Ọ̀rọ̀ rè é o lórí òfin àfàró tí CBN fi de Opay, Palmpay

Ọ̀rọ̀ rè é o lórí òfin àfàró tí CBN fi de Opay, Palmpay

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN ti ní àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní gba àwọn iléeṣẹ́ dókoòwò orí ayélujára bíi Opay, Palmpay, Kuda àti Moniepoint láàyè padà láti máa gba oníbàárà tuntun láìpẹ́.

Gómìnà CBN, Olayemi Cardoso ló sọ èyí níbi àpérò ìgbìmọ̀ Monetary Policy Committee (MPC) tó wáyé ní Abuja.

Níbi àpérò náà ni wọ́n ti mú àlékún bá àlékún ẹ̀yáwó láti ìdá 24.75 di 26.25.

Cardoso ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ ni àwọn ti bá ṣe ìpàdé láti báwọn sọ̀rọ̀ lórí àwọn ọ̀nà tí wọ́n máa gbà láti mú kí iṣẹ́ wọn dúró ire ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.

Ó ní ìgbìyànjú láti dènà ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ àti láti dènà kí àwọn kan máa fi akoto owó olówó gbé owó jáde lọ́nà àìtọ́ ni àwọn fi gbé àwọn ìgbésẹ̀ láti pọkún ààbò gbígba àwọn èèyàn láti ṣí àwọn akoto owó tuntun.

“Mo ní ìdánilójú pé nígbà tó bá yá ní oṣù díẹ̀ sí àsìkò yìí, gbogbo àwọn nǹkan yìí ma ti di ohun ìgbàgbé, táwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka yìí máa bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iṣẹ́ wọn bíi ti tẹ́lẹ̀ àmọ́ pẹ̀lú ìlànà tó gbópọn sí i.

Ẹ ó rántí pé nínú oṣù Kẹrin ni CBN fòfin de àwọn ilé ìfowópamọ́ orí ayélujára láti yé ṣí akoto owó fún àwọn oníbàárà tuntun.

Ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà náà sọ pé ìgbésẹ̀ CBN yìí fẹ́ kan ìyẹ́ apá àwọn ilé ìfowópamọ́ náà àmọ́ Cardoso ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ọ̀rọ̀ náà.

Ó ní àwọn kò yan àwọn ilé ìfowópamọ́ náà sójú tàbí gbé ìgbésẹ̀ tó máa pawọ́n lára àti pé CBN yóò túnbọ̀ máa ṣe àtìlẹyìn fún wọn nítorí ohun ribiribi tí wọ́n ń gbéṣe.

Ẹ̀wẹ̀, ó ní ó pọn dandan kí àwọn máa ṣe àmójútó ìgbésẹ̀ wọn nítorí bí wọ́n ṣe ń gòkè àti bí àwọn ìwà kò tọ́ kan ṣe ń wáyé láti ẹ̀ka náà.

Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn iléeṣẹ́ aláàbò láti mọ àwọn ibi tó yẹ láti mójútó ní ẹ̀ka náà.

Bákan náà ló fi kun pé àwọn kò gba ìwé àṣẹ àti máa ṣiṣẹ́ nínú àwọn ilé ìfowópamọ́ náà, pé gbogbo wọn ló lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin láti máa bá iṣẹ́ wọn lọ báyìí.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here