Níkẹyìn wọ́n ti sin òkú gbajúmọ̀ òṣèré nì, Junior Pope

Níkẹyìn wọ́n ti sin òkú gbajúmọ̀ òṣèré nì, Junior Pope

Ọlámídé Motúnráyọ̀

Gbajúmọ̀ òṣèré sinimá Nollywood, Obumneme Odonwodo tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Junior Pope tó kú sínú ìjàm̀bá okọ̀ ojú omi odò ọya ìyẹn River Niger níbi tí ó tí ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ ni ọjọ́ kẹ́wàá, oṣù kẹrin, ọdún 2024 yìí ni wọn ti sìnkú rẹ̀ báyìí.

Ní ọjọ́ tí ìjàm̀bá okọ̀ ojú omi náà wáyé ni Junior Pope fi fídíò kan sórí ayélujára nípa bí àwọn òṣèré ṣe
máa ń fi ẹmí ar̀a wọn wéwu láti wá oúnjẹ oòjọ́ wọn.
Fídíò náà ń ṣàfihàn bí Junior Pope àtàwọn yòókù rẹ ṣe wà nínú ọkọ̀ ojú omi lórí odò River Niger láì
wọ aṣọ ààbò. Ó ń sọ nínú fídíò náà pé òun ní ọmọ mẹta, òun sì ni yóò tọ́jú wọn, tí òun máa rè wọ́n dàgbà.
Níbẹ ló ti ń bẹ awakọ̀ ojú omi náà pé kó ṣe jẹjẹ́ nítorí òun nìkan ni àwọn òbí òun bí.

Ní ọjọ́ Ajé Mọ́ńdè ọjọ́ kẹtàlá oṣù karùn ún ọdún 2024 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ ètò ìsìnkú rẹ̀ pẹ̀lú ìsìn Ìdágbére ní ilé ìjọsìn
Christ the King Parish ní ìlú Enugu. Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun Túsìdèé, ọjọ́ kẹrìnlá oṣù karùn ún ni ètò àṣálẹ́ ìrántí wáyé fún olóògbé Junior Pope. Ọjọ́bọ̀ Tọ́sìdàé ni ìsìn àṣálẹ́ onígbàgbọ́ wáyé fún òkú rẹ̀ ní ìlú ìbínibí rẹ̀, Uwala Abaka, Ukehe ní Nsukka. Ní ọjọ́ Ẹtì ni wọ́n sin òkú rẹ̀

Lẹ́yìn ikú Junior Pope, Ààrẹ ẹgbẹ àwọn òṣèŕé ìyẹn Actors Guild of Nigeria (AGN), Emeka Rollas Ejezie ti fòfin de yíya sinimá àbí ṣíṣe eré ní etí odò tàbí lórí omi látara ìjàm̀bá tó wáyé náà. Bákan náà, AGN ní àwọn ti fòfin dè fíìmù “Another Side of Life”. Fíìmù yìí ni Junior Pope àtàwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ mẹ́ta mìíràn táwọn náà kú lọ yà ní ìpínlẹ Delta kí wọ́n tó ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ wọn. Ní ọjọ́ kọkànlá, oṣù kẹrin ọdún yìí. Ẹgbẹ̀ AGN fi àtẹ̀jáde léde tí wọ́n sì tún fi kún pé òṣèŕé kankan kò gbọdọ̀ bá Adamma Luke ṣiṣẹ mọ́. Adamma Luke ni ó ni eré tí àwọn Junior Pope lọ ṣe.

Wọ́n gbàdúrà kí Ọlọ́run tẹ àwọn tó pàdánù ẹmí wọn sí afẹ́fẹ́ rere.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here