Home Blog Page 63

Samklef gbóríyìn fún àwo̩n è̩yà Igbo bí wó̩n s̩e ‘ta kété’ sí ìfè̩hónú hàn káàkìri orílè̩ èdè

Samklef gbóríyìn fún àwo̩n è̩yà Igbo bí wó̩n s̩e ‘ta kété’ sí ìfè̩hónú hàn káàkìri orílè̩ èdè

Mary Fágbohùn

Alariyanjiyan agborinjade to di onirohin ori ayelujara, Samklef, ti kan saara fun awon e̩ya Igbo bi won ko se lowo si ifehonu han lodi si ijoba ti ko dara, eyi to n lo lowo kaakiri orile ede.

Irohin jade pe ogooro awon omo Naijiria ni won tu jade ni witiwiti ni Ojobo lati bere ifehonu han kaakiri orile ede lori bi nnkan ko se derun fun mutunmuwa.

Ninu awon irohin kan ni a ti toka si pe awon e̩ya Igbo ti won fi guusu ila-oorun se ibugbe ni won yera fun ifehonu han naa, Samklef wi pe ohun ti o dara ni.

O ni, awon eya ti o wa ni ijoba ni ki won tesiwaju ninu ifehonu han naa.

Ni oju awe X re, o ko o pe: “Olorun yoo bukun awon e̩ya Igbo ni bi won se yera fun ifehonu han. E je ki awon eya to wa ni ijoba gbe agbelebu won.”

 

 

Ilé E̩lé̩gbò̩n-ó̩n Àgbà abala ke̩sàn-án: ‘Mi ò wá síbí láti wá se o̩mo̩-ò̩dò̩’ – Chinwe s̩è’kìlò̩ fún àwo̩n alábàágbé rè̩

Ilé E̩lé̩gbò̩n-ó̩n Àgbà abala ke̩sàn-án: ‘Mi ò wá síbí láti wá se o̩mo̩-ò̩dò̩’ – Chinwe s̩è’kìlò̩ fún àwo̩n alábàágbé rè̩

Mary Fágbohùn

Chinwe ti se’kilo fun awon akegbe re pe oun ko ni gba ki won so oun di omo-odo laarin ile.

Ni aaro Ojobo, Chi saroye nipa bi awon alabagbe re kan ko ni se palemo leyin ti won ba dana tan.

O so fun awon akegbe re ni isori-n-sori pe oun ko ni fun won laaye lati din ipo oun ku si omo-odo nipa sise gbogbo ise to wa ni yara idana.

“Se maa fo abo ati ikoko fun won lati dana ni? Mi o ti sun lati ale ana, ori n fo mi. Mi o wa sibi lati se ise omo-odo ni yara idana o,” o leri.

“Ohun ti a fohunsokan si ni pe, bi o ba ti dana wa a fo abo, wa a pale ohun gbogbo ti o lo mo. Bawo ni maa se so fun awon eni to ye ki won ran ara won lowo lati dana pe ki won fo abo ti enikan fi dana?” O tesiwaju lati so.

Grammy: Wike ò fún mi ní nǹkankan – Burna Boy

Grammy: Wike ò fún mi ní nǹkankan – Burna Boy

Mary Fágbohùn

Olorin olugbafe e̩ye̩ Grammy, Damini Ogulu, ti a mo̩ si Burna Boy, ti so̩ pe ko si oloselu Naijiria kan ti o fun oun ni nǹkan ri.

Ninu ate̩jade to fi lede lori X ni O̩jo̩bo̩, o wi pe Gomina te̩le̩ri, Nyesom Wike ti ipinle̩ Rivers ko mu ileri re̩ se le̩yin ti oun gba ife e̩ye̩ Grammy.

E̩ ranti pe Wike ni o̩dun 2021 kede pe oun yoo fi e̩bun ile ati owo fun Burna Boy bii imo̩riri fun jijawe olubori ife e̩ye̩ Grammy.

Eyi waye le̩yin ti ipinle̩ Rivers seto ayeye ikini kaabo fun Burna Boy leyin ti awo orin re ‘Twice as Tall’ ti o gbe jade gba ife eye awo orin to dara ju lagbaye (Best Global Music Album).

Amo sa, Burna Boy, ninu atejade kan wi pe: “Ko si oloselu ti o fun mi ni nnkan ri. E lo beere lowo Wike ibi ti ile tabi owo ti o fun mi wa. E ro pe mo je aayo yin.”

Ìfè̩hónú hàn káàkìri orílè̩ èdè : Tems sún o̩jó̩ tí yóò gbé fó̩nrán orin rè̩ jáde síwájú

Ìfè̩hónú hàn káàkìri orílè̩ èdè : Tems sún o̩jó̩ tí yóò gbé fó̩nrán orin rè̩ jáde síwájú

Mary Fágbohùn

Olorin Naijiria olugbafe e̩ye̩ Grammy, Temilade Openiyi, ti a mo̩ si Tems, ti sun o̩jo̩ ti yoo gbe fo̩nran orin re̩, ‘Burning’ eyi ti gbogbo eniyan te̩wo̩gba kaakiri, to wa ninu awo orin re̩ ako̩ko̩ ‘Born In The Wild’ jade siwaju dipo ki o gbe jade lonii bi o ti so̩ te̩le̩.

Ninu o̩ro̩ kan to fi lede ni oju awe̩ X re̩, e̩ni ti a fa sile̩ fun ife e̩ye̩ Oscar naa salaye ipinnu re̩ lati bo̩wo̩ fun ife̩honu han to n lo̩ lo̩wo̩ kaakiri orile ede.

O si tun so̩ro̩ lodi si eto ijo̩ba ti ko dara, wi pe o ye̩ ki a gbo̩ ohun awo̩n eniyan.

Tems ko̩ o̩ pe: “Ni bibo̩wo̩ fun ife̩honu to n lo̩ kaakiri ni ile [pelu aami asia Naijiria], mo ti se ipinnu lati sun o̩jo̩ ti maa gbe fo̩nran orin ‘Burning’ jade siwaju.

“Mo n gbadura fun aabo lori awo̩n ti o wa ni ita ni iru asiko yi. Ohun awo̩n eniyan yoo di gbigbo̩.”

Wo ìgbésẹ̀ tí o lè gbé láti ṣí síìmù rẹ bí wọ́n bá dèna rẹ̀ láti fi pè

Wo ìgbésẹ̀ tí o lè gbé láti ṣí síìmù rẹ bí wọ́n bá dèna rẹ̀ láti fi pè

Ọrẹ Òtítọ́jù

Lọ́jọ́ Àìkú tó kọjá yìí, ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù keje, ọdún 2024, ni àwọn ilé-iṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ kan gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ojú òpó ìbánisọ̀rọ̀ kan lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Eyi jẹ ara igbesẹ to kẹyin lati gbegidina ipe awọn to kọ lati so nọmba NIN wọn papọ mọ siimu wọn.

Titi di asiko yii ni ọpọ araalu n kọminu lori bi awọn ileeṣẹ ibanisọrọ naa ṣe gbegidina awọn nọmba ibanisọrọ awọn onibara wọn, paapaa awọn ti wọn ko tii so nọmba idanimọ NIN papọ mọ siimu wọn.

‘Ki lo ṣẹlẹ’, abi foonu mi ti bajẹ ni’…wọnyi ati awọn ọrọ kayeefi miran lo n jade lẹnu ọpọ awọn onibara MTN, nigba ti wọn ṣakiyesi pe awọn ko le pe jade, bẹẹ si ni awọn ko le yẹ iye owo ku lori siimu wọn, pẹlu awọn nnakn miran.

Inu oṣu kejila, ọdun 2020 ni ijọba apapọ Naijiria paṣẹ fun gbogbo awọn ileeṣẹ eleto ikansira-ẹni bii MTN, Airtel, Glo, Etisalat ati awọn miran lati so nọmba idanimọ (NIN) awọn onibara wọn papọ mọ siimu wọn.

Eyi ni ijọba sọ pe yoo fopin si iwa ijinigbe, iṣẹkupani, igbesunmọmi ati oniruuru iwa ọdaran miran.

Ijọba apapọ sọ pe ki awọn ileeṣẹ eleto ikansira-ẹni yii gbegidina ipe awọn onibara wọn, ti wọn ba kọ lati tẹle ilana laarin gbedeke ọjọ ti wọn fi sita.

Awọn onibara miliọnu mẹtalelaadọrin ni awọn ileeṣẹ eto ikansira-ẹni yii dawọ ipe jade wọn duro, ti wọn ko si tun le ṣe ohun miran.

Igba mẹsan ọtọọtọ ni ijọba apapọ fi wọgile gbedeke ọjọ ti wọn pa a laṣẹ fun awọn ileeṣẹ ikansira-ẹni wọnyi, lati le gba awọn eeyan laaye lati kopa ninu eto naa, iyẹn ṣaaju ọjọ kẹrin, oṣu kẹrin, ọdun 2022

Ayẹyẹ ọdún Ọ̀ṣun Òṣogbo gbérasọ

Ayẹyẹ ọdún Ọ̀ṣun Òṣogbo gbérasọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ayẹyẹ ọdún Ọ̀ṣun Òsogbo tó gbérasọ lónìí ló bẹrẹ pẹ̀lú Ìwọpópó. Ìwọpópó jẹ́ ayẹyẹ tó máa ń ṣaájú Ìboríadé àti Ọ̀ṣun Òsogbo.

Iwopopo jẹ ọjọ ti wọn maa n fi wure fun gbogbo ilu ati fun gbogbo eeyan to maa wa sibi ayẹyẹ ọdun Ọṣun Osogbo.

Ọdun Ọṣun Osogbo jẹ ayẹyẹ to maa n waye ni ọdọọdun lati ni ilu Osogbo, olu ilu ipinlẹ Ọṣun.

Nibi ayẹyẹ ni wọn ti maa n bọ Ọṣun, to jẹ ọkan lara awọn oriṣa ilẹ Yoruba.

Ọṣun gẹgẹ bi itan ṣe fidi rẹ mulẹ jẹ ọkan lara awọn iyawo Sango.

Ninu ọrọ rẹ, Kabiyesi Ọba Jimoh Olanipekun, Ataoja ti ilu Osogbo sọ pe iwopopo jẹ olulana fun ayẹyẹ ọdun Ọṣun Osogbo.

Ọba Jimoh Olanipekun ṣalaye iwopopo kii ṣe ọdun ṣugbọn o jẹ atọna ibẹrẹ ọdun Ọṣun Osogbo to tun jẹ ọjọ pataki ti wọn maa n fi wure fun gbogbo eeyan n to bọ wa si bi ayẹyẹ ọdun naa.

Lasiko iwọpopo yii ni omidan ti yoo ru igba fun ọdun naa yoo ti gba igba lọ si odo Ọṣun.

Osunyemi Ifabode to jẹ Baba Orisa ti ilu Osogbo sọ pe pataki ọdun Ọṣun Osogbo kii ṣe fun awọn ọmọ bibi ilu Osogbo tabi ipinlẹ Ọṣun nìkan bikoṣe ọdun idupẹ fun gbogbo ọmọ kaaarọ-o-o-jire patapata.

Osundara Oyawale, iya Ọṣun ti ilu Osogbo ni ọdun naa eyi ti gbogbo eeyan maa n bere ohun rere ati wi pe, o jẹ ọdun ti Arugba yoo ru ibi danu, ti Kabiyesi yoo si wure fun gbogbo ilu ati fun gbogbo eeyan to peju pesẹ sibi ayẹyẹ naa.

Osundara tun fi kun ọrọ rẹ wi pe ọdun Ọsun Osogbo yatọ si ọdun aṣa sugbọn o jẹ ọdun adura ati iwure lati ẹnu Kabiyesi si gbogbo eeyan patapata.

Ọpọlọpọ eeyan lo peju pesẹ sibi eto Iwopopo lati ṣami ibẹrẹ ọdun Ọṣun Osogbo ti ọdun 2024.

Kaakiri agbaye ni wọn ti maa n ṣe irinajo wa lati kopa nibi ayẹyẹ ọdun Ọṣun Osogbo.

Ẹ̀yin alága ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ẹ tako ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ, ẹ má jẹ́ kí gómìnà ran yín lẹ́wọ̀n – APC

Ẹ̀yin alága ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ẹ tako ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ, ẹ má jẹ́ kí gómìnà ran yín lẹ́wọ̀n – APC

 

Lórí awuywuye ibi tó yẹ kí ìjọba àpapọ̀ máa san owó ìdàgbàsókè ìjọba ìbílẹ̀ sí tó ń jà rànìnrànìn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, agbẹjọro kan ti sọ pé ó lòdì sí òfin kí ìjọba Oyo tako ìdájọ́ ilé ẹjọ́.
Tó bá wu àwón alága ìbílẹ̀ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kí wọ́n dá ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ́ sílẹ̀, wọn ò lè yí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ padà.

Nígbà tó ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà, Monday Ubani (SAN) sọ pé kò sí ohun tí ìjọba Ọ̀yọ́ tàbí àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ rẹ̀ lè ṣe lẹ́yìn ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà.
Tó bá wu àwọn alága ìbílẹ̀ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kí wọ́n dá ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ́ sílẹ̀, wọn ò lè yí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ padà.

Ó ní láti nǹkan bíi ọgbọ̀n ọdún óle tí òun ti ṣiṣẹ́ agbẹjọro, òun kò tíì gbọ rí pé ìjọba ìpínlẹ̀ tàbí ìbílẹ̀ kankan gbénà wojú ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà láìíṣe pé wọ́n pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.

Ubani sọ pé “ó jẹ́ àpẹrẹ tó léwu gidi nígbà tí ìjọba ìbílẹ̀ bá sọ pé òun kò ní tẹ̀lé ìdájọ́ ilé ẹjọ́.

Wọ́n se ayẹyẹ ìpadàbọ̀ Bobrisky láti ọgbà ẹ̀wọ̀n Kiríkirì, nínú ọkọ̀ ojú omi l’Eko.

Wọ́n se ayẹyẹ ìpadàbọ̀ Bobrisky láti ọgbà ẹ̀wọ̀n Kiríkirì, nínú ọkọ̀ ojú omi l’Eko.

Gbọ́láhàn Quseem

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká ló péjú-pésẹ̀ níbi ayẹyẹ ìpadàbọ̀ Idris Okuneye tí ìnagijẹ rẹ̀ n jẹ́ Bobrisky ni’lu Èkó, lẹ́yìn tó gbòmìnira lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kiríkirì ní ìlú Èkó.

Ko pẹ ẹyin to gbominira ni fọn-ọnran kan bọ s’ori itakun ayelujara X, eyi to ṣafihan Bobrisky ati oṣere tiata kan, Eniola Ajao ati ẹnikan ninu ọkọ nibi ti Bobrisky ti n k’awọn ololufẹ rẹ.

Ni ‘rọlẹ ọjọ yi kan naa ni fọn-ọnran miran tun bọ s’ori ayelujara nibi ti Bobrisky at’awọn ọrẹ rẹ ti n ṣe ajọyọ ninu ọkọ oju omi.

Lara awọn gbajumọ to wa pẹlu Bobrisky ninu ọkọ oju omi ọhun ni oṣere tiata, Eniola ati Moyọ Lawal.

Àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ Oyo tako ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ, wọ́n ní kí owó àwọn wà lápò ìjọba ìpínlẹ̀

Àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ Oyo tako ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ, wọ́n ní kí owó àwọn wà lápò ìjọba ìpínlẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá
Báyìí làá ṣe nílé e wa, èèwọ̀ ibòmí-ìn ni, èyí ló bí n tí Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sọ pé láá ,òun kọ ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga kan tó pàṣẹ pé ìjọba ìpínlẹ̀ àti ìjọba ìbílẹ̀ kò gbọdọ̀ máa lo àpò ìṣúná kan náà mọ́.

Ṣaaju ni gomina Seyi Makinde ti kọkọ bu ẹnu atẹ lu idajọ ọhun, to si sọ pe kii ṣe ijọba apapọ ni yoo maa la le awọn ipinlẹ lọwọ lori bi wọn ṣe maa na owo wọn.

Eyi lo n waye lẹyin ti adajọ agba Naijiria, Lateef Fagbemi (SAN) pe ẹjọ lori ọrọ ọhun lọna ati fun awọn alaga ijọba ibilẹ lominira lati maa na owo wọn bo ba ṣe wu wọn.

Idajọ ile ẹjọ to ga julọ naa sọ pe ijọba ipinlẹ ko lagbara labẹ ofin lati maa ṣakoso owo ti ijọba ibilẹ yoo maa na fun atunṣe ilu.

O ni iwa naa ko ba ofin mu rara.

Wayi o, iroyin to n tẹ wa lọwọ ti sọ pe gbogbo awọn alaga ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Oyo ti fẹ yapa kuro ninu ALGON, lọna ati ṣatilẹyin fun Makinde.

Ninu atẹjade kan ti adari awọn alaga ijọba ibilẹ Oyo, Sikiru Sanda fi lede, o ni gbogbo wọn fọwọ si ohun ti Makinde ba sọ ati igbesẹ to ba gbe lori ọrọ naa.

Eredi igbesẹ awọn alaga ọhun, gẹgẹ bi wọn ṣe sọ ni pe Makinde jẹ adari rere to fi apẹrẹ rere silẹ, o si ti ṣe ọpọ aṣeyọri lati igba to ti gori alefa gomina.

Awọn alaga naa tun ti fẹnuko lati da ẹgbẹ tuntun mii silẹ, eyii ti kii ṣe ara ALGON, lọna ati tẹsiwaju iṣẹ wọn ni sinsin araalu.

Òfin fààyè gba ìwọ́de ita gbangba, àmọ́ a ò lè gbà kí dukia ìlú ó bàjẹ́-Ìjọba Èkó

Òfin fààyè gba ìwọ́de ita gbangba, àmọ́ a ò lè gbà kí dukia ìlú ó bàjẹ́-Ìjọba Èkó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀kan pàtàkì lára ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC níìpínlẹ̀ Èkó, tó tún jẹ́ Akọ̀wé fúnjọba ìpínlẹ̀ náà, Abilékọ Abimbọla Salu-Hundeyin, ní àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin orílèèdè yìí láti ṣèwọ́de ìta gbangba láti fẹ̀hónú hàn sóhun tí kò bá tẹ́ wọn lọ́rùn láàrin ìlú, ṣùgbọ́n kì í ṣe pé kí wọ́n fi dá wàhálà sílẹ̀.

O ni ijọba ipinlẹ Eko ko ni i faaye gba pe ki awọn oni-jagidi-jagan kan waa fọrọ iwọde ita gbangba naa kẹwọ lati doju ija kọ ijọba ipinlẹ gẹgẹ bo ṣe waye nigba EndSARSlọdun 2020, ti wọn da ijọba ipinlẹ Eko ni gbese nla lasiko naa.

O rọ awọn eeyan ipinlẹ Eko pe bi wọn ba tiẹ maa ṣewọde ọhun, ki wọn ṣe e pelu suuru, ki awọn ọmọ ganfe ma ja a gba mọ wọn lọwọ. O ni ki wọn ri i daju pe ọrọ iwọde ita gbangba naa ko di eyi to maa di yanpọnyanrin, ti gbogbo ẹ aa fi dojuru, ti ọrọ yoo si waa di bo o lọ o yago fun mi gẹgẹ bo ṣe ti waye lasiko tawọn ọdọ orileede yii n ṣewọde ita gbangba ti wọn pe ni EndSARS lọdun 2020.

Abilekọ Abimbọla sọrọ naa di mimọ ni Alausa, niluu Ikeja, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keje, ọdun yii, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ.

O ni, ‘‘Ipinlẹ Eko ko jẹ ẹnikẹni lowo ifẹyinti rara, gbogbo awọn to fara ṣiṣẹ sin ijọba ni wọn ti gba ẹtọ wọn patapata bayii. Bo o ba ṣiṣẹ pẹlu ijọba Eko, loju-ẹsẹ to o ba ti fẹyinti la ti maa ṣeto owo rẹ fun ọ lai si wahala kankan nibẹ. Gbogbo ọna nijọba n gba lati sọ aye dẹrun fawọn araalu rẹ. ‘’Ohun ti mo n sọ ni pe gbogbo eeyan pata ni wọn lẹtọọ labẹ ofin lati ṣewọde bi wọn ba fẹ, ṣugbọn eyi ti wọn maa ṣe lati fi da rogbodiyan silẹ laarin ilu la ta ko. Igbe aye idẹrun ta a n gbe lorileede yii lo daa, iṣẹ idagbasoke to n waye kaakiri ilẹ wa, paapaa ju lọ, nipinlẹ Eko, ko gbọdọ bajẹ. Ṣe lo yẹ ko maa tẹsiwaju si i, a ko nifẹẹ si ohunkohun to maa da wahala silẹ, paapaa ju lọ bi gbogbo nnkan ṣe n lọ deede lorileede wa bayii’’.