Ẹ̀yin ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Algeria, Tunisia, Morocco, ẹ bá wa mú Yahaya Bello tẹ́ ẹ bá rí o – EFCC

Ẹ̀yin ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Algeria, Tunisia, Morocco, ẹ bá wa mú Yahaya Bello tẹ́ ẹ bá rí o – EFCC

Ọrẹ Òtítọ́jù

Yoòbá bọ̀, wọ́n ní ìwákúwàá ohun tó bá sọnù, àti pé bí ẹni à ń pè kò bá tí ì dáhùn, ẹni ń pè’ni kò ní ín dákẹ, èyí ló d’ífà fún bí àjọ tó ń gbógun ti ìwà jìbìtí lílù, ì kówójẹ ní koto ọba àti ìwà àjẹbánú gbogbo nílẹ̀ wa, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) ṣe kégbàjarè s’áwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ àgbáyé, International Police, tí wọ́n ń pè ní INTERPOL láwọn orílẹ-èdè Tunisia, Morocco àti Algeria, pé kí wọ́n wa lójúfò dáadáa báyìí, kí wọ́n máa fura, kí wọ́n sì máa dọdẹ Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi àná, Ọ̀gbẹ́ni Yahaya Adoza Bello, bóyá wọ́n lè kẹ́ẹ́fín rẹ̀, tàbí kó sá pamọ́ sọ́dọ̀ wọn, wọ́n ní kí wón tètè b’áwọn fọwọ́ sìkún òfin mú un, kí wọ́n sì tètè ta àwọn lólobó, k’áwọn lè wá mú un níbikíbi tó bá wà, tàbí kẹ, kí wọ́n fi s’ọ̀kò padà sí Nàìjíríà, torí àwọn sì ń wá bàbá náà lójú méjèèjì.

EFCC ni yatọ s’awọn orileede Ariwa Afrika mẹta t’awọn darukọ yii, wọn tun fẹ k’awọn ọlọpaa orileede Egypt, Libya ati Sudan naa wa lojufo, lati ba wọn mu gomina tẹlẹri yii.

Olofofo kan nileeṣẹ EFCC sọ fawọn oniroyin pe laipẹ yii, Alaga ajọ EFCC, Ọgbẹni Ọla Olukoyede, gba orileede Singapore sọda si Tunisia, nibi to ti ba awọn oniroyin, awọn agbofinro, at’awọn aṣoju alaṣẹ ijọba wọn sọrọ lori igbesẹ lati gbe’gi dina fun awọn onijibiti, at’awọn ti wọn n ṣ’owo ijọba baṣubaṣu, titi kan awọn ti wọn n ji owo ko tọju pamọ si ilẹ okeere.

Nibi apero naa ni Olukoyede ti ṣepade idakọnkọ pẹlu awọn olori ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ agbaye, iyẹn awọn INTERPOL pe ki wọn ṣeranwọ f’awọn lori Yahaya Bello ti ajọ EFCC ti kede pe awọn n wa, o lẹjọ i jẹ lori awọn iwa ikowojẹ to waye lasiko iṣejọba rẹ nipinlẹ Kogi.

Olobo naa sọ pe awọn alaṣẹ INTERPOL ti gba lati ṣeranwọ lori ọrọ yii, ti wọn si ti sọ fawọn ẹṣọ wọn gbogbo lati wa lojufo daadaa, nipa irinsi Bello.

A gbọ pe ọpọlọpọ eto ati igbesẹ lo ti n lọ wẹrẹwẹrẹ labẹnu lati fi pampẹ ofin gbe Bello.

Wọn ni sisapamọ ti Yahaya Bello sapamọ jẹ ọna ẹtan lati ma ṣe kawọ pọnyin ro’jọ ni kootu lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an, eyi ti EFCC lawọn ti ṣewadii rẹ, ẹri si wa daadaa pe ọkunrin naa lẹbọ lẹru.

Ẹ o ranti pe obitibiti owo ti iye rẹ ju biliọnu lọna ọgọrin Naira lọ ni EFCC lo poora mọ Yahaya Bello lọwọ gẹgẹ bii Gomina ipinlẹ Kogi, eyi ti wọn fi tori ẹ kọwe si i pe ko yọju si wọn, amọ ti ko ṣe bẹẹ. Kaka bẹẹ, niṣe l’ọkunrin naa gbọna ẹyin sa mọ awọn EFCC lọwọ l’oṣu Karun-un, ọdun yii, nigba ti wọn wa a lọ lati fi pampẹ ọba gbe e.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here