Ṣáà ọdún mẹ́fà tó fun ààrẹ àti àwọn gómìnà–Àwọn asòfin.

Ṣáà ọdún mẹ́fà tó fun ààrẹ àti àwọn gómìnà–Àwọn asòfin.

Gbọ́láhàn Quseem

Àwọn aṣòfin Nàíjíríà kan ti da làbàá pe, kí àwọn ààrẹ àti àwọn Gómìnà maa lo sáà kan ṣoṣo tí yo jẹ́ ọdun mẹ́fà.
Wọn n gbero lati fi eyi dipo saa ọdun mẹrin ti wọn ma n ṣe l’ẹẹmeji.

Awọn aṣofin naa ti Ikenga Ugochinyere, to n soju ẹkun idibo Ideato Federal Constituency, sọ pe atunṣe si ofin ọdun 1999 yoo mu ayipada rere ba iṣejọba nilẹ Naijiria.

Aba ofin ọun to ti wọ ipele kika keji bayi, ni wọn ṣalaye pe yo mu adinku ba iye owo iṣejọba ati ipolongo ibo.

Bakannaa, ni wọn ni yo mu ki iṣọkan, idagbasoke ati idajọ ododo wa, ti yoo si tun dena magomago lasiko idibo nitori pe ajọ INEC yo ni ominira.

Awọn aṣofin ọun labẹ aburada Reform Minded Legislators, tun d’abaa pe ki igbakeji aarẹ jẹ meji. Ki ẹnikan lati Gusu,ki ikeji wa lati Ariwa.

Igbakeji aarẹ akọkọ ni yo dabi adele, o si gbọdọ wa lati ẹkùn kan naa pẹlu aarẹ ọun. Oun ni yoo si rọpo aarẹ ti ko ba l’agbara lati ṣe ijọba mọ.

Ẹnikeji yo si jẹ minisita fun amojuto eto ọrọ aje nilẹ Naijiria.

Ẹgbẹ aṣofin naa tun fẹ ki idibo Gomina ni gbogbo ipinlẹ mẹrẹrindinlogoji maa waye ni akoko kan naa.

Wọn ni awọn n fẹ ki aarẹ maa wa lati ẹkun mẹfẹẹfa to wa ni Naijiria, ni ṣiṣẹ-n-tẹle. Igbagbọ wọn ni pe yo din kirakita lati d’ori alefa aarẹ, ku.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here