Ìpalára ńlá ni òjò sé sí ojú òpópónà mọ́tò nípínlẹ̀ Ògùn

Ìpalára ńlá ni òjò sé sí ojú òpópónà mọ́tò nípínlẹ̀ Ògùn

Ọlámídé Motúnráyọ̀

Òjò àrọ̀rọ̀dá kan tó rọ̀ láìpẹ́ yìí, lápá ìwọ̀ òòrùn Nàíjíríà ṣe ìjàmbá sí ojú ọ̀nà márosẹ̀ lójú títì; àwọn onímọ́tò ò ríbi gbà, ẹlẹ́sẹ̀ náà kò ríbi rìn.

Ohun tójú ń rí láwọn òpópónà tó wà ní ìpínlẹ̀ Ògùn, tí fi ọ̀pọ̀ àṣírí hàn gbangba pé àwọn òpópónà ti di ẹgẹrẹmìtì. Ní èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ aráàlú sì da ẹnu bo ìpínlẹ̀ Ògùn jùlọ, lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Èyí mú ikọ̀ akọ̀ròyìn tẹkọ̀létí gba ìpínlẹ̀ Ògùn lọ láti fi ojú gánní ipò tí àwọn òpópónà náà wà àti ìrírí àwọn
aráàlú lágbègbè náà nípa àwọn òpópónà yìí.

Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ náà pàápàá àwọn awakọ̀ àtawọn oníṣòwò ni wọ́n ké tantan, tí wọ́n sì ń fi àìdunnú wọn hàn sí ipò ti àwọn òpópónà naa wà léyìn tí ó sì ń jẹ́ ọgbẹ́ ọkàn fún wọn. Wọ́n ní kìí ṣe ọṣẹ́ díẹ̀ ni àwọn òpópónà náà ti ṣe kó bá ọrọ̀ ajé wọn tí awọn mìíràn tilẹ̀ ní ó ti rán àwọn lọ sí oko gbèsè.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here