Ìfè̩hónú hàn osù ké̩jo̩ jé̩ ìgbáradì fún ìjà-ǹ-gbara – Charly Boy

Ìfè̩hónú hàn osù ké̩jo̩ jé̩ ìgbáradì fún ìjà-ǹ-gbara – Charly Boy

 

Gbajumo atokun eto, Charles Oputa, ti a mo si Charly Boy, ti so pe ona abayo fun eto isejoba ti ko dara ni Naijiria ni ija-n-gbara fun atunse, o ni ifehonu han kaakiri orile ede to waye ni ojo kin-in-ni si ojo kewaa osu kejo je ‘igbaradi lasan’ fun koko eto.

Gbajumo ati ajafeto omoniyan naa sotele pe ija-n-gbara fun atunse yoo waye, won kii yoo kede re saaju, o tenumoo pe ko ni si lori mohunmaworan.

Ninu ifilede kan lori X re, Charly Boy wi pe ijoba Naijiria ti kuna lati menuba iponrere awon odo, ija-n-gbara fun atunse naa le e ba nnkan je, tabi ki o fa itajesile.

O ko o pe, “Yoo gba ija-n-gbara fun atunse lati le ri ona abayo si isoro adari ti ko dara. Mo ri ojo kin-in-ni si ojo kewaa osu kejo bii igbaradi fun ojulowo eto.

“Ojulowo ifehonu yoo waye lai ni ikede. Yoo buru ju ohun ti e lero lo.
IJA-N-GBARA FUN ATUNSE naa ki yoo si lori mohunmaworan.
Biba nnkan je ati itajesile yoo ji dide.

“Pelu ireti, yoo je abayori ti yoo mu ONA ABAYO wa”.

E ranti pe awon odo Naijiria ti wa ni igboro lati ojo kin-in-ni osu kejo, ti won si n kigbe pe ki opin de ba bi nnkan ko se derun ni orile ede yi.

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here