Home Blog Page 64

Lẹ́yìn tí Mbappe ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wọ ìbòjú, ó mi àwọ̀n l’ẹ́ẹ̀ mejì.

Lẹ́yìn tí Mbappe ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wọ ìbòjú, ó mi àwọ̀n l’ẹ́ẹ̀ mejì.

Gbọ́láhàn Quseem

Ọ̀dọ́mọdé elégèé àrà tó jẹ́ ọmọ orílé-èdè France, Kylian Mbappe, mi àwọ̀n méjì nínú eré bọ́ọ̀lù tí ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù orílẹ́-èdè rẹ̀ gbá, lẹ́yìn tó fi imú ṣèṣe.

Mbappe fi imu ṣeṣe ninu ere bọọlu akọkọ ti orilẹ-ede France gba pẹlu orilẹ-ede Austria ninu idije Euro 2024 to n lọ lọwọ.

Mbappe wọ iboju gba bọọlu fun wakati kan,ninu ifigagbaga ti wọn fi n segbaradi ẹgbẹ agbabọọlu Germany.

Mbappe to jẹ balogun ẹgbẹ agbabọọlu France ko le kopa kankan ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye laarin ikọ agbabọọlu Les Blues ati Netherlands ninu eyi ti wọn ti ta ọmi ayo 0-0.

Ọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu alafẹsẹgba lo sọ pe Mbappe ko ba mi awọn ti o ba ni anfani lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ France ati Netherlands ti wọn ti ta ọmi odo-odo .

Amọ, lọjọ Abamẹta ni Mbappe kopa ninu ere bọọlu ọlọọrẹsọọrẹ pẹlu Paderborn t’ilu Germany, ninu eyi to ti gba ami meji wọle.

O ṣeeṣe ki Mbappe wọ iboju rẹ lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ọjọ Iṣẹgun ti yoo waye laarin France ati Poland.

Ṣaaju idije Euro 2024 ni Mbappe fi ẹgbẹ agbabọọlu PSG silẹ lọ darapọ mọ ikọ Real Madrid lorilẹ-ede Spain.

N ò lè dá èdè Lárúbááwá fi ṣàdúrà,ni mo ṣe di kítẹ́nì —–  Adewale Ayuba .

N ò lè dá èdè Lárúbááwá fi ṣàdúrà,ni mo ṣe di kítẹ́nì —–  Adewale Ayuba .

Ọrẹ Òtítíjù

Gbajúmọ̀ olórin Fújì t’áyé mọ̀ bí ẹni mọ owó nnì Adewale Ayuba, ti bó ọ̀rọ̀ lójú bó ṣe kúò nínú ẹ̀ṣìn mùsùlùmí bọ́ sínú ẹ̀sìn kítẹ̀nì ní bíi ọdún mélòó kan sẹ́yìn .

Laipẹ yii ni olorin Fuji Bonsue ẹ naa pe ẹni ọdun mọkandinlọgọta (59) loke eepẹ.

Nibi ifọrọwerọ ti Akọroyin ṣe fun agba akọrin yii, lo ti ṣalaye idi to fi kuro ninu ẹsin Islam ti wọn bi i si, to si di Kítẹ̀nì lati ọdun 2010.Nigba to n ṣalaye idi to fi di Kìtẹ́nì, Ayuba sọ pe,

‘’Mo yan Jesu Kírísítì laayo nitori ti o kede pe emi ni otitọ, ọna ati iye’’

‘’Ohun to wu mi lọkan mi ni, o si maa n munu mi dun. Ibaṣepọ eeyan pẹlu Ọlọrun to yan laayo maa n ti ọkan wa ni.

‘’Nigba ti mo n ṣe ẹsin Islam, ṣe wọn ri mi ni mọ́ṣálááṣí ni. Ko sẹni to waa ba mi pe mi o kirun wakati marun-un, ọrọ aye mi ko kan wọn.

‘’Awọn obi eeyan lo le ba eeyan sọrọ lori aye rẹ, ara ita ko le ṣe e. Bi wọn ba sọ fun mi ti mo ni ki lo kan wọn nibẹ nkọ.

‘’Alaaja ni mama mi, baba mi o lọ si Mẹ́kà ṣugbọn gbogbo wa la n ṣe Islam nile wa nigba yẹn. Ayuba lorukọ mi, Job ninu Bibeli.

‘’Mo di Kìtẹ́nì nitori ohun ti wọn n sọ ye mi, mi o mọ keu, mi o gbọ Lárúbááwá.

‘’Ti mo ba fẹẹ ba Ọlọrun sọrọ, ma a ṣẹṣẹ maa pe awọn aafaa ki wọn wa ba mi sọ ọ. Mo si beere lọwọ ara mi pe ṣe bi maa ṣe maa ba a lọ ree, mo ṣe ohun to yẹ ki n ṣe, nitori mo fẹẹ sun mọ Ọlọrun mi bo ṣe yẹ.

’’ Mo kuro ninu ẹsin Islam nitori ki n le jọsin nilana to rọ mi lọrun, ti mo si ri i pe Oluwa sun mọ mi pẹkipẹki.

‘’Mo maa ni lati lọ sile keu ti mo ba fẹẹ maa ṣe Islam lọ ki n too le ba Ọlọrun mi sọrọ, abi ki n maa ran eeyan si i.

‘’Mi o si ni asiko lati kọ keu tori iṣẹ mi ni mo ṣe mu eyi to rọ mi lọrun ti mo si sunmọ Ọlọrun mi.

‘’Mi o foju tẹmbẹlu ẹsin Islam ti wọn bi mi si, koda pupọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ mi ni wọn jẹ Musulumi ti a si jọ maa n gba adura papọ.’’

Ayuba ṣalaye nipa iyawo kan ṣoṣo to ni, to si loun ki i yan ale.

O ni nitori boun ko ba ṣẹ iyawo oun nipa iru iwa bẹẹ, oun yoo ṣẹ Ọlọrun.

Nipa bo ṣe da bii ọmọ ogoji ọdun lasiko yii to ti pe 59, Ayuba sọ pe oun maa n ṣọ ohun toun n jẹ ni.

Olorin Fuji naa sọ pe oun le mu tii nigba mi-in koun ma fi miliiki si i, koun si ma jẹ burẹdi si i pẹlu.

Lakootan, o ni ohun to ba ba kaluku lara mu ni ko jẹ.

Kò dára láti jẹ oúnjẹ ṣíṣe inú firiiji tayọ ọjọ kejì, ó léwu gidi- NAFDAC

Kò dára láti jẹ oúnjẹ ṣíṣe inú firiiji tayọ ọjọ kejì, ó léwu gidi- NAFDAC

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀gá àgbà pátápátá fún ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ tó ń mójútó oúnjẹ jíjẹ àti òògùn lílò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ‘National Agency For Food And Administration And Control’ (NAFDAC), Ọ̀jọ̀gbọ́n Mojisọla Adeyẹye, ti ṣèkìlọ pàtàkì fáwọn ọmọ Nàìjíríà pé wọ́n kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan àwọn oúnjẹ ṣíṣe gbogbo tí wọ́n bá ti gbé sínú firiiji fún ọjọ́ mẹ́ta mọ́, nítorí pé ó lè ṣe ìpalára gidi fún ìlera wọn lọ́jọ́ iwájú.

Ó ní bíi ẹni pé èèyàn ń ṣẹwọ siku aitọjọ ni béèyàn bá ń jẹ oúnjẹ ṣíṣè tí wọ́n gbé sínú fíríìjì fún ọjọ́ mẹ́ta ṣe jẹ́, nítorí pé ikú àìtọ, àrùn àìtó oṣù, ló máa padà ṣe ònítọhùn.

Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù yìí, ló sọrọ náà lásìkò ayẹyẹ àyájọ oúnjẹ lágbàáyé tọdún yìí, èyí tó wáyé l’Abuja, tí í ṣe olú ilẹ̀ wa. Nínú àtẹ̀jade kan tí Alukoro ètò ìròyìn fún àjọ náà, Ọ̀gbẹ́ni Ṣayọ Akintọla, fọwọ́ sí lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ni ọ̀gá àgbà àjọ náà ti ṣèkìlọ̀ pàtàkì ọ̀hún fáwọn aráàlú pé kí wọ́n yé jẹ oúnjẹ sísè tí wọ́n gbé sínú fíríìjiì fún ọjọ́ mẹ́ta mọ́, nítorí ìpalára gidi ló rọ̀ mọ́ ọ.

Àtẹ̀jáde ọ̀hún lọ báyìí pé, ‘ Ọ̀gá àgbà àjọ NAFDAC orílẹ-èdè yìí rọ àwọn aráàlú pé kí wọ́n jáwọ́ nínú jíjẹ àwọn oúnjẹ gbogbo tí wọ́n gbé sínú fíríìji fún ọjọ́ mẹ́ta, ó ní ó ṣeé ṣe kí àwọn kòkòrò àìrí (Bacteria) kọ̀ọ̀kan ti sápamọ́ sínú irúfẹ́ oúnjẹ bẹ́ẹ̀, ó sì lè ṣàkóbá gidi fún ìlera wọn bí wọ́n bá jẹ ẹ́ . Àkóbá náà sì lè padà já sí ikú fún ọ̀pọ̀ èèyàn bí wọn kò bá tètè rí ìtọjú gidi gbà nílé ìwòsàn.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Adeyẹye ní ìdí pàtàkì táwọn ṣe ń ṣèpolongo yìí ni pé jíjẹ́ ojúlówó oúnjẹ gidi kìí ṣe fún ìlera àwọn aráàlú nìkan, ṣùgbọ́n ó ṣe pàtàkì púpọ̀ fún ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú orílẹ-èdè lápapọ̀ ni.

Ó wáá rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n fọwọ́-sowọ́-pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláṣẹ orílẹ-èdè yìí, kí èròngbà wọn láti fòpin sí ikú àìtọ́jọ́ tó lè wáyé nídìí àwọn oúnjẹ tí kò bójúmu rárá lè wá sí ìmúṣẹ .

Ọkọ ìyàwó fósánlẹ̀ lóru jọ́kejì ìdùnú ìgbéyàwó

Ọkọ ìyàwó fósánlẹ̀ lóru jọ́kejì ìdùnú ìgbéyàwó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀jọ́ ẹyẹ ò ní-ín dọjọ́ ọ̀fọ̀ nílé e gbogbo wa ,àṣẹ.
Ṣùgbọn àdúrà yìí kò gbà tórí inú ìbànújẹ́ ńlá àti ìpòrúùru ọkàn làwọn ẹbí, ará àti ojúlùmọ̀ géńdé-kùnrin kan, Olóògbé Daniel Adole, tó kú lọ́jọ́ kejì tó ṣègbeyàwó alárinrin tán wà báyìí.

Oun tá a gbọ́ ni pé ọjọ́ ọdún Iléyá, ìyẹn ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kẹfà, ọdún 2024 yìí, ní olóògbé náà ṣegbeyawo pẹ̀lú ololufẹ rẹ̀ nílé àwọn òbí rẹ̀ tó wà lágbègbè Ochingini Adiko, nijọba ibilẹ Obi, nipinlẹ Benue. Ṣùgbọ́n nígbà tó máa fi di ọjọ́ kejì, ìyẹn ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù yìí kan náà ní ariwo ẹkún ńlá sọ nílé rẹ̀, tí wọ́n sì kéde pé ọkọ tó ṣẹṣẹ ṣègbéyàwó alárinrin tán tifò sánlẹ, ó ti kú pátápátá.

Ohun tó jẹ́ k’ọrọ ikú olóògbé náà ya àwọn mọlẹbi rẹ̀ lẹnu ni pé, ọmọkùnrin náà kò ṣàìsàn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àpẹẹrẹ àárẹ̀ kankan lára rẹ̀ lásìkò tó ń ṣayẹyẹ ìgbéyàwó rẹ̀ ọ̀hún, kokooko lara rẹ̀ le. Bó ṣe ń fò sókè, bẹ́ẹ̀ ló ń rẹrin-in sáwọn alábàáṣe gbogbo tí wọ́n wá bá a ṣàjọyọ pàtàkì náà. Ààrin òru ni nǹkan náà dédé kì í mọ́lẹ lójijì, tó sì kú sínú yàrá lẹgbẹẹ iyawo rẹ̀. Eré àti Àwàdà lásán nì yàwó rẹ̀ kọkọ pè é , ṣùgbọ́n nígbà tí kò dá a lóhùn mọ́ bó ṣe ń pè é nìyàwó figbe bọnu, táwọn aráalé sì sáré síta láti wáá wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀.

Àmọ́, ọ̀pọ̀ tó gbọ́ nípa ikú olóògbé ọ̀hún ló n ṣe ní hàà-hiin.

Àrùn kó̩lé̩rà gbilè̩ ní ìpínlè̩ Eko àti Ogun.

Àrùn kó̩lé̩rà gbilè̩ ní ìpínlè̩ Eko àti Ogun.

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìjáfara léwu lọrọ dà báyìí bí Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn àti ìpínlẹ̀ Èkó ti fìdí ìtànkálẹ̀ àrùn onígbá méjì múlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ kóówá wọn Ogun, èyí ti wọ́n ní ó gba ẹmi èèyàn mẹẹdọgbọn

Ní ìpínlẹ̀ Ògùn. obìnrin kan, ẹni ọdún mejilelọgọta náà ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ ṣọwọ́ àrùn.

O sójú ù mi ko kòró tó bá àwọn akọroyin ní olóògbé náà jáde láyé lásìkò tó ń se ìtọjú ọmọ rẹ̀ tó ní àrùn náà, tí ọmọ náà sì wà lára àwọn èèyàn márùn ún tó wà ní ilé ìwòsan.

Bákan náà ni ìjọba tún jẹ́ kó di mímọ̀ pé èèyàn márùn un ti wà ní ilé ìwòsan báyìí níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọjú àrùn onígbáméjì Kọlẹra

Kọmisana fún ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Ògùn, Tomi Coker sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní Ìjèbú-òde , ní ìjọba ìbílẹ̀ Àríwá Ìjèbú.
Nínú atẹjade tí ẹgbẹ́ àwọn onímọ̀ ìṣẹ́gun ní ìpínlẹ̀ Ògùn fi léde, Alága ẹgbẹ́ náà, Kunle Ashimi ní òtítọ ni pé àrùn náà ti tàn ká, tó sì ń ṣe ìjàmbá ní ìpínlẹ̀ ọgbọ̀n pẹ̀lú ìpínlẹ̀ Ògùn.

Ó wá ránṣẹ́ ibanikẹdun sí àwọn mọlẹbi àwọn èèyàn náà, “Lónìí, àrùn onígbáméjì ti wà ní ìpínlẹ̀ ọgbọ̀n tó fi mọ ìpínlẹ̀ Ògùn, ti ọgbọ̀n èèyàn sì ti kú káàkiri orílẹ-èdè . A gbàdúrà fún àwọn èèyàn náà.”

Ashimi ní ìjọba àti NMA kò kọ etí ikun sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, tí wọ́n sì ń gbé gbogbo ìgbésẹ̀ láti fòpin sí itankalẹ náà.

Bákan náà ní ìpínlẹ̀ Èkó, èèyàn mẹrinlelogun ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn ṣọwọ́ àrùn onígbáméjì báyìí

Ìjọba kéde ọrọ̀ náà lọjọ Eti nígbà tí wọ́n sọrọ nípa àwọn èèyàn tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti bẹrẹ.

Gómìnà Seyi Makinde buwọ́lu ìyànsípò Olakunleyin gẹ́gẹ́ bíi Olubadan

Gómìnà Seyi Makinde buwọ́lu ìyànsípò Olakunleyin gẹ́gẹ́ bíi Olubadan

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti buwọ́lù iyansipo Oba Akinloye Owolabi Olakunleyin gẹ́gẹ́ bíi Olúbàdàn ti ilẹ̀ Ìbàdàn.

Olakunleyin ni yóò jẹ Olúbàdàn ẹkẹtalelogoji nínú ìtàn ilẹ̀ Ìbàdàn.

Gómìnà kéde ìgbésẹ̀ yìí nínú ọrọ̀ kan tó fi léde èyí tó ti buwọ́lu láti ọjọ́ kẹrinla oṣù kẹfà ọdún 2024, ní òun pàṣẹ pẹ̀lú ìlànà tí ìwé òfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ọdún 2000 gbé kalẹ̀.

Nínú atẹjade ti Kọmisọna fún ọrọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ àti oyè jíjẹ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Olusegun Olayiwola fi léde fún àwọn akọroyin, ó ní ìgbésẹ̀ yìí wáyé ní ìlànà tí òfin ti ṣètò nípa oyè jíjẹ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Nínú atẹjade náà, Gómìnà Seyi Makinde kí Olúbàdàn tuntun náà kú oríire, tó sì gbà á ladura pé ìgbà rẹ̀ yóó san gbogbo aráàlú Ìbàdàn.
Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, Ọba Owolabi Olakunleyin ti sọ pé tàbí ṣugbọn kan kò sí, òun ni ipò Olúbàdàn kan.

Lásìkò tí ikọ alabẹwo láti ọdọ Gómìnà Ṣèyí Makinde lọ kí bàbá náà nílé rẹ̀ lágbègbè Alalubọsa, n’Ibadan ló sọ bẹ́ẹ̀.

Alàgbà Ọlakulẹyin ní òun ti ṣetán láti gun ori ìtẹ, àti pé ọpẹ́ ló kàn lọrọ òun.

Alàgbà Ọlakulẹyin tó sọrọ pẹlú ohun tó já geere, sí iyalẹnu ọpọ èèyàn tó wà níbè, sọ pé, “ Inú mi dùn láti rí àwọn ikọ alabẹwo láti ọdọ Gómìnà.

‘’ Nígbà tí wọ́n sọ fún mi pé ẹ ń bọ̀, ẹsẹkẹsẹ ni mo sọ fawọn olóyè mi pé kí wọ́n máa bọ̀, kí wọ́n jẹ́ ká jọ gbà yín lálejò.

‘’ Inú mi dùn pé àwọn èèyàn mìíràn wà níbí pẹ̀lú mi.

‘’Mo ti ṣetán pátápátá. Mo mọ pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn mi. Ó ti sọ pé èmi ni ipò Olúbàdàn kàn, èmi náà sì mọ òdodo pé èmi ló kan, àsìkò mi rè é .’’

Ará ìlú nìkan ló leè fi Olubadan sórí ìtẹ́, kìí ṣe Gómìnà – Rasheed Ladoja ṣàlàyé

Ará ìlú nìkan ló leè fi Olubadan sórí ìtẹ́, kìí ṣe Gómìnà – Rasheed Ladoja ṣàlàyé

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní àìfẹ̀lẹ̀ kébòsí,làì rẹ́ni jó o.
Ọ̀tún Olúbàdàn ti ilẹ̀ Ìbàdàn, Sẹ́nẹ́tọ̀ Rasheed Ladoja ti sàlàyé pé, Gómìnà kọ́ ló làṣẹ láti fi Olúbàdàn tuntun sórí ìtẹ́ .

Gbólóhùn yí jẹyọ lẹ́yìn tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣeyi Makinde sọ pé, òun kò ní ṣètò ìfọbajẹ fún Ọba Owolabi Olakulehin tí wọ́n fà kalẹ̀ láti jẹ Olúbàdàn ti ìlú Ìbàdàn àyàfi tí ipò ìlera rẹ̀ bá wà ní pípé.

Àgbà oyè ilẹ̀ Ìbàdàn, Rasheed Ladọja sọ̀rọ̀ níbi pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ọdún Iléyá tó wáyé nílùú Ìbàdàn, pé kò sí òótọ́ nínú ìròyìn tó gbòde pé òun ló wà nídìí bí Gómìnà Makinde kò ṣe fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ fífi Olúbàdàn tuntun jẹ.

Ladoja sàlàyé pé, ọwọ́ àwọn ará ìlú ni àti fi Olúbàdàn tuntun sórí àpèrè wà, ìgbésẹ̀ náà kò sí lọ́wọ́ Gómìnà Seyi Makinde rárá.

“Ojúṣe Gómìnà ní láti gbé ọ̀pá àṣẹ pẹ̀lú àwọn ohun èlò mìíràn tí Ọba náà yóò máa lò lórí ìtẹ́ fún un, torípé dúkìá ìjọba ni àwọn èròjà náà jẹ́.”
Ladoja sàlàyé pé, Olúwo tìlú Ìbàdàn nìkan ló lágbára láti gbé adé lé Olúbàdàn tuntun lórí, tí Gómìnà yóò sì fún un ní ọ̀pá àṣẹ àti àwọn èròjà yòókù.

Ó tún tenumọ́ pé ìbáṣepọ̀ tó gún régé ló wà láàrin ohun àti Gómìnà Makinde àti pé Gómìnà ti kí òun kú ọdún Iléyá pẹ̀lú ẹ̀bùn tó jọjú.

Ààrẹ Tinubu darapọ̀ kírun yídì Eid-el-Kabir nílùú Eko

Ààrẹ Tinubu darapọ̀ kírun yídì Eid-el-Kabir nílùú Eko

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Ahmed Tinubu darapọ̀ mọ́ àwọn mùsùlùmí láti kírun yídíì ọdún iléyá ní Dodan barracks tó wà ní nílùú Èkó lọjọ Àìkú.

Ọdún Eid Kabir jẹ́ ọdún àwọn mùsùlùmí jákèjádò àgbáyé èyí tí wọ́n máa ń ṣe ní ọjọ́ kẹwàá oṣù Dhual-Hijjah.

Ààrẹ Tinubu gúnlẹ sí yidi náà ní nǹkan bíi agogo mẹsan an ku iṣẹju márùn un lọjọ Àìkú.

Olórí àwọn tó ń bá ààrẹ ṣiṣẹ́, Fẹmi Gbajabiamila, adari ètò àbò ní Nàìjíríà, Nuhu Ribadu; igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Ọbafẹmi Hamzat; Gómìnà tẹlẹ ní ìpínlẹ̀ Èkó, Babátúndé Fashọla, àgbà oníṣòwò nnì, Aliko Dangote at’awọn eekan ìlú mìíràn.

Ṣaájú ni ààrẹ ti kọ́kọ́ darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti woye lórí pàtàkì àjọ̀dún Eid-el-Kabir, èyí tó ní ó mú ìtumọ̀ pàtàkì dání fún orílẹ-èdè Nàìjíríà lọwọ́ yìí.

Nínú ọ̀rọ̀ tó bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ, ààrẹ rọ àwọn ẹlẹsin mùsùlùmí jákèjádò Nàìjíríà láti tẹlẹ ìlànà ifaraẹnijin, ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn sí àṣẹ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ajọdun náà ṣe là á kalẹ .

“Ààrẹ mọ rírì ìfara ẹnijin àwọn ọmọ Nàìjíríà láti ọdún kan sẹyìn bí ìṣèjọba rẹ̀ ṣe ń gbé ìgbésẹ̀ láti fi ẹṣẹ̀ Nàìjíríà lé orí ọnà ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú .”

Ààrẹ Tinubu rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti tubọ máa gbàdúrà fún orílẹ-èdè náà fún àlàáfíà láti jọba bí òun tikara ṣe ń ṣiṣẹ́ láti mú iṣọkan, àlàáfíà àti ìlọsíwájú gogò sí i.

Ó wá tún tẹnumọ pé ìṣèjọba òun ń mú ìgbáyé-gbádùn àlàáfíà àti ètò ọrọ̀ ajé lọkunkundun, kò sì ní sinmi nínú afojusun rẹ̀.

Àwọn Gómìnà ilẹ̀ Yorùbá kò faramọ́ ìdásílẹ̀ ‘Yoruba Nation’

Àwọn Gómìnà ilẹ̀ Yorùbá kò faramọ́ ìdásílẹ̀ ‘Yoruba Nation’

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní èyí wùmí ò wù mí ò wù ọ́,ni kìí jẹ́ á pawọ́ pọ̀ fẹ́bìnrin,ní báyìí, àpapọ̀ ẹgbẹ́ àwọn Gómìnà ìpínlẹ̀ Yorùbá ‘South-West Governors Forum’ ti làwọn ò fara mọ́ ìpolongo kan táwọn alákatakítí kan n ṣe pé kí ẹ̀yà Yorùbá ó dá dúró, èyì tí wọ̀n n pè ní Yorùbá Nation. Ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹwàá, oṣù Kẹfà, ọdún 2024 yìí, ni àpapọ̀ ẹgbẹ́ ọ̀hún bẹnu àtẹ lu ìgbésẹ̀ àti èròngbà àwọn èèyàn ọhun ti wọn n ṣepolongo fún ìdásílẹ̀ orílẹ-èdè Yorùbá Nation báyìí. Pàápàá jù lọ, bí àwọn kan ṣe tún fẹẹ fipa gbajọba ní sẹkiteraiti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, loṣu tó kọjá yìí.

A gbọ́ pé lẹ́yìn ìpàdé pàtàkì kan tó wáyé lọ́jọ́ Ajé ọsẹ yìí, láàrin gbogbo àwọn Gómìnà ilẹ̀ Yorùbá, tó wáyé ní Alausa, niluu Ikeja, ìpínlẹ̀ Èkó, ni wọ́n ti sọ pé kò gbọdọ̀ s’ohun tó ń jẹ́ Yorùbá Nation lorile-ede yìí nítorí pé, ọ̀kan ṣoṣo ni gbogbo wa pata lórílẹ̀-èdè yìí, ẹya Yoruba ko si le pin kuro lara orileede Naijiria rara. Ìpàdé ọhún tó gba àwọn Gómìnà náà tó wákàtí mẹrin ni wọ́n tún lo àkókò náà láti fi kẹdun Olóògbé Rótìmí Akeredolu tó jẹ́ olórí ẹgbẹ́ náà tẹlẹ kó tó ó kú.

Bákan náà ni wọ́n tún gboṣuba ńlá fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Ọgbẹni Lucky Ayedetiwa, bo ṣe rí tikẹẹti ẹgbẹ́ APC to fi fẹẹ dupo Gómìnà ìpínlẹ̀ náà gbà lọwọ́ ẹgbẹ́.

Lára àwọn Gómìnà ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n peju-pesẹ síbi ìpàdé pàtàkì ọ̀hún ni: Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Sanwo-Olu, Gómìnà ìpínlẹ̀, Ondo, Lucky Ayedetiwa, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke Jackson, Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun àti Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì, Ọgbẹni Abiọdun Oyebanji.

Nítorí ipò Olúbàdàn: Ẹgbẹ́ ọmọbàdàn bínú sí Gomina Seyi Makinde

Nítorí ipò Olúbàdàn: Ẹgbẹ́ ọmọbàdàn bínú sí Gomina Seyi Makinde

Ọrẹ Òtìtíjù

Pẹ̀lú bó ti ṣe di oṣù mẹ́ta báyii tí orí ìtẹ̀ Olúbdàn ilẹ̀ Ìbàdàn tí ṣófo, tí ọba mi-in kò sì ti i gorí ìtẹ́, ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ yoruba kaakiri agbaye, Yoruba Youth Socio-Cultural Association (YYSA), ati ẹgbẹ awọn ọmọ ibilẹ Ibadan, Ibilẹ G-7, ti naka aleebu si Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, wọn loun lo n mọ-ọn-mọ fi asiko falẹ lati fi ẹni ti ipo Olubadan kan bayii jọba.

Nigba to n ba akọroyin sọrọ n’Ibadan, Aarẹ ẹgbẹ YYSA, Ọgbẹni Ọlalekan Hammed, sọ pe, “ejo ti fẹẹ maa lọwọ ninu lori ọrọ ifọbajẹ Olubadan lasiko yii.

“Nilẹ toni to mọ yii, o yẹ ka ti mọ ọjọ ti gomina maa gbe ọpa aṣẹ le Ọba Ọlakulẹhin ti ipo Olubadan kan bayii lọwọ. Ohun ti wọn sọ tẹlẹ ni pe nibi ayẹyẹ oku Ọba Lekan Balogun (Olubadan to gbesẹ) ni wọn yoo ti kede igba ti eto iwuye yoo bẹrẹ, ṣugbọn iru iroyin bẹẹ ko jẹ yọ ninu ọrọ ti gomina sọ nibi ayẹyẹ ọjọ Satide yẹn.

“Eyi tumọ si pe a o ti i mọ ọjọ, oṣu tabi ọdun ti Ibadan too maa lọba bayii, bẹẹ, Ibadan ti ni eto to daa ti wọn fi n jọba, ẹni ti ipo ọba kan ko ruju, awọn afọbajẹ ti yan an, wọn si ti fi orukọ rẹ ranṣẹ si ijọba lati oṣu meji sẹyin.

“Nitori naa, a rọ Gomina Makinde lati ma ṣe fi eto yii falẹ mọ, fun alaafia ati idagbasoke ilu Ibadan”.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, l’Olubadan ilẹ Ibadan, Oba Lekan Balogun, waja sileewosan UCH, ti wọn si sinku ẹ nirọlẹ ọjọ keji.

Ipapoda Ọba Balogun lo sun Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Owolabi Akinloye Ọlakulẹhin, siwaju gẹgẹ bii ẹni to kan bayii lati gori itẹ nla naa ni ibamu pẹlu bi wọn ṣe n to oye ọba ilu awọn akọni ilẹ Yoruba naa.

Aarin oṣu kan lẹyin ti ori apere ṣófo lo yẹ ki eto gbogbo ti pari, ki wọn sì gbe ẹni tí ipò ọba ọhun kan gori itẹ, paapaa lẹyin ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ti awọn afọbajẹ Ibadan ti fa Ọba Ọlakulẹhin kalẹ gẹgẹ bii ọmọ oye Olubadan, ti wọn si ti fi orukọ rẹ ranṣẹ si ijọba ipinlẹ Ọyọ.

Lọjọ Abamẹta, Satidé, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii, lariya aṣekagba ayẹyẹ isinku Ọba Balogun waye ni papa iṣere Ọbafẹmi Awolọwọ, to wa l’Oke-Ado, n’Ibadan. Nibẹ lawọn eeyan nireti pe gomina yoo ti kede igba ti wọn yoo fi Olubadan tuntun jẹ.

Ṣugbọn òtúbáńtẹ́ nireti awọn ara Ibadan ja si nigba ti gomina naa sọrọ, to ni o digba ti Ọba Ọlakulẹhin, ẹni ti ko ṣaisan, ti ko fara pa, ba too gbadun, ti ara rẹ ba too mokun daadaa, ki oun too le bẹrẹ eto lati gbe ọpa aṣẹ le baba ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin (84) naa lọwọ gẹgẹ bii ojulowo ọba.

Lati ọjọ Satide, ti gomina ti sọrọ yii lawọn eeyan, titi dori awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ti n bu ẹnu atẹ lu u.

Ninu atẹjade ti Aarẹ ẹgbẹ Ibilẹ G-7, Pasitọ Lanre Ogundipẹ, ati Ọgbẹni Jide Ọlaniyọnu, ti i ṣe akọwe ẹgbẹ naa, fi ṣọwọ sawọn oniroyin, wọn ní ọrọ ti Makide sọ nibi oku Olubadan to fori itẹ silẹ fi han pe gomina naa ko ti i ṣetan lati fi Ọlakulẹhin jọba ni.

Wọn ni, “Loootọ ni gomina fidi ẹ mulẹ pe oun ti fara mọ Ọlakulẹhin ti awọn afọbajẹ fi ranṣẹ si oun, ati pe ilana to yẹ ki wọn tẹle naa ni wọn tẹlẹ lati yan an. Ẹ gbọ, ki lo tun wa n da a duro lati ṣeto bi baba naa yoo ṣe gori itẹ?

“Nigba ti Ọba Balogun ṣẹṣẹ waja loriṣiiriṣii awuyewuye wa lori ọrọ oye Olubadan tuntun. Ṣugbọn lẹyin ti gbogbo awuyewuye wọnyi ti kọja sẹyin, ti ọkan gbogbo eeyan ti balẹ pe ọba tuntun maa gori itẹ, lasiko yii ni Gomina Makinde waa lọọ sọ iru ọrọ yii, pe o digba ti ara Ọba Ọlakulẹhin ba too mokun daadaa ki oun too fi wọn jẹ Olubadan.

“Ki Ọba Ọlakulẹhin gori itẹ Olubadan lai fi akoko ṣofo rara mọ lo pọn Gomina Makinde le lasiko yii. Eyi paapaa ni yoo ṣafihan ifẹ to ni si ilu Ibadan ati ipo ọba Olubadan”.