Home Blog Page 3

Ìyàwó parọ́ mọ́ ọkọ pé ó bà ọmọ àwọn obínrin lò pọ̀

Ìyàwó parọ́ mọ́ ọkọ pé ó bà ọmọ àwọn obínrin lò pọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní olóòtọ́ kìí kú sí ipò ìkà.
Òrọ̀ ti bẹ́yìn yọ fún ìyàwó ilé kan ní ìpínlẹ̀ Enugu, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Chisom, tó fi ẹ̀sùn kan ọkọ rẹ̀ pé ó bá àwọn ọmọ àwọn obìnrin méjì lò pọ̀, tí ẹ̀sùn ọ̀hún sì padà jẹ́ irọ́ lásán.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Enugu, SP Daniel Ndukwe, ṣalaye pe Chisom fi ẹsun ifipaba awọn ọmọ ti ọjọ ori wọn jẹ marun-un ati mẹta lo pọ, kan baba wọn, Ozioma Okonkwo.

Eyi lo fa a ti awọn ọlọpaa fi mu baba naa si ahamọ, bo tilẹ jẹ pe o n sunkun kikoro ninu fidio ti wọn ti mu un pẹlu ṣẹkẹsẹkẹ lọwọ, o ni oun ko ṣe ohun ti iyawo oun sọ fun ọlọpaa.

Awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii lẹyin ti wọn ti gbe ọkọ naa ju si ahamọ, iwadii naa lo si jẹ ki wọn mọ pe ko si ẹri kan to fẹsẹ mulẹ pe ẹni to wa lahamọ naa ṣẹ loootọ.
Lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹwaa ọdun 2025 ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Enugu, gba ifisun lati ọdọ Chisom, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29).

O ṣalaye fun wọn pe ọkọ toun bi awọn ọmọ mẹta fun (ọkunrin kan, obinrin meji) n ba awọn ọmọbinrin naa ti ọjọ ori wọn ko ju marun-un ati mẹta lo, ṣe iṣekuṣe.

Obinrin naa fi kun un pe ọkọ oun ni ko jẹ koun tu aṣiri naa tipẹ, nitori o leri lati pa oun boun ba sọ fun ẹnikẹni.

Eyi ni awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii lorii rẹ, lẹyin ti wọn ti gbe ọkọ ju si ahamọ.
Iwadii pada fidi ẹ mulẹ, pe akoba lasan ni ẹsun ti Chisom n ka si ọkọ rẹ lẹsẹ.

Alukoro ọlọpaa Enugu sọ pe iwadii awọn fi han, pe 2024 si 2025 ti Chisom fẹsun iṣekuṣe naa kan ọkọ, lo ti funra rẹ ko awọn ọmọdebinrin ọhun lọ si ipinlẹ Imo, lati Enugu.

Awọn ọmọ ko tilẹ si lọdọ baba wọn lasiko ti iya n fẹsun naa kan baba.

Bakan naa, akọbi wọn to jẹ ọkunrin, ọmọ ọdun meje, ṣalaye fun awọn ọlọpaa pe iya awọn lo kọ oun ati awọn aburo oun obinrin lati purọ mọ baba awọn.

Lẹyin ti iwadii ọlọpaa ti fi han pe irọ ni ẹsun ti Chisom fi kan ọkọ rẹ, wọn fi ọwọ ofin gbe oun naa.

Wọn gbe e lọ sile ẹjọ majisreeti ipinlẹ Enugu, lori ẹsun meji to rọ mọ ibanilorukọjẹ ati sisọ ohun ti ko ri bẹẹ.

Laaarin asiko naa, Chisom gbiyanju lati fi opin si ẹjọ to n lọ lọwọ, ati iwadii ọlọpaa, ṣugbọn wọn ko gba fun un.

Kootu fi aaye beeli silẹ fun un, wọn si sun igbẹjọ siwaju.

Bi ẹnikẹni ba jẹbi ẹsun ibanilorukọjẹ ni Naijiria, ijiya rẹ ni ẹwọn ọdun kan tabi meji pẹlu owo itanran.

Ẹnikẹni ba si to eke lorilẹede yii, ẹwọn ọdun mẹrinla gbako ni ijiya rẹ.

Ìdí tí Sheikh Gumi ṣe ń pè fún bíbá àwọn agbébọn ṣe ìpàdé

Ìdí tí Sheikh Gumi ṣe ń pè fún bíbá àwọn agbébọn ṣe ìpàdé

Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọnà àgbà sọ pé ẹbọ tó nípọn ló tọ́ kí ẹdá máa rú, látàrí àwọn ọ̀rọ̀ tó máa ń jáde láti ẹnu wa.

Lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí, ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjìríà ló ń sọ pé ìjọba àpapọ̀ fi ọwọ́ òfin mú gbajúmọ̀ onímọ̀ ẹ̀sìn Islam nnì, Sheikh Ahmad Mahmud Abubakar Gumi, lórí bí wọ́n ṣe ní ó mọ̀ nípa ìkọlù àwọn agbébọn tó ń wáyé lémọlémọ lórílẹ̀èdè Nàìjìríà.

Ohun to fa a ti wọn fi n pe fun fifi ọwọ ofin mu Gumi ko ṣẹyin bi Alfa naa ṣe n beere fun biba awọn agbebọn ṣepade alaafia.

Ṣugbọn Sheikh Gumi funra rẹ ti sọ pe ẹru ko ba oun, o ni bijọba tilẹ mu oun fun biba awọn agbesunmọmi ṣepade, to ba ti jẹ ki alaafia le jọba loun n wa, ko si wahala kankan.

Tẹ o ba gbagbe, ọpọ igba ni Gumi ti pe fun pe kijọba ba awọn agbebọn naa ṣepade.

O ni eyi nikan ni ọna abayọ si iṣoro eto aabo, yatọ si ki ijọba maa fi ipa koju wọn.
Nigba to n ṣalaye bo ṣe nira to lati ri awọn agbebọn naa ba ṣepade, eyi ti Sheikh Gumi ti ṣe ri, o ni ewu kekere kọ ni awọn maa n la kọja bawọn ba wọgbo lọ lati ri wọn.

Loju opo Facebook rẹ, Gumi sọ pe awọn to ni ki ijọba mu oun ko mọ nnkan kan bii awọn agbebọn to n daamu ilu naa ni

“Bi wọn ba mọ ewu ti a maa n dojukọ lati ri awọn agbebọn yii ni, wọn a maa yìn wa ni, dipo bi wọn ṣe n tẹmbẹlu wa.”
Bẹẹ ni Alfa Gumi wi.

Lori idi ti ọrọ awọn agbebọn ṣe maa n mumu laya rẹ lọpọ igba, Sheikh Gumi ṣalaye pe:

“Awa eeyan Ariwa ni ọrọ yii kan ju, awa ni wọn si n ṣe ijamba fun ju. Wọn ko jẹ ka lọ soko, wọn si tun n le awọn miran kuro niluu wọn.

“Fun idi eyi, a ko le kawọ gbera ka maa wo, bi a ba n woran, a ko ṣe ohun to tọ fun ilu wa ati ijọba. ”

” Nitori ẹ la ṣe maa n wọgbo lọ pẹlu awọn oṣiṣẹ ijọba, ṣugbọn awọn eeyan ko mọ pe a n ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba.

“Nitori ẹ lo ṣe n jọ bii pe a n ba awọn agbebọn dowo pọ loju wọn. A n gbiyanju lati fi aṣiṣe wọn han wọn ni, ka si kọ wọn lẹkọọ, nigba ti a ti mọ pe wọn ko ni ẹkọ ẹsin.”

Bẹẹ ni Sheikh Gumi ṣalaye.

Bi iṣoro ai si aabo yii yoo ba wa sopin ni Naijiria, Gumi sọ ọna abayọ si oju opo Facebook rẹ:

“Ọna kan ṣoṣo lati fopin si igbesunmọmi ni lati kọ awọn agbebọn naa lẹkọọ, ka fi igbagbọ kọ wọn pẹlu ireti ohun rere.”

Akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ 227 ni wọ́n jígbé ní ilé ẹ̀kọ́ St Mary – Àjọ CAN

Akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ 227 ni wọ́n jígbé ní ilé ẹ̀kọ́ St Mary – Àjọ CAN

Fẹ́mi Akínṣọlá

Alága ẹgbẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristẹni, Christian Association of Nigeria, CAN tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Niger, Ẹni ọ̀wọ̀ Bulus Dauwa Yohanna ti sọ pé èèyàn 227, tó fi mọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ láwọn ajínigbé tó ṣe ìkọlù sí ilé ẹ̀kọ́ St Mary Catholic Schools, Papiri ní ìjọba ìbílẹ̀ Agwara ní ìpínlẹ̀ náà ni wọ́n jí gbé lọ.

Ẹni ọ̀wọ̀ Yohanna nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ rẹ̀ Daniel Atori fi léde sọ pé òun ṣe àbẹ̀wò sí ilé ẹ̀kọ́ náà níbi tí òun ti ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn òbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.

Ó ní òun ṣe àrídájú rẹ̀ fáwọn òbí àwọn ọmọ náà pé àwọn ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti ṣe àwárí àwọn ọmọ náà àti láti láti gbà wọ́n sílẹ̀ láyọ̀ àti àlááfíà.

“Nínú àkọ́sílẹ̀ tí a rí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 215 àtàwọn olùkọ́ 12 láwọn ajínigbé náà jí gbé lọ.”

Ó fi kun pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan móríbọ́ lásìkò ìkọlù ọ̀hún, tí àwọn òbí sì ti ń lọ mú àwọn ọmọ wọn nítorí wọ́n máa ti ilé ẹ̀kọ́ náà pa fún ìgbà kan ná.

Bákan náà ló rọ àwọn èèyàn láti ṣe sùúrù, kí wọ́n sì máa gbàdúrà fún ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láìpẹ́ ọjọ́.

Ìjọba àpapọ̀, àwọn ìpínlẹ̀ gbé ilé ẹ̀kọ́ tìpa nítorí ìkọlù àwọn ajínigbé

Ìjọba àpapọ̀, àwọn ìpínlẹ̀ gbé ilé ẹ̀kọ́ tìpa nítorí ìkọlù àwọn ajínigbé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní n tí a kò bá fẹ́ kò bájẹ́, ó ní bí a ti i ṣe é.
Ìjọba àpapọ̀ àtàwọn ìpínlẹ̀ kan lẹ́kùn àríwá Nàìjíríà ti pàṣẹ gbígbé àwọn ilé ẹ̀kọ́ kan tìpa látàrí ìpèníjà ààbò àti báwọn ajínigbé ṣe ń jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé.

Bí ìjọba àpapọ̀ ṣe gbé àwọn ilé ẹ̀kọ́ mọ́kànlélógójì tìpa náà ni àwọn gómìnà ní ìpínlẹ̀ Kwara, Plateau, Niger, Benue àti Katsina náà ti dá ètò ẹ̀kọ́ dúró láwọn ilé ẹ̀kọ́ kan fún ìgbà kan ná.

Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kọkànlá, ọdún 2025 ni inú fu àyà fu tún bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn agbébọn tún ṣe ìkọlù sí ilé ẹ̀kọ́ St Mary Catholic School ní ìlú Papiri, ìjọba ìbílẹ̀ Agwara, ìpínlẹ̀ Niger.

Níbi ìkọlù náà ni àwọn ajínigbé ọ̀hún ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 215 àtàwọn olùkọ́ méjìlá gbé lọ.
Ìkọlù àwọn agbébọn yìí ló ń wáyé lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin tí wọ́n jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n gbé lọ ní ilé ẹ̀kọ́ Government Girls Comprehensive Secondary Secondary School, Maga ní ìpínlẹ̀ Kebbi.

Bákan náà ló ń wáyé lẹ́yìn ọjọ́ kejì táwọn agbébọn ṣèkọlù sí ilé ìjọsìn CAC ní ìlún Eruku, níbi tí wọ́n ti jí ọ̀pọ̀ olùjọsìn gbé lọ táwọn agbébọn náà sì ti ń bèèrè fún ogún mílíọ̀nù náírà gẹ́gẹ́ bí owó ìtúsílẹ̀ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan iye èèyàn mẹ́tàdínlógójì tí wọ́n jí gbé.

Àwọn ìkọlù yìí ló mú kí ìjọba àpapọ̀ àtàwọn ìjọba ìbílẹ̀ láti wá ọ̀nà láti mú àdínkù bá àwọn ìjínigbé yìí.

Ìjọba àpapọ̀ ti pàṣẹ pé kí wọ́n ti àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n máa ń pè ní unity school tìpa láti dènà ìkọlù àwọn agbébọn yìí.

Àtẹ̀jáde kan tí adarí ètò ẹ̀kọ́ girama ní iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ẹ̀kọ́, Binta Abubakar ni wọ́n ti kéde ìgbésẹ̀ náà.

Lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó máa wà ní títìpa ni FGGC Minjibir; FGA Suleja; FTC Ganduje; FGGC Zaria; FTC Kafanchan; FGGC Bakori; FTC Dayi; FGC Daura; FGGC Tambuwal; FSC Sokoto; FTC Wurno; FGC Gusau; FGC Anka; FGGC Gwandu; FGC Birnin Yauri; FTC Zuru; FGGC Kazaure; FGC Kiyawa; FTC Hadejia; FGGC Bida; FGC New Bussa; FTC Kuta Shiroro.

Àwọn míì ni FGC Ilorin; FGGC Omu Aran; FTC Gwanara; FGC Ugwolawo; FGGC Kabba; FTC Ogugu; FGGC Bwari; FGC Rubochi; FGGC Abaji; FGGC Potiskum; FGC Buni Yadi; FTC Gashau; FTC Michika; FGC Ganye; FGC Azare; FTC Misau; FGGC Bajoga; FGC Biliri; àti FTC Zambuk.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Niger náà ti kéde gbígbé àwọn ilé ẹ̀kọ́ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń sun ibẹ̀ ní ẹkùn Niger North tìpa fún ìgbà kan ná.

Ìkéde yìí ni wọ́n gbé jáde nínú àtẹ̀jáde tí akọ̀wé ìjọba, Alhaji Abubakar Usman fi síta lọ́jọ́ Ẹtì.

Bákan náà ni ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara tí kéde títi àwọn ilé ẹ̀kọ́ pa ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rin ìyẹn ní Isin, Irepodun, Ifelodun àti Ekiti níbi tí ìkọlù àwọn agbébọn ti ń wáyé lemọ́lemọ́.

Ìpinnu yìí ló ń wáyé nínú ìkéde tí alága ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ìpínlẹ̀ Kwara, Yusuf Agboola fi síta.

Bẹ́ẹ̀ náà ni ìjọba ìpínlẹ̀ Plateau kéde títi àwọn ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ káàkiri gbogbo ìpínlẹ̀ náà nítorí ètò ààbò tó mẹ́hẹ.

Agbẹnusọ ètò ẹ̀kọ́ káríayé ní ìpínlẹ̀ náà, Richard Jonah sọ pé ìjọba gbé ìgbésẹ̀ náà láti wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí nítorí ìkọlù tó ń wáyé láwọn ìpínlẹ̀ míì.

Ó ní àwọn gbé ìgbésẹ̀ náà láti dènà irúfẹ́ ìkọlù bẹ́ẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Plateau.

Ní ìpínlẹ̀ Katsina, ìjọba ti pàṣẹ pé kí wọ́n gbé gbogbo àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó jẹ́ ti ìjọba tìpa títí di ìgbà kan ná.

Kọmíṣánnà ètò ẹ̀kọ́ ní Katsina, Yusuf Jibia sọ fún àwọn akọ̀ròyìn lọ́jọ́ Ẹtì pé ìgbésẹ̀ náà ń wáyé láti dá ààbò bo àwọn akẹ́kọ̀ọ́.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ń ṣe ìdánwò lọ́wọ́, dídá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá ṣe pàtàkì, tí àwọn sì mú ní òkúkúdùn.

Jibia fi kun pé àwọn gbé ìgbésẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ ná láti ṣe àgbéyẹ̀wò ètò ààbò ìpínlẹ̀ náà.

Ẹ̀wẹ̀, agbẹnusọ ìjọba ìpínlẹ̀ Kebbi, Ahmed Idris sọ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Kebbi ti pọn kún ètò ààbò àmọ́ wọn kò ní ti àwọn ilé ẹ̀kọ́ pa.

Idris ní bíi ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sí mẹ́rin ló kù fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti parí sáà àkọ́kọ́ tí wọ́n ń ba lọ lọ́wọ́ àti pé ètò ààbò tí wọ́n ti là kalẹ̀ yóò jẹ́ kí ìtẹ̀síwájú bá ètò ẹ̀kọ́.

Àdánù ńlá ni ikú Olúṣẹ́gun Awólọ́wọ̀ jé̩ fún Naijiria lápapò̩ – Akpabio

Àdánu ńla ni ikú Olúṣẹ́gun Awólọ́wọ̀ jé̩ fún Naijiria lapapo̩ – Akpabio

Yínká Àlàbí

Ààrẹ Ilé Igbimo̩ Asòfin, Godswill Akpabio, ti sọ pé ikú olóògbé Olúṣẹ́gun Awólọ́wọ̀ Jnr., ọmọ bàbá ńlá idílé Awólọ́wọ̀, jẹ́ nnkan buruku fún ile̩ Yorùbá àti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ní ìkéde tí aṣojú rẹ̀ fún ìrọ̀yìn, Jackson Udom, fi síta, Akpabio sọ pé ìròyìn ikú ọ̀rẹ́ àti arákùnrin rẹ̀ yìí wá sí i lojijì ó sì dùn gan-an.
Ó sọ pé a kò lè béèrè lọ́wọ́ Olúwa nípa ìpinnu rẹ̀, torí Ọlọ́run ló mọ ìgbà tá a bí ènìyàn àti ìgbà tí yóò lọ.
Ó se ibanike̩dun pẹ̀lú gbogbo idílé Awólọ́wọ̀ ní Ikènné, Gómìnà Dàpọ̀ Abíọ́dún àti ará Ogun State lórí àìníye yìí. Ó tún fi e̩dun ọkàn rẹ̀ hàn fún ìyàwó àti ọmọ tí Olúṣẹ́gun fi sílẹ̀.
Akpabio ṣàfikún pé Olúṣẹ́gun jẹ́ agbẹjọ́rò ọlọ́gbọ́n, ọkọ àti baba onírẹ̀lẹ̀, tí ìrántí iṣẹ́ rere rẹ̀ yóò tẹ̀síwájú.
Láti orúkọ àwọn ènìyàn Akwa Ibom North West àti Ilé Asòfin Kẹwàá, ó gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún un ní ìsinmi aláfíà, kí ó sì fún idílé àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní agbára láti ní sùúrù.
Ó parí o̩ro̩ re̩ pé kí Ọlọ́run fun idílé Awólọ́wọ̀ ní agbára ati okun láti gbà adanun nla ti ko se fowo ra yii. Ki Eledua si jo̩wo̩ ba wa te̩ e̩ si afe̩fe̩ rere.

Àwo̩n báńdíìtì tún jí aké̩kò̩ó̩ bíi àádó̩ta ní ìpínlè̩ Niger

Àwo̩n báńdíìtì tún jí aké̩kò̩ó̩ bíi àádó̩ta ní ìpínlè̩ Niger

Yínká Àlàbí

Awo̩n janduku agbebo̩nrin tun gbinaya wo ile-iwe St. Mary’s ní Papiri, Agwara, ní ipinle̩ Níger, ní owurọ ọjọ́ Ẹtì, o̩jo̩ ko̩kanlelogun, Oṣù kọkànlá o̩dun 2025.
SSG ìpínlẹ̀ naa, Alhaji Abubakar Usman, àti o̩ga ọlọ́pàá tún jẹ́rìí si ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọn sọ pé a kò tíì mọ iye àwọn ọmọ tí wọ́n ji ko gan-an.
Agbe̩nuso̩ ọlọ́pàá ipinle̩ naa, CP Adamu Abdullahi Ellema, sọ pé àwọn ọmọ ogun àti agbofinro ti lọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ si ni wa awo̩n ake̩ko̩o̩ naa.
Be̩e̩ si ni iwadii to gbopo̩n bii awo̩ Erin naa n te̩ siwaju lori ise̩le̩ laabi naa.
Ó tún sọ pé wọ́n máa ṣe àyẹ̀wò ìdí tí ilé ẹ̀kọ́ fi ṣí sílẹ̀ láì tẹ̀lé àṣẹ ìjọba tó ní kí wọ́n ti gbogbo ilé ẹ̀kọ́ ní agbègbè yẹn nípa ààbò to n me̩he̩ lasiko yii.

Àpẹẹrẹ mẹ́jọ láti mọ̀ pe o ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà, ipa rẹ̀ nínú àgọ́ ara ,àti ọ̀nà láti dènà rẹ̀

Àpẹẹrẹ mẹ́jọ láti mọ̀ pe o ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà, ipa rẹ̀ nínú àgọ́ ara ,àti ọ̀nà láti dènà rẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gbémi pamọ́ kí n pa ọ́, tú mi síta kí n fi ọ́ sílẹ̀ lórúkọ tí àrùn n jẹ́,ọ̀kan lára wọn ni àìsàn ìtọ̀ ṣúgà.
Àìsàn ìtọ̀ ṣúgà jẹ́ àìsàn tó máa ń ṣokùnfà ikú tó lé ní mílíọ̀nù kan ní ọdọọdún, tó sì jẹ́ pé kò sí èèyàn tí kò lè ni.

Ohun tó máa ń ṣokùnfà àìsàn yìí ni tí ṣúgà bá ti pọ̀ jù ní ara, tí ẹ̀yà tó máa ń fọ ṣúgà kúrò lára kò lè lọ gbogbo rẹ̀.

Àìsàn yìí le ṣokùnfà kí èèyàn ní àìsàn ọkàn, àìsàn rọpá rọsẹ̀, àìsàn kíndìnrín àti kí egbò má jiná tó le mú kí wọ́n gé apá tàbí ẹsẹ̀ èèyàn.

Àjọ tó ń rí sí ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization, WHO sọ pé èèyàn tó tó mílíọ̀nù 422 ló ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà káàkiri àgbáyé – èyí tó jẹ́ àlékún ìdá mẹ́rin sí iye àwọn tó ni ní ogójì ọdún sẹ́yìn.

Ohun tó léwu níbẹ̀ jùlọ ni pé ìdajì àwọn tó ń ní àìsàn yìí ni wọn kò mọ̀ pé àwọn ni.

Àwọn àmì àpẹẹrẹ kan wà tó jẹ́ pé tí èèyàn bá ti rí lára, ohun tó tọ́ ni pé láti lọ sí ilé ìwòsàn lẹ́yẹ ò sọkà fún àyẹ̀wò.

Lára àwọn àmì àpẹẹrẹ náà ni:

Kí òùngbẹ máa gbẹ èèyàn jù: Lára àmì tí ẹni tó bá ní ìtọ̀ ṣúgà máa ń rí ni pé òùngbẹ máa ma gbẹ wọ́n ní gbogbo ìgbà kódà bí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ mu omi tán. Èyí sì máa ń wáyé bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọ́n máa ń tọ̀ púpọ̀.
Ìtọ̀ gbogbo ìgbà: Èèyàn ma máa tọ̀ léraléra pàápàá ní alẹ́. Ní kété tí ó bá tọ̀ ni ìtọ̀ míì yóò tún máa gbọn èèyàn.
Àárẹ̀ ara: Ẹni tó bá ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ma máa ri pé ó ń rẹ òun ní gbogbo ìgbà láì ṣe iṣẹ́ tàbí wàhálà kan pàtó.
Kí èèyàn máa gbẹ: Tí o bá ri pé ò ń gbẹ ju bí ó ṣe yẹ lọ láì sí pé èèyàn ní àìsàn kan tí kò jẹ́ kí èèyàn jẹun dáadáa, ọ sàn láti lọ ṣe àyẹ̀wò àìsàn ìtọ̀ ṣúgà.
Kí ebi máa pa èèyàn léraléra: lára àmì àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ni kí ebi máa pa èèyàn ní gbogbo ìgbà. Kódà bí èèyàn bá ń jẹun léra, ebi yóò ṣì tún máa pa èèyàn.
Kí ojú máa ṣú: Tí o bá ti ń rí àyípadà nínú bí ó ṣe ń ríran, tó jẹ́ pé ó máa ń ríran dada tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n tí o kò ṣàdédé ríran bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ó sàn láti ṣe àyẹ̀wò ìtọ̀ ṣúgà.
Kí egbò má tètè jiná: Tí egbò bá ń pẹ́ ju bí ó ṣe yẹ lọ kí ó tó jiná jẹ́ àmì àpẹẹrẹ ìtọ̀ ṣúgà.
Kí ẹnu máa bó ní gbogbo ìgbà: Àìsàn ìtọ̀ ṣúgà máa ń ṣokùnfà kí èèyàn ní egbò ní ẹnu.
Èyí ni àwọn àmì àpẹẹrẹ tó ṣe gbòógì tí ẹni tó bá ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà le máa rí, tó sì dára kí ẹnikẹ́ni tó bá ń rí irú àwọn àmì báyìí tètè kàn sí ilé ìwòsàn fún àyẹ̀wò àti ìtọ́jú tó péye.

Ọ̀pọ̀ ẹ̀yà ara tó fi mọ́ ọkàn, kíndìnrín, ọkàn, ojú, àti ẹsẹ̀ ni àìsàn ìtọ̀ ṣúgà máa ń kóbá.

Bí àìsàn bá ṣe pọ̀ lára sí ló máa ń ṣe àkóbá fún ara sí.

Àìsàn ìtọ̀ ṣúgà kìí jẹ́ kí ara le pèsè tàbí lo insulin, ẹ̀yà ara tó máa ń jẹ́ kí ṣúgà ara di ohun àmúṣagbára.

Tí èyí bá ti rí bẹ́ẹ̀, glucose tó máa wà nínú ẹ̀jẹ̀ èèyàn máa pọ̀ si tí kò sí máa ma ṣàkóbá fáwọn ẹ̀yà ara tó ṣe kókó láti gbé ayé ìrọ̀rùn.

Wo àwọn ọ̀nà láti dènà ìtọ̀ ṣúgà
Àwọn dókítà sọ pé àìsàn ìtọ̀ ṣúgà jẹ́ ohun tó máa ń tọ ìran àtàwọn ìgbé ayé tí èèyàn bá ń gbé.

Àmọ́ ó ṣe é ṣe àmójútó pẹ̀lú ọ̀nà wọ̀nyí:

Jíjẹ àwọn oúnjẹ aṣaralóore ní gbogbo ìgbà.
Yíyàgò fún àwọn oúnjẹ inú agolo àtàwọn ọtí ẹlẹ́rìndòdò.
Jíjẹ àwọn oúnjẹ tó ní ṣúgà ní ìwọ̀nba.
Jíjẹ àwọn èso àti ẹ̀fọ́ lọ́pọ̀ ìgbà àti àwọn oúnjẹ tí wọ́n fi ẹ̀wà ṣe.
Jíjéun lásìkò tó yẹ, tó sì dára láti dá oúnjé dúró lẹ́yìn tí èèyàn bá ti yó.
Ṣíṣe eré ìdárayá náà dára láti mú àdínkù bá iye ṣúgà tó ń wà nínú ẹ̀jẹ̀ èèyàn.
Àjọ tó ń ri sí ètò ìlera ní UK, National Health Service ní ó dára láti máa ṣe eré ìdárayá fún ó kéré tán wákàtí méjì àbọ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ kan tó fi mọ́ ìrìn.
Yíyàgò fún sìgá mímu àtàwọn ohun tó fara pẹ jẹ́ ohun tó dára láti dènà àìsàn ìtọ̀ ṣúgà.
Lára àwọn ìgbésẹ̀ láti dènà níní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ni èyí àti láti gba ìwòsàn lórí rẹ̀.

Kókó ìpàdé Nuhu Ribadu pẹ̀lú aṣòfin Amẹrika lórí àwọn alákatakítí

Kókó ìpàdé Nuhu Ribadu pẹ̀lú aṣòfin Amẹrika lórí àwọn alákatakítí

Fẹ́mi Akínṣọlá

Aṣòfin orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà tó sọ pé ìṣekúpani àwọn kìtẹ́nì n ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà, Sẹ́nétọ̀ Riley Moore, ti ṣèpàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn aṣojú orílẹ̀èdè Nàìjíríà tí olùdámọ̀ràn Ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ ààbò, Nuhu Ribadu kó wọn sòdí.

Aṣofin Moore fidi rẹ mulẹ pe oun ṣe ifọrọwerọ pẹlu Ribadu gẹgẹ bii aṣoju Aarẹ Bola Tinubu niluu Washington D.C. l’Amẹrika.

Ọgbẹni Moore sọ pe ipade oun pẹlu Ribadu da lori iṣekupani awọn kristẹni ati ọṣẹ tawọn agbesunmọmi n ṣe ni Naijiria.
Moore ni oun ti sọrọ pẹlu Ribadu lori ọna lati fopin si iṣekupani awọn alaiṣẹ to n waye loorekoore ni Naijiria.

Aṣofin naa sọ pe awọn aṣoju ijọba orilẹede Naijiria sọ nipa awọn nnkan to n kọ ijọba Naijiria lominu lori ọrọ awọn agbesunmọmi ati bi Amẹrika ṣe le ṣeranwọn lati daabo bawọn awujọ tawọn agbesunmọmi yii n ṣekọlu si ni Naijiria.

Moore ṣalaye pe Amẹrika ṣetan lati fọwọ sowọ pọ pẹlu Naijiria, o ni oun sọ fun awọn aṣoju ijọba Naijiria wi pe Amẹrika ko ni gba ki wọn maa ṣeku pa awọn kristẹni lọ ni Naijiria.

Ọrọ ti Moore sọ yii wa ni ibamu pẹlu nnkan ti Aarẹ Donald Trump naa ti sọ tẹlẹ nipa Naijiria.

O ni oun yoo maa tẹsiwaju lati maa wo nnkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria, oun yoo si ri pe Naijiria ṣe ohun to yẹ lati fopin si awọn agbesinmọmi to n ṣe ikọlu sawọn eeyan ni Naijiria.
Lati oṣu Kẹsan an ọdun yii ni ọkan-o-jọkan awọn oloṣelu ti n sọ pe awọn alakatakiti ẹsin islam n ṣekọlu sawọn kristẹni ni Naijiria.

Ọrọ yii jade ninu iṣẹ iwadii Mike Arnold, oniroyin CNN, Van Jomes, Sẹnẹtọ Moore, Sẹnẹtọ Ted Cruz atawọn olorin ẹsin mii naa ti n sọrọ yii bakan naa.

Sẹnẹtọ Cruz to n ṣoju ipinlẹ Texas ti ṣagbatẹru aba kan loṣu Kẹsan an eyi to pe ni ”ába lati ṣe ẹsin to wu eeyan ni Naijiria ti ọdun 2025.”

Aba yii ni o fi fẹsun kan ijọba
Naijiria pe wọn n faye awọn alakatakiti ẹsin islam lati maa ṣekọlu sawọn kristẹni.

Sẹnẹtọ Moore naa ti sọ tẹlẹ pe wọn n ṣekupa awọn kirisitẹni nitori wọn n ṣe esin to wu wọn.

Moore si kọwe si akọwe ijọba awọn ipinlẹ l’Amẹrika, Marco Rubio, wi pe ko gbe igbesẹ lori ọrọ naa kiakia.

Ìkọlù tuntun ní Kwara, agbébọn pa èèyàn méjì, kó mẹ́rin sálọ

Ìkọlù tuntun ní Kwara, agbébọn pa èèyàn méjì, kó mẹ́rin sálọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn agbésùnmọ̀mí ti jí èèyàn mẹ́rin gbé lọ tí wọ́n tún ṣekúpa méjì mìíràn nílùú Bokungi, tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Edu, níìpínlẹ̀ Kwara.

Iṣẹlẹ naa lo waye lẹyin wakati mẹrinlelogun ti awọn agbesunmọ kọkọ kọlu ile ijọsin CAC Oke Isgeun to wa niluu Eruku, ni ijọba ibilẹ Ekiti, nipinlẹ kan naa.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe irọlẹ ni iṣẹlẹ ọhun waye lasiko ti awọn eeyan naa n ṣiṣẹ ninu oko irẹsi wọn.
Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, asiko ti awọn agbẹ naa n kore irẹsi inu oko lawọn agbebọn ṣadede yi wọn ka.

Ẹni to ba awọn akọroyin sọrọ a mọ ti ko fẹ fi orukọ ara rẹ lede ni “lootọ ni awọn agbebọn kọlu Bokungi to wa labẹ Lafiagi.

“Eeyan mẹrin ni wọn ji gbe lọ, a ṣi n ko iroyin naa jọ lọwọ.”

Oun ti a gbọ ni pe eeyan meji ni wọn ṣekupa yatọ si awọn mẹrin ti wọn ji gbe lọ.

Awọn olugbe ilu naa sọ pe awọn agbesunmọmi ọhun ṣọṣẹ fun ọpọ iṣẹju lai si idiwọ kankan ki wọn to dari awọn agbẹ naa sinu igbo ti wọn si gbe wọn lọ.
Wọn ni ọpọ awọn olugbe ilu ọhun lo ti na papa bora latari eto abo to mẹhẹ nibẹ ti ijinigbe si ti di ohun to n waye lemọlemọ.

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, pupọ awọn agbẹ to wa nibẹ ni ko lọ sinu oko mọ lati lọ kore nitori ibẹru awọn ajinigbe.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ati ijọba ipinlẹ naa ko tii sọ ohunkohun lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ipinlẹ Kwara yii kan naa ni agbebọn ti kọlu ile ijọsin lasiko ti isin n lọ lọwọ ti wọn si ji eeyan marundinlogoji lọ nigba ti wọn ṣekupa eeyan meji mii.

Àfi bí àwàdà! Nnamdi Kanu wẹ̀wọ̀n gbére

Àfi bí àwàdà! Nnamdi Kanu wẹ̀wọ̀n
gbére

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja ti sọ olọ́rí ẹgbẹ́ ajìjàgbara fún òmìnira ilẹ̀ Biafra, Nnamdi Kanu sí ẹ̀wọ̀n ayérayé.

Idajọ yii lo n waye lẹyin ọdun mẹwaa ti wọn kọkọ fi ṣikun ofin mu u.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, adajọ Omotoso sọ pe Kanu ko kabamọ ohun to ṣe ni gbogbo asiko ti igbẹjọ rẹ n lọ lọwọ bẹẹni ko tuuba.

O ni Kanu ṣe oniruru igbohunsafẹfẹ lawọn ọdun kan sẹyin lasiko to n pe fun ominira ilẹ Biafra, ati pe awọn igbohunsafẹfẹ ọhun lo ṣokunfa oniruru ifẹmiṣofo to waye ni ila oorun Naijiria nibi ti ọpọ agbofinro ti sọ ẹmi wọn nu.

Idajọ yii lo waye lẹyin ti ile ẹjọ naa ni Kanu jẹbi ẹgbogbo ẹsun meje ti wọn fi kan an, eyii to ni ṣe pẹlu igbesunmọmi.

Ọdun 2009 ni irawọ Kanu kọkọ tan kalẹ ni Naijiria lẹyin to bẹrẹ igbohunsafẹfẹ lori ẹrọ aṣọrọmagbesi Radio Biafra.

Ori redio naa lo ti n pe fun ominira ilẹ Biafra lati ilu London pe ki ẹya Igbo yapa kuro lara Naijiria
Adajọ James Omotosho ti ile ẹjọ giga apapọ ilu Abuja ti fidi rẹ mulẹ pe olori ẹgbẹ IPOB to n jija gbara fun orilẹede Biafra, Nnamdi Kanu, jẹbi ẹsun igbesunmọmi onikoko meje ti wọn fi kan an.
Adajọ Omotosho ni Kanu ti hu oriṣiiriṣii iwa ipa eyi to ti ṣakoba fawọn eeyan rẹ to loun n ja fun un.

Lasiko to n ka idajọ naa ni adajọ sọ pe ki olori ẹgbẹ IPOB jade nile ẹjọ bi o ṣe n ka idajọ rẹ.
Oni ogunjọ oṣu Kọkanla ọdun 2025 yii ni Adajọ Omotosho fi idajọ Kanu si eyi to le jasi idajọ iku gẹgẹ bi iwe ofin Naijiria ṣe sọ.

Adajọ Omotosho bẹrẹ sii jokoo lori igbẹjọ Kanu lati oṣu Kẹta ọdun yii, lẹyin ti Kanu fẹsun kan Adajọ Binta Nyako to n ṣakoso igbẹjọ naa tẹlẹ pe o n figba kan bọkan ninu.

Lati igba naa ni Adajọ Ọmọtosho ko ti fi igbẹjọ naa falẹ rara titi ti oni ọjọ idajọ.

Nigba ti ile ẹjọ beere lọwọ Kanu pe ki lo ni lati sọ ni olori IPOB sọ pe ki lo de ti wọn fi ju oun satimọle lai ṣẹ.

Kanu sọ pe ki wọn fun oun ni beeli.

”Nnkan ti mo n beere ni pe ki wọn jẹ ki n gbe ẹjọ yii lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun.

Bawo ni mo ṣe maa wa lahamọ lori ofin ti ko si ninu ofin Naijiria?

Mo fẹ ki wọn fun mi ni beeli,” Kanu lo sọ bẹẹ.

Amọ, adajọ fesi wi pe ko tọna lati gbe ẹjọ naa lọ si ile ẹjọ kotẹmilọprun lọwọ yii.

Nigba ti adajọ fẹ bẹrẹ sii maa ka idajọ rẹ ni Kanu sọ fun adajọ pe ko fi han ninu ofin nibi ti oun ti ṣẹ.

Bi adajọ ti fẹ sọrọ ni Kanu pariwo mọ ọn pe ko fi ofin to fẹ lo fun idajọ rẹ han oun.

Nigba ti Kanu ko jẹ ji adajọ sọrọ ni adajọ paṣẹ wi pe ko jade kuro ninu ile ẹjọ.

Kanu ko dakẹ ariwo, bo tilẹ jẹ pe adajọ ti paṣẹ pe ko jade kuro nile ẹjọ.

Bakan naa ni ko tun jẹ kawọn ẹṣọ alaabo fọwọ kan an.

Adajọ ni Kanu lẹtọọ lati pe ẹjọ kotẹmilọrun lẹyin idajọ oun, amọ, Kanu si n sọrọ lọ.

O ni adajọ ko mọ ofin, ati pe ofuutu-fẹẹtẹ ni idajọ ti ile ẹjọ fẹ gbe kalẹ.

Adajọ Omotosho fidi rẹ mulẹ pe o wa ninu ofin wi pe bi afurasi ko ba huwa bii Omoluabi, adajọ lagbara lati le e jade ti yoo fi ka idajọ rẹ.