Ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gọ́ta tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ san fún wá kò b’ ẹ́rìn-ín dé o, àádọ́tadinlọọdunrun ẹgbẹ̀rún naira la fẹ́ – NLC/TUC
Quseem Gbọ́láhàn
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà (NLC) ní òun kò ní faramọ́ owó tó dín ní aadọtadinlọọdunrun ẹgbẹ̀rún náírà (#250,000), gẹ́gẹ́ bí owó oṣù òṣìṣeẹ́ tó kéré jùlọ.
Igbakeji akọwe agba ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC, Chris Onyeka ni ẹgbẹrunmejilelọgọta naira (#62 ,000) ti ijọba fi lọ awọn ko ni jẹ atẹwọgba, bẹẹ lawọn ko ni gba ẹgbẹrunlọnaọgọrun náírà (#100,000) ti awọn eeyan kan ni ki awọn gba.
Ọrọ yi lo n jade lẹyin ti alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ọun, Joe Ajaero sọ pe awọn n duro de esi Aarẹ Bola Tinubu lori ọrọ naa ati igbesẹ ti yoo gbe.
Ni lọọlọọọ yi, ni ọfisi akọwe ijọba apapọ jabọ pe, igbimọ to n jiroro lori ọrọ owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ naa ti jabọ ijiroro rẹ fun ijọba.
Ṣaaju, lẹyin ipade igbimọ ọun ni ijọba ti kọkọ sọ pe ẹgbẹrunmejilelọgọta ni agbara oun gbe, gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ, ti ẹgbẹ oṣiṣẹ si yari pe owo ọhun ti kere ju, ati pe aadọtadinlọọdunrun ẹgbẹrun naira (#250,000) l’awọn o gba.
Ẹwẹ, bi awọn araalu ṣe n jẹ ọrọ naa lẹnu ni ẹgbẹ awọn Gomina ni Naijiria kede pe awọn ko ni le san owo oṣiṣẹ to kere julọ to ba le ni ọgọtaẹgbẹrun naira (#60,000)
Agbenusọ igbimọ ijọba to n jiroro lori ọrọ naa, Segun Imohiosen, sọ pe igbimọ oun ti pari ijiroro rẹ, o si ti fun akọwe ijọba apapọ ni ohun to ba bọ “.
“Wọn yoo fun Aarẹ ni esi ti awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ, aṣoju ijọba ati awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ aladani ba pada de lati apero ẹgbẹ oṣiṣẹ agbaye ti wọn lọ ṣe ni Geneva, Switzerland.”