Kàyéfì ni ikú arìnrìnàjò ọkọ̀ òfurufú Kenya ní Naijiria

Kàyéfì ni ikú arìnrìnàjò ọkọ̀ òfurufú Kenya ní Naijiria

‘Aisan lo se wo, a ko ri ti ọlọjọ se’ ni isẹlẹ buruku kan to waye ni Murtala Muhammed International Airport, Lagos.
Arakunrin kan ti wọn forukọ bo lasiri lo wọ baluu Kenya lati Eko lọ si orileede Madagascar sugbọn ti awọn alasẹ ọkọ ofurufu ilu naa ko jẹ ki o wọle, gbogbo akitiyan rẹ ati igbiyanju pẹlu agidi lo ja si pabo gẹgẹ bi ọgbẹni Micheal Achimugu to jẹ ọga kan ni Nigeria Civil Aviation Authority (NCAA) se salaye.
O ni ofin ọkọ ofurufu ni pe ẹni to ba gbe ero lọ, ti isoro tabi idiwọ kan wa naa lo maa gbee pada, lo fi jẹ pe Kenya Airline lo gbe arakunrin naa pada pelu agidi. O ni gbogbo igbiyanju arakunrin naa lati ma se pada si Naijiria lo ja si pabo, nigba ti ko fẹ gba fun wọn , ki o ma lọ daran tabi pa ara rẹ ni wọn ba de e mọ aga kan ninu baluu naa. Igba ti baluu balẹ ni wọn bẹrẹ si ni du emi rẹ ti ẹpa ko boro mọ.
Awọn ọlọpaa orileede yii ti gba iwadii naa kanri. Iwadii to gbopọn ti bẹrẹ nipa iku iyanu arakunrin onisowo naa. O ma se o!

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí irú ìsẹ̀lẹ̀ báyìí máa wáyé –
Ni osu kẹta ọdun 2019, ẹni ọdun mẹrinlelaadọta kan to wọ ọkọ ofurufu Delta Air Lines lati Atlanta ni Amerika wa si Eko gbẹmi mi ni bi o se ku isẹju diẹ ki baluu naa balẹ si Eko.
Ni osu kẹsan-an ọdun 2025, isẹlẹ buruku bẹẹ naa tun sẹlẹ ninu ọkọ ofurufu United Airlines lati Eko si Washington D C.

Àwọn bàlúù tí kò ni ìsẹ̀lẹ̀ burúkú rí –
Easyjet Airlines to bẹrẹ isẹ ni ọdun 1995 ni ilu London.
Etihad Airways bẹrẹ isẹ ni ọdun 2003 ni ilu United Arab Emirates.
Eva Air bẹrẹ ni ọdun 1989 ni agbegbe Europe.
Finnair bẹrẹ ni ọdun 1923 ni orileede Finland.
Hawaiian Airlines bẹrẹ ni ọdun 1929 ni orileede U.S
JetBlue bẹrẹ ni ọdun 2000 ni ilu New York.
Qantas bẹrẹ ni ọdun 1920 ni ilu Australia.
Qatar Airways bẹrẹ ni ọdun 1997 ni orileede Qatar.
Virgin Atlantic bẹrẹ ni ọdun 1984 ni ilu London.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here