Ọ̀dọ́kùnrin kan pàdè ikú òjijì lọ́wọ́ àwọn darandaran nílùú Ògbómọ̀ṣọ́

Ọ̀dọ́kùnrin kan pàdè ikú òjijì lọ́wọ́ àwọn darandaran nílùú Ògbómọ̀ṣọ́

Ọrẹ Òtítọ́jù

A kíí gbélé ẹni ká fọrùn rọ́ ní àwọn àgbà sọ.
Inú ọ̀fọ̀ làwọn olùgbé abúlé Elémúye, níjọba ìbílẹ̀ Surulere, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, wà bàyìí pẹ̀lú bí àwọn afurasí Fulani ọlọsín màálù kan ṣe lọ̀ọ́ ká ọ̀dọ́mọkùnrin àgbẹ̀ kan, Adigun Solomon Adeyẹmi, mọ́’nú oko lágbègbè Ogbomọṣọ, tí wọ́n sì pa á bíi ẹni pẹran.

Ninu oko baba ẹ to wa nibi ti wọn n pe ni Oke-Asa, nitosi Iwofin, nijọba ibilẹ Surulere, niṣẹlẹ ọhun ti waye lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun (22), oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii.

Pipa ti wọn pa ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelọgbọn (31) yii, lawọn olugbe abule Elemuye ṣapejuwe gẹgẹ bii igba teeyan ba gbẹsan iwa ika tabi bii igba teeyan ba foró yaró latari ija kan to ti waye laarin oloogbe naa pẹlu awọn ọdaju eeyan to pa a wọnyi.

Oun ti a gbọ ni pe, agbẹ ọlọgbin kaṣu ni baba Ọgbẹni Adeyẹmi. O si ti to bii ẹẹmeloo kan ti awọn Fulani ti da awọn maaluu lọ sinu oko baba naa, ti wọn si ba awọn ohun ọgbin inu ẹ jẹ.

Ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin ni wahala bẹ silẹ, nigba ti ọkunrin ti wọn tun pe loniṣowo kòkó yii gbena woju awọn darandaran ọhun, ti ọkan ninu awọn maaluu wọn si ba iṣẹlẹ ọhun rin.

Ọkan ninu awọn ara abule ọhun, ẹni to kọ lati darukọ ara ẹ, ṣalaye fun akọroyin wa pe, “Lọjọ keji iṣẹlẹ yii lawọn Fulani fi ọlọpaa mu baba ọmọkunrin yii, ko too di pe wọn ṣọ oun naa de ọgangan ibi to wa ninu oko naa, ti wọn si lu u bii ejo aijẹ, ti wọn si sa lọ nigba ti wọn gburoo pe awọn eeyan n bọ lọọọkan.

“Awọn eeyan gbe ọmọ yẹn lọ sileewosan BOWEN, to wa niluu Ogbomọṣọ, ṣugbọn ko pẹ ti wọn gbe e debẹ lo dagbere faye”.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ lọkandinọgbọn (29), oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii, lawọn daradaran lọọ ka ọkunrin agbẹ kan, Ajihinrere Ṣẹgun Adegboyega, naa mọ inu oko ẹ to da sẹyinkule ile wọn labule kan lọna Ogbomọṣọ siluu Isẹyin, ti wọn si pa a bii ẹni pẹran, nitori bi oun naa ṣe kilọ fun wọn pe ki wọn yee fi maaluu wọn ba ohun ọgbin oko oun jẹ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here