Ará ìlú nìkan ló leè fi Olubadan sórí ìtẹ́, kìí ṣe Gómìnà – Rasheed Ladoja ṣàlàyé

Ará ìlú nìkan ló leè fi Olubadan sórí ìtẹ́, kìí ṣe Gómìnà – Rasheed Ladoja ṣàlàyé

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní àìfẹ̀lẹ̀ kébòsí,làì rẹ́ni jó o.
Ọ̀tún Olúbàdàn ti ilẹ̀ Ìbàdàn, Sẹ́nẹ́tọ̀ Rasheed Ladoja ti sàlàyé pé, Gómìnà kọ́ ló làṣẹ láti fi Olúbàdàn tuntun sórí ìtẹ́ .

Gbólóhùn yí jẹyọ lẹ́yìn tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣeyi Makinde sọ pé, òun kò ní ṣètò ìfọbajẹ fún Ọba Owolabi Olakulehin tí wọ́n fà kalẹ̀ láti jẹ Olúbàdàn ti ìlú Ìbàdàn àyàfi tí ipò ìlera rẹ̀ bá wà ní pípé.

Àgbà oyè ilẹ̀ Ìbàdàn, Rasheed Ladọja sọ̀rọ̀ níbi pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ọdún Iléyá tó wáyé nílùú Ìbàdàn, pé kò sí òótọ́ nínú ìròyìn tó gbòde pé òun ló wà nídìí bí Gómìnà Makinde kò ṣe fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ fífi Olúbàdàn tuntun jẹ.

Ladoja sàlàyé pé, ọwọ́ àwọn ará ìlú ni àti fi Olúbàdàn tuntun sórí àpèrè wà, ìgbésẹ̀ náà kò sí lọ́wọ́ Gómìnà Seyi Makinde rárá.

“Ojúṣe Gómìnà ní láti gbé ọ̀pá àṣẹ pẹ̀lú àwọn ohun èlò mìíràn tí Ọba náà yóò máa lò lórí ìtẹ́ fún un, torípé dúkìá ìjọba ni àwọn èròjà náà jẹ́.”
Ladoja sàlàyé pé, Olúwo tìlú Ìbàdàn nìkan ló lágbára láti gbé adé lé Olúbàdàn tuntun lórí, tí Gómìnà yóò sì fún un ní ọ̀pá àṣẹ àti àwọn èròjà yòókù.

Ó tún tenumọ́ pé ìbáṣepọ̀ tó gún régé ló wà láàrin ohun àti Gómìnà Makinde àti pé Gómìnà ti kí òun kú ọdún Iléyá pẹ̀lú ẹ̀bùn tó jọjú.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here