Ó wùmi kí n bí ọmọkùnrin fún Ebuka – Cynthia

Ó wùmi kí n bí ọmọkùnrin fún Ebuka – Cynthia

Cynthia, iyawo Ebuka Obi-Uchendu, atọkun eto Ile Elegbon Agba Naijiria ti safihan pe oun fẹ ọmọkunrin bii ọmọ kẹta.

Bẹ o ba gbagbe,Cynthia ati Ebuka se igbeyawo ni osu keji ọdun 2016, ti Ọlọrun si bukun asopọ wọn pẹlu ọmọbinrin meji, Jeweluchi ati Irubinachi.

Nigba to n sọrọ ninu ijomitoro ọrọ kan lori eto Mum’s Next Door podcast, Cynthia so di mimọ pe oun nifẹ si ọmọkunrin.

Nigba ti wọn bi leere pe boya o si fẹ bi ọmọ miran, o ni; “Bẹẹni, mo fẹ ọmọ kan si. Mo ti bi ọmọbinrin meji bayi adura mi ni lati bi ọmọkunrin kan si.”

Nigba to n da atọkun lohun ẹni to beere boya Ebuka pẹlu fẹ ọmọ miran, o dahun pe, “Ipinnu mi ni. Kiise ti Ebuka.

“Ọkọ mi fẹ ọmọ kan soso nitori pe o fẹ fun ni igbe aye to rọrun.

“O ni owo ile iwe, ati gbogbo nnkan ti wọn ni iye, nitori naa ọmọ kan dara. Sugbọn bayi, o fẹran awọn ọmọ wa, o si da mi loju pe ti a ba bi ọmọ kẹta yoo fẹran oun na pẹlu.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here