣe fẹnukò láti ra Land Cruiser kí ó lè tọ́jọ́.

Karimi ṣàlàyé pé tí òun bá lọ sí ẹkùn tòun ń ṣojú nílé aṣòfin àgbà, owó kékeré kọ́ ni òun máa ń ná sí ọkọ̀ nítori àwọn ọ̀nà tí kò dára.

Ó ní àwọn kò bá tún ra àwọn ọkọ̀ ọ̀hún lọ́wọ́ àwọn tó ń pèsè ọkọ̀ ní Nàìjíríà àmọ́ iye àtàwọn nǹkan míì ló jẹ́ kí àwọn padà pinnu láti ra SUV náà.

Ogún Mohbad wà lára n tó n dìjà sílẹ̀ láàrin ẹbí méjèèjì- Iyabo Ojo

Ogún Mohbad wà lára n tó n dìjà sílẹ̀ láàrin ẹbí méjèèjì- Iyabo Ojo

Fẹ́mi Akínṣọlá

Yorùbán ní bí
ọ̀rọ̀ ńlá kò bá tí í tán, èèyàn ńlá kò ní-ín sinmi àròyé.
Gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin onítíátà ilẹ̀ wa nnì, Iyabo Ojo, ti tún ṣí aṣọ lójú eégún lórí ọ̀rọ̀ ìjà ojoojúmọ́ tó ń lọ láàrin ẹbí Olóògbé Mohbad àti Wunmi tí í ṣe ìyàwó rẹ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ tí Iyabọ Ojo sọ lórí ètò kan lórí ẹ̀rọ ayélujára lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹtádínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹwàá, ọdún 2023 yìí, ló ti sọ pé àwọn dúkìá olóògbé ọ̀hún kọ̀ọ̀kan tó wà níkàáwọ́ ẹbí ìyàwó olóògbé náà ló n díjà sílẹ̀ láàrin àwọn ẹbí méjèèjì nígbà gbogbo.

Àìmọye ìgbà ni Alàgbà Joseph Alọba tí í ṣe bàbá olóògbé ti fẹ̀sùn kan ẹbí ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé àwọn gan-an ni kò jẹ́ kí ọmọ òun gbé ohun gidi ṣe fóun làtìgbà tí ìràwọ̀ rẹ̀ ti gòkè nídìí iṣẹ́ tó yàn láàyò.

Iyabo Ojo ní, ‘ Kì í ṣe ìròyìn mọ́ rárá pé bàbá olóògbé yìí kì í fi bò nígbà gbogbo tó bá lanfaani láti bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ pé ìyàwó ọmọ òun àtàwọn ẹbí rẹ̀ ni wọn kò jẹ́ kí ọmọ òun ṣètọ́jú òun nígbà ayé rẹ̀. Bàbá olóògbé pàápàá tiẹ̀ ti fìgbà kan pè mí rí lórí fóònù, tó sì sọ b’áwọn ẹbí ìyàwó ọmọ rẹ̀ ṣe ti gbẹ́sẹ̀ lé àwọn dúkìá ọmọ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan, mi ò fara mọ́ èyí rárá ’.

Bákan náà ló jẹ́ pé àwọn ẹ̀sun ńlá gbogbo ti bàbá olóògbé fi kan ìyàwó ọmọ rẹ̀ kò dùn mọ́ ìyàwó yìí nínú rárá, tó sì ń fojú kò tọ́ wo bàbá ọkọ rẹ̀ báyìí.

Ìrọ̀lóyè Ghandi ti dá ògo àti orúkọ rere ìdílé wa padà – Ìdílé Laoye

  • Ìrọ̀lóyè Ghandi ti dá ògo àti orúkọ rere ìdílé wa padà – Ìdílé Laoye

IKÚ Ò MẸWÀ

Hafsat Olúwatóyìn aya Sanni

*IKÚ Ò MẸWÀ*

Ìlẹ̀kẹ̀ já tòun tòwú
Ọ̀pẹ nàró kádún
A ò rónkọ
Ẹnu dẹ̀ẹ̀rẹ̀ kalẹ̀
A ò róùn pèdè
Ahéré padà rẹ́yìn olóko
Ọkọ́ àgbẹ̀ la fi bàṣírí àgbẹ́
Òṣùpá wọ̀òkùn
Ìràwọ̀ já
Ìyẹ́ lá rí
A wòréré tí tí tí
Ìríran jìngòdò
A ò rábọ̀ ẹyẹ
Gbàgọ̀dọ̀ já
Ìṣu àgbẹ̀ ṣòfò
Apẹ́ fọ́
Ẹ wo bójú omi ṣe pọ́n olóko.
Ẹ má ràròkàn pẹ́ títí
Ẹ má barajẹ́ kánrin
Òòrùn tó kù yí
Ó tó sàtúnṣe ìgbààìmọ̀
Àgbáyéju ò ì gbẹ̀bí
Ká tètè dẹrù níwọ̀n
Wọn kìí sọni lálède
Kóówá ni yóó lòwà ẹ̀sìn tú ti ẹ̀ fóníbodè ní gbàgede.
Àtúnṣe ìwà kò sí níbojì.
Sánni ti lọ
Èmi wà
Ìwọ ń bẹ
Kín la á fi ròyìn mi?
Kín la á fi ròyìn rẹ?

Fẹ́mi Akínṣọlá

Adeleke fagi lé ìrìnàjò sí Òkè-Òkun fáwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun

Adeleke fagi lé ìrìnàjò sí Òkè-Òkun fáwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ ti di sọ́wóná báyìí o, bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Sẹ́ẹnétọ̀ Ademọla Adeleke, ti pàṣẹ pé títí tí ọdún 2023 tí a wà yìí yóò fi parí, kò sí ọ̀gá àgbà nínú iṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ náà tó gbọdọ̀ rin-ìrìnàjò lọ sí òkè-òkun.

Ó ní ìgbésẹ yìí wáyé láti dín owó tí ijọba ń ná kù, kí ìjọba sì lè gbájú mọ́ àwọn iṣẹ́ àkànṣe tó yẹ láti ṣe, nítorí ìrètí àwọn aráàlú pọ̀ látọ̀dọ̀ ìjọba.

Lásìkò ìpàdé àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹlẹ́ẹ̀kejì irú ẹ tó wáyé nílùú Oṣogbo, lọjọ Tọ́sìdeè, ní Gómìnà ti ṣàlàyé pé gbogbo àwọn lọ́gàálọ́gàá náà ni wọ́n ní iṣẹ́ pàtàkì láti ṣe pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ lórí àgbékalẹ̀ ètò ìṣúná ọdún tó ń bọ̀.

Adeleke sọ síwájú pé ṣe ni kí àwọn lọ́gàálọ́gàá náà máa darapọ̀ mọ́ ìpàdé Òkè-òkun tí wọ́n bá ní nípasẹ̀ ìkànnì ayélujára.

Ó ní tí irú ìpàdé bẹ́ẹ̀ bá wáá jẹ́ pàjáwìrì, tó sì pọn dandan fún irú ọ̀gá bẹ́ẹ̀ láti lọ, wọ́n ní láti gba àṣẹ latọdọ Gómìnà fúnra rẹ̀.

Bákan náà ni Adeleke tún sọ fún olórí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun níbi ìpàdé náà láti ṣe àkọsílẹ ojúṣe àwọn kọmíṣánnà àti àwọn olùdámọ̀ràn pàtàkì fún Gómìnà.

Adeleke pàṣẹ pé, láti àsìkò náà lọ, àwọn olùdámọ̀ràn pàtàkì gbọdọ̀ kọkọ máa fún àwọn Akọ̀wé-àgbà ní lẹ́tà tí wọ́n bá fẹ́ẹ́ fi ránṣẹ́ sí kọmíṣánà iléeṣẹ́ tí wọ́n wà.

Ó ní eléyìí yóó dènà ìwà ‘emi-ju-ọ, iwọ-o-ju-mi láàrin àwọn kọmíṣánnà àtàwọn olùdámọ̀ràn pàtàkì.

Ilé aṣòfin Òndó sì ń dọdẹ yíyọ igbákejì Gómìnà nípò

Ilé aṣòfin Òndó sì ń dọdẹ yíyọ igbákejì Gómìnà nípò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Egbìnrìn ọ̀tẹ̀,bí wọ́n ṣe n pàkan lòmíràn n rú tú ú.
Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Òndó ti kọ ìwé ìpè tuntun ránṣẹ́ sí adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ náà, adájọ́ Olusegun Odusola, pé kó ṣe àgbéǹde ìgbìmọ̀ tí yóó tọpinpin ẹ̀sùn aṣemáṣe tí wọ́n fi kan ìgbákejì Gómìnà, Ọ̀gbẹ́ni Lucky Aiyedatiwa.

Ìwé náà ti olórí ilé, Olamide Oladiji buwọ́lù, ṣàlàyé pé ilé tẹ̀síwájú láti gbé ìgbésẹ̀ yíyọ ìgbákejì Gómìnà náà lẹ́yìn tí gbèdéke àṣẹ tí ilé ẹjọ́ gíga gbé kalẹ̀ wá sí òpin.

Ìwé náà sọ pé ”Lọ́jọ́ kẹta oṣù kẹwàá ni ilé bèèrè pé kí Olúwa mi ó ṣe àgbéǹde ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni méje, tí yóó ṣe àgbéyẹ̀wò ẹ̀sùn aṣemáṣe tí ilé fi kan Lucky Aiyedatiwa, ni ìbámu pẹ̀lú ìwé òfin Nàìjíríà .”

Ó fi kún un pé, adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ náà ló ti fi àákè kọrí tẹ́lẹ̀ pé òun kò ní gbé ìgbésẹ̀ kankan lórí àgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ oluwádìí náà, bí wọn kò bá yanjú àṣẹ tí ilé ẹjọ́ gíga ti pa ṣaájú nípa ìgbésẹ náà.

Àmọ́ ó ní ní báyìí tí gbèdéke lórí àṣẹ tí ilé ẹjọ́ gíga gbé kalẹ̀ ti wá kọjá, ilé aṣòfin ní àsìkò ti tó, bẹ́ẹ̀ sì ni ààyè wà kí adájọ àgbà ṣe àgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ ìwádìí yìí.

Ìgbésẹ̀ tí ilé aṣòfin fẹ́ gúnlè báyìí ń wáyé lẹyìn bí ọ̀sẹ̀ kan tí ilé kéde pé àwọn ti káwọ rọ̀ lórí ìyọni nípò igbákejì Gómìnà lẹ́yìn tí àwọn olórí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress APC dá si ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

Dókítà Olaleye, tó fipá bá ọmọdé lòpọ̀, rí ẹ̀wọ̀n gbére he

Dókítà Olaleye, tó fipá bá ọmọdé lòpọ̀, rí ẹ̀wọ̀n gbére he

Fẹ́mi Akínṣọlá

Èèyàn tó n yọ́lẹ̀ dà, ohun abẹ́nú a máa yọ́rú u wọn ṣe.
Ilé -ẹjọ́ tó gbọ́ ẹjọ́ nípa ìbánilòpọ̀ tó ń jókòó nílùú Ikeja ti rán Dókítà Ilé-iṣẹ́ Optima Cancer Care Foundation kan, Olufemi Olaleye lọ sí ẹ̀wọ̀n gbére fún ẹ̀sùn pé ó fipá bá àbúrò Ìyàwó rẹ̀ lòpọ̀. tó sì tún fi fi nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ síi lẹ́nu.

Adájọ́ Rahman Osodi ló gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀ lẹ́yìn tó jẹ́ kó di mímọ̀ pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé ó bá ọ̀dọ́mọbìnrin, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lòpọ̀, tó sì tún já ìbàlé rẹ̀.

Adájọ́ ní Dókítà kùnà láti fi ẹ̀rí hàn pé kò jẹ̀bi àti pé gbogbo ẹ̀rí tó wà ní ilé ẹjọ́ fihàn pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn ọ̀hún.

Olaleye ní Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó fẹ̀sùn méjì kan tó sì dá lórí pé ó fipá bá àbúrò ìyàwó rẹ̀ lòpọ̀.

Ṣaájú ni Olaleye ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun lọ́jọ́ Kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá ọdún 2022.

Agbẹjọ́rọ̀ fún ìjọba, Babajide Martins ní láàrin oṣù Kejì ọdún 2020 sí oṣù kọkànlá ọdún 2021 ni Dókítà dá ẹ̀ṣẹ̀ náà.

Ó ní ìṣẹlẹ̀ náà wáyé ní ojúlé kẹtàdílógún, ní àgbègbè Layi Ogunbambi, Maryland ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Wọ́n fi ẹ̀sùn kan Olaleye pé ó fipá bá ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lòpọ̀, ẹni tí í se àbúrò ìyàwó rẹ̀, tó sì já ìbàlé ọ̀dọ́bínrin ọ̀hún, ní ìlànà tí kò bá òfin mu.

Bákan náà ni wọ́n fẹ̀sùn kan Olaleye pé ó fi tipá fi nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ sí ọmọ náà lẹ́nu.

IIé-ẹjọ́ tó ga jù lọ tèsíwájú lórí àwọn ẹ̀sùn tuntun t’Atiku fi kan Tinubu

IIé-ẹjọ́ tó ga jù lọ tèsíwájú lórí àwọn ẹ̀sùn tuntun t’Atiku fi kan Tinubu

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ní bí ọ̀rọ̀ ńlá kò bá tíì tán,èèyàn ńlá kò ní-ín sinmi àròyé n lọ̀rọ̀ dà báyìí
Bí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn ṣe ń fojú sọ́nà, tí gbogbo inú kóòtù sì pa rọrọ láti gbọ́ ibi tí ìdájọ́ yóó forí sọ lórí ẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn tí Alaaji Atiku Abubakar, olùdíje fúnpò Ààrẹ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP), nínú ètò ìdìbò gbogbogboo tó wáyé lóṣù Kejì, ọdún 2023 yìí, pè ta ko Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu, láti ẹgbẹ́ All Progressives Congress (APC), síwájú ilé-ẹjọ́ tó ga jù lọ nílẹ̀ wa, to wa niluu Abuja, àwọn adájọ́ náà ti gbé ìpinnu wọ́n kalẹ̀, wọ́n láwọn kò tí ì lè ṣe ìdájọ́ ojú-ẹsẹ̀ lórí atótónu àti àwíjàre olùpẹ̀jọ́ àti olùjẹ́jọ́, pàápàá lórí ẹ̀bẹ̀ tí Atiku tún bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n gba àwọn ẹ̀sùn tuntun tóun lọ̀ọ́ gbà nílẹ̀ Amẹ́ríkà lòdì sí Tinubu wọlé, wọ́n láwọn yóó gbé ìdájọ́ àwọn kalẹ̀ tó bá yá.

Eyi waye nigba ti Onidaajọ Inyang Okoro n ka ipinnu igbimọ onidaajọ naa sawọn eeyan leti lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtalelogun, yii.

Ṣaaju lawọn adajọ naa ti kọkọ ke si awọn lọọya to ṣoju ọkọọkan olupẹjọ ati olujẹjọ lati yẹ iwe ẹsun ati awijare koowa wọn, eyi ti igbimọ to n gbọ awuyewuye lori ẹsun to su yọ nibi idibo aarẹ, iyẹn Presidential Election Petition Tiribunal to ti kọkọ ṣedajọ lori ẹjọ naa fi ṣọwọ si wọn.

Wọn si ni ki awọn lọọya naa buwọ luwe lati fara mọ alaye, awijare ati atotonu koowa wọn, boya o peye, eyi ti ọkọọkan wọn ṣe bẹẹ.

Awọn adajọ naa tun tẹti bẹlẹjẹ si ẹbẹ pataki kan ti Amofin agba Chris Uche, to jẹ agbẹjọro Atiku Abubakar bẹ ọba awọn kootu naa pe ki wọn tẹwọ gba awọn ẹsun tuntun toun ko wa, eyi to da lori bi wọn ṣe ni Tinubu yiwee, o ṣe ayederu sabukeeti, o si purọ labẹ ibura.

O lonibaara oun rọ ile-ẹjọ lati wo awọn ẹsun ati ẹri wọnyi, ki wọn wo bo ṣe tẹwọn to, ki wọn si ṣedajọ ododo. O ni adura onibaara oun, iyẹn Atiku, ni pe kile-ẹjọ giga ju lọ yẹ aga mọ ọn nidii, ki wọn si da a lẹbi, pe ko kunju oṣuwọn lati waa dije tabi wa nipo aarẹ.

Àmọ́, isọrọ-nigbesi, loju-ẹsẹ lawọn lọọya olujẹjọ, ìyẹn Amofin àgbà Abubakar Mahmoud, to ṣoju fún àjọ elétò ìdìbò ilẹ wa, Independent National Electoral Commission (INEC), ati Amofin àgbà, Olóyè Wọle Ọlanipẹkun, tó ṣojú fún Ààrẹ Bọla Tinubu, àti Amofin àgbà Akin Olujimi, tóun dúró fún ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC, ti nawọ soke, ti wọn si ta ko ẹbẹ Atiku, wọn ni kile-ẹjọ naa ma ṣe gba awọn ẹsun tuntun wọnyi wọle, tori ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ, ti ko si nitumọ ni. Eyi lawọn agbẹjọro naa ṣe fa-n-fa-a mọ ara wọn lọwọ tile-ẹjọ náà fi lọ fún ìsinmi ráńpẹ́.

  1. Nígbà tíjokòó bẹ̀rẹ̀ padà, àwọn adájọ́ ọ̀hún fẹnu kò pé àwọn máa lọ̀ọ́ yiiri gbogbo ẹ̀bẹ̀ àti àwíjàre wọ̀nyí wò, àwọn yóó sì gbé ìdájọ́ kalẹ̀ tó bá yá.

Ọwọ́ ọlọ́pàạ́ ìpínlẹ̀ Ògùn tẹ ọkùnrin tó fipá bá wòlíìbìrin láṣepọ̀ ní ṣọ́ọ̀ṣì

Ọwọ́ ọlọ́pàạ́ ìpínlẹ̀ Ògùn tẹ ọkùnrin tó fipá bá wòlíìbìrin láṣepọ̀ ní ṣọ́ọ̀ṣì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìwé mímọ́ sọ pé bí òpin ayé bá kù dẹ̀dẹ̀, onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ à gbọ́ ṣe hàà ni yóó ṣẹ̀lẹ̀ ọ̀kan ni èyí, tí Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn ṣẹ̀rí ẹ̀ pé ọwọ́ àwọn ti tẹ ọkùnrin, ẹni ogójì ọdún kan, Lekan Sunday, ti wọ́n fi ẹ̀sùn kan pé ó f’ipá bá wòlíì obìnrin láṣepọ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì.

Ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni wọ́n sọ pé Sunday f’ipá bá wòlíì obìnrin náà láṣepọ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀, tó wà ládugbó Ilogbo Adu, Kemta nílùú Abẹokuta, kí ọwọ́ tó tẹ̀ ẹ́ .

Ojú oorun ni wọ́n sọ pé ìyá wòlíì náà wà nígbà tí Sunday fi digun wọ ṣọ́ọ̀ṣì ọ̀hún pẹ̀lú àwọn nǹkan ìjà, kí ó tó fi tipátipá ṣí ìyá wòlíì náà láṣọ wò lẹ́yìn tó ti dúnkookò mọ́ ọ.

Ìròyìn tó tẹ wá lọ́wọ́ sọ pé ní ṣe ni Sunday yọ ọ̀bẹ sí obìnrin náà, tó sì fi halẹ̀ mọ́ ọn pé bí kò bá gbà nǹkan tóun wá ṣe, òun yóò gun pa.

Ìyá wòlíì náà pariwo ìbosi ará àdúgbò títí láì sí ẹni tó gbọ́ ariwo rẹ̀ rárá.

Nígbà tó ń f’ìdi ìròyìn ọhún múlẹ̀, agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn, Ọmọlọla Odutọla sọ pé iṣẹ́ bíríkìlà ni Sunday ń se lágbègbè Kemta.

Odutọla ní wòlíì náà dá Sunday mọ̀ dáadáa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé alẹ́ ló fi lọ ká a mọ́ ṣọ́ọ̀ṣì láti ṣe iṣẹ́ ibi náà,

Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ni ìpínlẹ̀ Ògún náà ṣàlàyé síwájú síi pé ní kété tí ọwọ́ àwọn agbófinró ti tẹ̀ ẹ́, ní ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀, kó tó di pé àwọn f’ójú rẹ̀ ba ilé-ẹjọ́.