Blackface pè fún ìpàdé Plantashun Boiz

Blackface pè fún ìpàdé Plantashun Boiz

Mary Fágbohùn

Olorin, Augustine Amedu Obiabo, ti a mo si Blackface, ti pe fun atunjopade Plantashun Boiz, egbe orin kan eyi ti 2Face, Faze ati oun funra re wa.

Olorin ‘Hard Life’ naa lo si ori Instagram re laipe yi lati pe awon omo egbe orin re teleri fun ipade.

O toka sii pe agbara wa ninu isokan.

Blackface ro awon afenifere lati ba oun parowa si 2Baba ati Faze ki won dahun ipe isokan re.

O ko o pe: “Plantashun Boiz, ibeere naa ni pe se ki o wa bee tabi ki o ma wa bee, ati pe kin ni idi? @fazealone @official2baba.

“Eyin eniyan mi, o ya, e ba mi da si oro yi! A wa lori ise fun alaafia agbaye, kii se nnkan kekere!

“Isokan ni okun kii se iyapa. E je ki a lo eyin asegun.”

Plantashun Boiz pinya ni 2004 nigba ti won gbe awo orin ‘Sold Out’ jade.

Ni 2007, egbe naa se atunjopade fun awo orin won keta ati eyi to gbeyin ‘Plan B’, saaju ki won tun to pinya.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here