‘Àdánù ńlá ni ikú ìyá mi’ – Wizkid

‘Àdánù ńlá ni ikú ìyá mi’ – Wizkid

Mary Fágbohùn

Olorin Naijiria olugbafe eye Grammy, Ayodeji Balogun, ti a mo si Wizkid, si n kedun iku iya re, Mrs Jane Morayo Balogun, eyi farahan ninu orin re tuntun to ko pelu Asake, ‘MMS’.

Ninu ese orin re, Wizkid mu awon oluteti sile rin irin ajo arodokan bi o se so nipa bi iku iya re se yii pada.

Olorin naa safihan pe oun “sonu ” leyin iku iya oun sugbon leyin re o ri eredi iwalaaye fun un.

“O le sa fun iru eni ti o je arakunrin, ohun ti o fe sele yoo sele, arakunrin, ti a so sinu okuta….

Kin ni idi ti iya se fi mi sile, bee ni, ko pe

Mo sonu, mo si ri ereedi iwalaaye mi
Bee ni, lojoojumo, mo mo pe mo di alabunkun…

Ko si oun ti eniyan ko koju, imunidun loni

Iru nnkan yii, wi pe aye ni a wa,” ni o fi korin.

E ranti pe iya Wizkid, Jane Morayo Balogun, jade laye ni ojo kejidinlogun osu kejo, odun 2023, ni London.

Nigba to n seranti ojo ibi iya re leyin iku ni ojo kerin osu keje, Wizkid kigbe pe aye oun sofo laisi iya oun.

O toka sii pe oun n saferi re lojoojumo, o tenumoo pe o ba oun lokan je titi aye.

Wizkid kede pe oun yoo gbe awo orin tuntun jade ni iranti iya oun.

Awo orin naa ni o pe akole re ni ‘Morayo’, to wa lara oruko iya re.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here