Ó dójú ẹ̀! Ọjọ́ Ajé lẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fẹ́ bẹ̀rẹ̀ kọ̀yìnṣíṣẹ́ jákèjádò Orílẹ̀ yìí.
Ọrẹ Òtítọ́jù
Níbi ọ̀rọ̀ dé báyìí,aráàlú ní tètè wọ́nà àbáyọ kí wọ́n lè máa rí nnkan jẹ, kọ́rọ̀ ó tó bẹ́yìn yọ torí bí ìhàlẹ̀ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ orílẹ̀-èdè yìí, ‘Nigeria Labour Congress’ (NLC), àti àjọ ọlọ́jà orílẹ̀-èdè yìí ‘Trade Union Congress’ (TUC), sọ bá jẹ́ òtítọ́, ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹta, oṣù Kẹfà, ọdún 2024 yìí, ni gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọba àti ti aláàdáni yóò kọ̀yìn ṣíṣẹ́, olóko kò ní-ín lè roko, olódò kò ní-ín le rodò, gbogbo ẹsẹ̀ gìrì gìrì lọ́fíìsì àti ilé-èkọ́ yóò di gbígbé ti pa latari ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ tí wọ́n kéde pé àwọn yóó gùn lé jákè-jádò orílẹ̀èdè yìí. Ìyanṣẹ́lódì ọ̀hún máa bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀gànjọ́ òru ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kejì, oṣù Kẹfà, ọdún yìí.
Niṣe ni awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati ti olokoowo, TUC, Kọmureedi Joe Ajaero ati Festus Osifo, n tu bii ejo sebe tinu n bi lasiko ti wọn n sọrọ ọhun di mimọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, lẹyin ipade pajawiri kan to waye laarin awọn aṣoju ijọba apapọ ati ti ẹgbẹ mejeeji naa.
Ajaero ni o ṣe pataki pupọ fawọn lati gun le iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ, ti ko ni gbedeke ìgbà ti wọn yoo jáwọ ninu rẹ naa nitori bi ijọba orileede yii ṣe n fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ owo-oṣu tuntun tawọn n beere lọwọ wọn, ati owo ina ẹlẹntiriiki tawọn ni kijọba da pada si bọ ṣe wa tẹlẹ.
Aarẹ ẹgbẹ naa waa rawọ ẹbẹ sawọn araalu gbogbo ti igbesẹ wọn maa ni ipalara gidi fun pe ki wọn fọwọ wọnu, ki wọn fọwọ-sowọ-pọ pẹlu awọn, nitori pe ija gbogbo araalu lawọn n ja.
O ni, ‘Mo mọ daju pe igbesẹ ta a fẹẹ gbe yii maa ṣakoba nla fawọn araalu kan, mo n bẹ wọn ni, pe ki wọn fọwọ-sowọ-pọ pẹlu wa, ija ilu la n ja bayii, o si daju pe aa so eeso rere nigbẹyin ni. O ṣe pataki pupọ fun wa lati bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ naa bayii, kawọn alaṣẹ ijọba apapọ orileede yii le mọ pe a ko fọrọ naa ṣere rara, wọn ko da wa lohun awọn ohun taa beere lọwọ wọn gbogbo, a n fẹ owo-oṣu tuntun lọwọ wọn, wọn ko da wa lohun, bẹẹ la n sọ pe ki wọn da owo ina pada si bo ṣe wa tẹlẹ, wọn ko da wa lohun’. Gẹgẹ bi wọn ṣe wí.