Home Blog Page 5

Awakò̩ BRT gba ìdájó̩ ikú

Awakò̩ BRT gba ìdájó̩ ikú

Yínká Àlàbí

Ile-e̩jo̩ giga to fi ikale̩ si ilu Eko ti dajo̩ iku fun awako̩ BRT (Bus Rapid Transit) ti Eko. Awako̩ naa ni Andrew Ominikoron, oun lo se̩mi Oluwabamise Ayanwo̩la legbodo ni o̩mo̩ o̩dun mejilelogun pere.
Onidajo̩ ile-e̩jo̩ to wa ni Tafawa Balewa square Annexe naa, Abileko̩ Serifat Sonaike f’e̩sun marun-un o̩to̩o̩to̩ kan de̩re̩ba naa. Awo̩n e̩sun naa ni ipaniyan, ifipa-banilo, pansaga, idite̩ ati iwa ibanilayeje̩ to s’eku pa Ayanwo̩la, to tun se iwa ibaje̩ miiran pe̩lu Dokita Anosike Victoria ati ifipa-banilo ti Maryland Ojiezelu.
Bi o tile̩ je̩ pe o̩daran naa ni oun ko je̩bi, Adajo̩ ni pe̩lu gbogbo iwadii, afi ki wo̩n so o̩daran naa ko̩ titi ti e̩mi yoo fi bo̩ lara re̩.

Alao Malaika sín Portable ní gbẹ́rẹ́ ìpàkọ́ lórí jàgídíjàgan

Malaika

Bola Afolabi

Akorin fuji to fi ilu Eko se ibujokoo, Sule Alao Malaika, ti sin akorin onijangbon, Portable, ni gbere ipako lori bi a se n fi iwa pele se aye.

Malaika, eni to korin ‘O boju mi je Olorun’ gba Portable ni imoran nigba ti olomokunrin to korin ‘Zazzoo’ ba a lalejo.

Portable lo ki Malaika leyin ti Olorun yo o, ti ko di ero ewon.

Adajo kan ni Ipinle Ogun ti so pe Portable jebi esun ole jija ati ikolu omolakeji lona ifiyaje.

Sugbon won ni dipo ko lo si ewon, o le san owo itanran to je ogbon naira.

Eyi ni Portable sare san, ti inu re wa n dun sese.

Malaika ba a dupe, sugbon o kilo fun un pe ko ye se jagidijagan.

O ni bi alariya kan ba wa wa to n se laulau, awon aniyan gidi to le ba a dowo po maa sa jinna si i.

Ni pataki, o bun Portable ni ebun owo dola.

Ta wá ló fẹ́ parí ìjà láàrin Akewugbagold àti Alhaja Kaula báyìí?

Alhaja Kaola

 

Hmm. Ibeere nla.

Awuyewuye to wa laarin awon agba adari esin Musulumi meji kan, iyen Sheikh Taofeek Akeugbagold ati Alhaja Kafila Kaola, ti di nanto bayii.

Bi ekinni se n fi esun kan ekeji, ni toun naa n juko oro si i.

Bi o tile je pe agbo opo awon Musulumi lo ti di agbo alawuyewuye latari bi awon aafaa se n ba ara won fa surutu lori ero ayelujara, ti Akewugbagold ati Kaola n ko opo eniyan lominu gan-an.

Akewugbagols

Idi ni pe, ore timotimo ni won tele.

Bee, Ibadan nile Oluyole naa ni won fidi si ju.

Ohun to tun wa n ko awon janmoo lominu ni pe won ko mo pato ohun to dija sile.

Ninu arokan tii fa ekun asun-un-dake awon mejeeji, oro asorofaa Aafaa Sshittu jeyo.

Ekinni ni bi oun se pari ija laarin oun ati Shittu ni ekeji ko fe.

Sugbon opo ohun ti okookan won maa n sipaya lori Facebook fihan pe edun okan awon mejeeji rinle gidi.

Boya ohun to ye ki a maa wa ko ni kin lo dija sile, bi yoo se pari lo se koko.

Boya ki awon agbaagba ninu esin lo anfaani inu aawe Ramadan ti o n lo lowo yii, ki won fi petu si won ninu, ki irepo o le joba niu esin alaafia ti esin Musulumi je.

Kò sẹ́ni tó kọjá ẹ̀wọ̀n – Portable ló sọ bẹ́ẹ̀

Portable

Lasun Alagbe

Akorin igbalode to maa n se jagidijagan, Habeeb Okikiola, ti opo eniyan mo si Portable, ti kilo fun awon eniyan pe ko si eni to koja ewon.

Iwaasu yii ni Portable fi bonu leyin ti ori yo o lewon, ti adajo fun laaye pe ko san ogbon naira gege bi owo itanran.

Adajo majisireeti kan ni ilu Ifo ni Ipinle Ogun lo taari Portable si ewon, lori esun ole jija ati ifiyaje eni-eleni lai nidii.

Odun 2022 ni won ni o ti da oran naa.

Oun ti le gbagbe, sugbon ofin kii gbagbe.

Koda ti won ko ba so pe o le san owo itanran ni, oun naa ki ba ti di elewon gege bii awon alariya bii Bobrisky ati Baba Ijesha.

Nigba to wa n soro lori isele naa, Portable dupe lowo Oluwa pe oro oun ko ja si garigada.

O wa so pe o ti ye oun kedere pe ko si eni to koja ewon.

Ọ̀TỌ̀ LOWÓ, Ọ̀TỌ̀ NÌWÀ:  Tọmọdé-tàgbà ń yòmbò Otunba Michael Adenuga nó ṣe pé ẹni ọ́dún méjìléláàdọ́rin: 72

Adenuga

Mudasir Alabi

 

  • Àwọn nnkan pàtàkì mẹ́wàá tí àgbà ìsòwò náà ti ṣe fún ọmọnìyàn

Bi a ba n soro awon to lowo ju ni Naijiria ati Aafirika, a ko ni ka meta ti a fi maa daruko Otunba Mike Adenuga, to je oludasile ile ise Globacom ati awon ile ise okowo miran. Sugbon tori owo ti Adenuga ni nikan ko ni awon eniyan se maa n ranti re. Tori ohun to n fi owo ati ola re se lawujo ni. Bee, ka ma paro, ka ma seke, Adenuga le ma maa pariwo ni, o n na owo re si ibi to to ati ibi to ye.

Idi niyii to fi je pe lasiko ojo ibi re, bo se je pe o je eni kan ti ko feran ariwo bii eye ega, awon eniyan kan ko le ma ko o jade bi omo ojo mejo. Won ko le ma logun awon ipa nla to n ko lawujo fun araye. Bi won se n ki i ni won yoo maa ki i, ti elomiran ti Adenuga ti fi owo ola ba lara lai pariwo yoo maa royin, ti a fee to ile la.

Baba olowo naa to fi Banana Island ni ilu Eko se ibugbe, nibi to ko awon ile ti won te rere bii odo Osa si, di eni odun mejilelaadorin (72 years) lojo Isegun, April 29, 2025. To ba je olowo miran ni , ikede ibanisajoyo a gba gbogbo iwe iroyin, redio ati telifisan pa ni. Se owo ti yoo fi se bee ni ko ni ni? Sugbon Adenuga kii fe ki awon eniyan maa se eyi. To ba je pe o fe e ni, gongo iba so. Opo eniyan to ti soore fun, ti won ti dide lati ara re ni won ba maa figa gbaga lori ipolowo ojo ibi naa.

Sibesibe, lati nnkan bii ose meji seyin ni oniruuru apileko ti n jade lori igbesi aye gidi ti Adenuga n gbe.

Odun gidi ni odun to koja yii je ninu igbesi aye Adenuga. Lona kinni, Olorun ba a doju ti awon ota alaheso, awon ti won gbe ofege iroyin jade pe lapalapa ti ku. Aseyinwa, aseyinbo, imoran awon ota ko se lori Adenuga. Sakamaje lasan ni won ta bi okoto. Ero won, pabo lo ja si. Eyi wa tumo si pe oro Adenuga tope o ju ope lo.

Adenuga

Lona miran ewe, oro (wealth) Adenuga gberu sii laarin odun kan seyin. Gege bi awon atopinpin olowo Forbes ti gbe e jade, owo bii eedegberin milionu dolla ($700m) lo kun owo Adenuga lasiko naa. Ti a ba se eyi si naira, ile a kun falafala ni. K ma deena penu, owo to le ni tirilionu kan naira lo kun owo Baba Ijebu ti kii se ahun yii.

Bi owo re se n bureke sii, ni awon ile ise re naa n gbooro sii. Itumo eyi ni pe ilosiwaju n ba oawon ogooro eniyan to n sise pelu re. Owo tubo n wo apo ijoba lati owo re nipa orisiirisii owo orinto n san. Bakan naa, lai figbe ta, Adenuga n na owo lori orisiirisii nnkan to n ran ilu, elegbejegbe ati awon eniyan kookan lowo.

Abalajo, nigba ti Aare Tinubu n ki olowo tabua ti won n pe ni The Bull yii ko oriire ti ojo ibi, Aare se alaye pe o je ogunna gbongbo laarin awon ti won n mu ilosiwaju ba Naijiria. O ni o je eni ti ko see fowo ro seyin nidii ise okowo, ti ihuwasi re kii sii se ti eni to n se ipalara won awujo.

Bi IROYIN OWURO se n ki Otunba Dokita Mike Adenuga ku oriire, o je ohun amuyangan fun wa lati yannana awon ona bii mewaa ti Adenuga se n ran omoniyan lowo:

– Dokita Mike Adenuga je okan lara eni to n gba aimoye eniyan sise lawon ile ise re bii Globacom, ConOil ati bee bee lo. Aimoye osise re ni awon naa ti laami laaka.

– Dokita Mike Adenuga n gbe oniruuru ise fun awon kongila. Nipa bayii, awon kan ti la, won ti lu lati ara Adenuga.

– Dokita Mike Adenuga maa n diidi bun awon eniyan lowo nla-nla lati fi ran ebi ati ise won lowo.

– Dokita Mike Adenuga n gbe owo sile fun awon elegbejegbe ati ajo lati se awon eto pataki pataki. Lara eyi ni awon ti ile ise re bii Globacom maa n se nipa ohun ti won oloyinbo n pe ni Corporate Social Responsibility.

– Dokita Mike Adenuga n seun pataki fun oro aje Naijiria ati awon ipinnle nipa owo ribiribi ti oun ati awon ile ise re n sa lowo ori.

– Dokita Mike Adenuga n gbe asa ati ise Naijira soke latari bi Globacom se maa n fi owo gbe nnkan abinibi bii odun Ojude Oba ati Ofala ga.

– Dokita Michael Adenuga je opo pataki kan to je ki idagbasoke ise fiimu ati orin rinle ni Naijiria nipa iranwo nla to n se fun awon osere nipase eto Globacom Ambassadors.

– Dokita Mike Adenuga n yi kadara awon eniyan pada si rere latara eto tete orire Festival of Joy ti Globacom maa n se, nibi ti awon eniyan ti n je ile, je moto ati awon ohun meremere miran.

– Dokita Mike Adenuga n seto idagbasoke ere idaraya, gege bi Globacom se maa n se agbateru awon idije kan.

Adenuga

– Lakootan, Dokita Mike Adenuga twa lara awon akoni to je ki ibowofun wa fun awa eniyan dudu. Oun lo je ki araye mo pe omo Naijeria naa le da ile ise telifoonu igbalode sile, ti yoo si seto naa ti yoo ye kooro. Adenuga lo fi ye wa pe opolo olokowo dudu ko kere si ti oyinbo egbe re.

Nje aseyisamodun o, Otunba Mike Adenuga. Ki Olorun maa so agbara di otun.

N kò pàdánù nǹkan kan bí mo s̩e fé̩ àgbàlagbà – Shade Oko̩ya

Shade ati olowo ori re, Akanni Okoya

Iyaadin Shade Okoya, to je gbajugbaja onise okowo tati iyawo olowo tabua, Alhaji Rsaq Akanni Okoya, ti sọ pe oun ko padanu nnkan kan lori bi oun se fe agbalagba okunrin.

Shade, to je eni ọdun mejidinlaadota bayii ṣe igbeyawo pẹlu  Okoya ni 1999 nigba ti olowo tabua naa je eni ọdun marundinlaadorin (65, ti obinrin naa si je eni ọdun mokanlelogun nigba naa.

Amo sa, nigba to n sọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba, Shade fowo gbaya pe oun ko padanu ohunkohun rara nitori pe oun ko fẹ ọdọmọkunrin.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìrírí rẹ̀ nínú ìgbéyàwó naa, ó sọ pé inú òun dùn gan-an ni.

Ó ní, “Ọkọ mi jẹ́ ọ̀làwọ́ pẹ̀lú mi. O sì ń gbèjà mi níbikíbi. Ọlọ́run sọ pé ibi tí màá wà nìyí. A pàdé ara wa; ó sì nífẹ̀ẹ́ mi. Kò sì fi àkókò ṣòfò rárá.

“Inu mi dun ninu igbeyawo mi pẹlu rẹ. O dagba ju mi lọ, ṣugbọn mi o ro pe mo padanu ohunkohun nitori pe mi o fẹ ọdọmọkunrin kan.”

Afihan fiimu: Muyiwa Ademola tọrọ oforiji lọwọ awọn ẹlẹgbẹ ti ko pe 

Muyiwa Ademola

Mary Seunfunmi

Osere ati olusefiimu Muyiwa Ademola ti toro aforiji ni gbangba lọwọ awon akegbe re kan lori bi ko se le pe won sibi afihan fiimu re to n bo, “ORI Rebirth” to waye laipe yi, ni ojo ketadinlogbon osu kerin odun yii.

Ó sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ jáde; o ní òun nìkan lo ni ẹ̀bi náà, to sì ń tọrọ aforijjì.

Ademola tenu mo o pe awon akegbe oun, agba ati kekere, se pataki ni irin ajo oun; bee oun si ka won si pupo.

O so lori ero alatagba: “E kaarọ, eyin ebi mi. Mo kan fẹ lati lo akoko yii lati tọrọ aforiji lọwọ  awọn to yẹ ki n pe ṣugbọn ti mi o pe, paapaa awọn ẹlẹgbẹ mi, agba ati kekere. Ẹbi naa wa lọwọ mi. E jọwọ e dariji mi. Gbogbo nyin ṣe pataki fun mi ati irin-ajo mi. Mo moyi yin ni bayi ati nigba gbogbo.

“E ma binu simi. Afojudi ko o. E MA BINU?

“E ṣeun fun ifẹ ti e fi han yi. Mo moyi re pupo. Mo nife gbogbo yin. Afihan ORI rebirth loni! Yoo jade ni sinima ni ọjọ kinni osu karun.”

Aforiji oṣere naa wa lẹyin ti o dabi ẹni pe o ise po lorun re pẹlu awọn igbaradi fun afihan naa.

“ORI Rebirth” yoo wa ni awọn sinima lati ọjọ kinni osu karun-un.

Akoja onifiimu naa ni ni sinima.

Awon ololufe ati awon elegbe re si ti fesi pelu ife ti o po, eyi ti Ademola moriri.

 

Olori Omo Oba Ijebu ni Wasiu je, kii se olori onifuji – Kollington Ayinla

Niwon igba ti mo ba wa laye, Wasiu Ayinde ko le je olori onifuji – Kollignton Ayinla

Bola Afolabi

Gbajugbaja olorin Fuji, Alhaji Kollington, ti so pe oye Olori Omo Oba ti gbajugbaja onifuji ‘Ade Ori Okin;, iyen Wasiu Ayinde, je ori awon eniyan re ni Ijebu lo je e le.

Kollington ni kii se olori oun tabi olori onifuji.

O ni Wasiu ko le gba ipo naa lowo oun niwon igba ti oun ba si wa laye.

O so eyi nigba to n fesi  si ẹsun ti Wasiu fi kan an pe ko kaaramasiki lasiko ti iya oun ku.

Ninu iforowanilenuwo kan, K1 sọ bi o ṣe atilẹyin fun Kollington nigba iku iya tirẹ, ti o fi ẹsun kan an pe ko se bee fun oun.

Sugbon nigba to n soro ninu iforowanilenuwo kan laipe yi lori  Agbaletu, Kollington tako esun naa.

O ni ohun gbiyanju lati kan si Kwam1 lori foonu, ṣugbọn ko gbe ipe rẹ tabi ki o pe pada.

Kollington tun fi esun igberaga kan Wasiu.

O ni oye Olori Omo Oba to je n gun un.

Wasiu Ayinde ati iyawo re, Emmanuela

O ni: “Nigba ti iya Wasiu Ayinde ku, mo pe e ni ooto. Ko gbe e, bee ni ko da ipe naa pada. Koda lojo odun tuntun ni mo pe, ko si gbe e. Mo ni, kini nnkan to n sele si omokunrin yii? Nitori naa, mo je ki o ri I. Ko le so fun mi pe o n sise lowo.

“Kí ni ọwọ́ rẹ̀ dí fun? Bo ba je pe nitori o de ade ‘Olori omoba’, ipo naa wa fun idile re ni Ijebu, ki i se ti emi. Ṣé ó fẹ́ di Ọlọ́run ni? Emi ni olori gbogbo awon olorin fuji. Ko le jẹ olori rara nigba ti mo wa laaye.”

Ìròyìn òwúrò̩ tuntun

Ìròyìn òwúrò̩ tuntun

STANBIC IBTC ń dá bírà

STANBIC IBTC gbé ètò ìrò̩rùn kalè̩ fún àwo̩n oníbárà.
E̩ kàá dáadáa kí e̩ sì máa bá ìlànà orí kòm̀pútà náà lo̩.

https://survey.stanbicibtc.com/survey/runtimeApp.app?invitationId=0Kiaa000002vPtN&surveyName=stanbic_ibtc&UUID=e1160250-fa03-4e0c-8c1f-c299bb003762