Àwọn agbébọn pa àádọ́ta èèyàn,tí wọ́n sì tún jí ọ̀pọ̀ èèyàn gbé lọ ni Katsina.
Gbọ́láhàn Quseem
Kò dín ní èèyàn márùndínlọ́gbọ̀n ti awọn agbebọn tún ti ṣekúpa, tí wọ́n sì tún jí ọpọ gbe lọ lasiko rúkèrúdò to waye ní ‘pínlẹ̀ Katsina.
Awọn olugbe agbegbe Yargoje sọ fun awọn akọroyin pe awọn agbebọn tun ti ṣe ikọlu si agbegbe naa.
Wọn ni awọn agbebọn kan sadede yabo ilu naa pẹlu ọkada ni alẹ, ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn ti wọn fi ji ọpọ eeyan gbe lọ.
“Awọn eeyan ti awọn agbebọn yi ṣekupa le ni aadọta nitori a si n ri oku awọn eeyan ninu igbo.”
“Wọn ṣekupa ọmọde, obinrin ati ọkunrin, wọn tun wa ji ọpọ eeyan gbe lọ.
“Eeyan to le ni ọgbọn lo tun farapa yanayana ninu ikọlu naa, ti wọn wa ni ile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju.” Eyi ni ọrọ olugbe kan ti ko fẹ darukọ rẹ.
Bakan naa, Al Hassan Ya’u ba awọn akọroyin sọrọ lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ pe iṣẹlẹ naa ba awon eeyan lojiji.
“Wọn kan da ‘bọn bolẹ, ti wọn si ṣekupa aadọta eeyan, pẹlu aburo mi,” Al Hassan Ya’u ṣalaye lori foonu.
Olugbe agbegbe naa, Abdullahi Yunusa sọ fun akọroyin pe ori lo ko oun yọ nigba ti awọn agbebọn naa kọlu ilu rẹ.
“Wọn sọ ilu wa di ilẹ ‘paniyan, ko fẹ si ile ti ko fara gba nibi iṣẹlẹ yii.
“A si n ri oku awọn eeyan ninu igbo.” O ṣalaye bẹẹ.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Kọmisana fun ile-iṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Katsina, Nasiru Babangida Mu’azu sọ fun oniroyin pe awọn ẹsọ alabo to n sọ agbegbe naa wa lara awọn to fara kasa ikọlu naa.