Alága ọlọ́kọ̀ èrò tẹ́lẹ̀rí nípínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Auxiliary rẹ́wọ̀n he!

Alága ọlọ́kọ̀ èrò tẹ́lẹ̀rí nípínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Auxiliary rẹ́wọ̀n he!

Ọlámídé Motúnráyọ̀

Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ tí àwọn agbófinró ti kéde síta pé àwọn wá Auxillary, nínú oṣù yìí ni ìròyìn jáde pé àwọn agbófinró ti lọ mú ún. Àjọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS ló lọ gbé alága ìgbìmọ̀ alámòjútó àwọn gáréèjì ọkọ̀, PMS, tẹ́lẹ̀rí l’Óyò.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé àhámọ́ iléeṣẹ́ olópàá ni alága tẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ́ awakọ̀ nípìnlẹ́ Ọ̀yọ́, Alhaji Làmídiì Múkáílà, ẹni ti ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ síi Auxillary wà báyìí; wọ́n fojú ẹ̀ hàn, léyì tí wọ́n sì ka ẹ̀sùn orísirísi sí i lẹ́sẹ̀.

Àwọn ẹ̀ṣùn tí wọ́n fi kan Auxillary, ẹni tí wọ́n furasí pé ó lọ́wọ́ nínú: ìjínigbé lágbègbè Òkè-Ògùn àti Ìbàràpá, ìṣekúpani, ìgbìmọ̀ láti gbẹ̀mí eniyan, ṣíṣe ènìyàn lésè, ìpànìyàn, kátàkárà ìbọn àti ìdigunjàlè.

Kọmísánà fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nípínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Adébọ́lá Hamzat ní afurasí náà yóò fojú ba iléẹjọ́ láìpẹ́ láti wí tẹnu rẹ̀ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fikàn. Látàrí àwọn ohun ìjà olóró tí wọ́n rí ní ilé rẹ̀ ní agbègbè Alákíá-Ìṣẹbọ lábẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Ẹgbẹ́dá ni ìbọn AK47, Ilé ọta ìbọn mẹ́rin, ìbọn Pumb Action, Ìbọn Barreta, Ìbọn cut to size àti ìbọn òyìnbó kan; pẹ̀lú àwọn ọta ìbọn 724, Àdá 25, Ọ̀bẹ Jack 7, ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ 33, Ẹ̀rọ kọ̀mpútà , Òògùn abẹnu
gọ̀gọ̀, Ọkọ̀ akérò Mazda, Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Toyota Sienna, àti Owó tótó N3.45m.

Ṣáájú kí ọwọ́ tó tẹ Auxillary, lo tí ní gbogbo ohun tí àwọn iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣàfihàn gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà olóró tí wọ́n kó ní ilé òun, kò kí se tirẹ̀ rárá, tí wọn kò sì lè kéde pé wọ́n ń wá òun nítorí òun kò tàpa sófin tàbí wùwà jàndùkú kankan. Ó ní bí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe kéde pé wọ́n wá òun ni kò bójú mu, tí kò dẹ̀ kí ń ṣe ti tòun rárá nítorí òun kò kọjá àyè òun tàbí fa wàhálà.

Ní báyìí, Auxiliary ti wà láhàámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Agodi, n’Íbàdàn; látàrí ẹ̀sùn mẹ́rin gbòógì tí wọ́n fi kàn. Èyí kò sẹ̀yìn àṣẹ tí ilé ẹjọ́ Májísírèètì tó wà ní ìyágànkú nílùú Ìbàdàn filéde, láti ẹnu Onídàájọ Ọlábísí Ògúnkànmí; tó pàṣẹ pé kí wọ́n tọ́jú olùjẹ́jọ́ náà pamọ́ sí àhámọ́ títí di ọjọ́ kọkànlá, oṣù Kẹfà, ọdún 2024 yìí. Nígbà tí ìmọ̀ràn yóò ti wá láti ọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ ìdájọ́ nípínlẹ̀ Ọ̀yọ́, lórí ilé-ẹjọ́ tó lágbára láti gbọ́ ẹjọ́ náà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here