Kàyéfì ni ìwọ́de àwọn aláìsàn ọpọlọ tó ń gba ìtọ́jú ní Árò jẹ, kódà wọ́n gé dókítà jẹ yánna-yànna.

Kàyéfì ni ìwọ́de àwọn aláìsàn ọpọlọ tó ń gba ìtọ́jú ní Árò jẹ, kódà wọ́n gé dókítà jẹ yánna-yànna.

Ọlámídé Motúnráyọ̀

Àrà me è rírí nìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ l’ọ́jọ́rú wẹ́sìdàé, ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù Karùn-ún ọdún 2024 yìí. Níbi tí àwọn alárùn ọpọlọ ti faraya. Nǹkan kò ṣe ẹnu re nílé ìwòsàn ìtọ́jú alárùn ọpọlọ tó wà ní Árò, nílùú Abéòkúta.

Àwọn tí wọ́n ti ń ní àlàáfíà nínú àwọn aláìsàn náà la gbọ́ pé wọ́n yarí mọ́ àwọn olùtọ́jú àti aláṣẹ
iléèwòsàn náà lọ́wọ́. Kódà, wọ́n ní díẹ̀ ló kù kí dókítà kan àti àwọn nọ́ọ̀sì mẹ́ta pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àwọn olùfẹ̀hónù hàn náà, bí kò ṣe orí tó kó wọn yọ. Pẹ̀lúpẹ̀lú ẹ̀ náà, dókítà kan foríkó ìyà lọ́wọ́ àwọn alárùn ọpọlọ tí àlàáfíà ti ń to náà.A gbọ́ pé wọ́n gé e jẹ yánna-yànna ni. Àfìgbà tí àwọn ọlọ́pàá téṣàn Láfẹ́n̄wá wáá yanjú wàhálà náà ni àlàáfíà tóó jọba.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ tí áwọn aláìsàn tó ń gbàtọ́jú fi dojú ìjà kọ àwọn tó ń tọ́jú wọn ni pé, wọ́n bínú lórí ìwà táwọn aláṣẹ àti àwọn dókítà Árò ń hù. Wọ́n ní wọn kì í fún àwọn lóúnjẹ tó dáa. Bí iná ọba bá lọ, wọ́n ní òkùnkùn birimù làwọn yóò wà, àwọn aláṣẹ Árò kò ní í wá ọ̀nà láti tan ẹ̀rọ amúnáwá, bẹ́ẹ̀ wọ́n ń gbówó ribiribi lọ́wọ́ àwọn èèyàn àwọn. Láti ṣe ìgbọ̀nṣẹ̀ tàbí tura kò tún dẹrùn gẹ́gẹ́ báwọn èèyàn náà ṣe wí. Bákan náà, wọ́n ní àwọn kò lè rìn yan fanda nínú ọgbà tó bẹ́ẹ̀, àwọn kò tún ní anfààní láti lè rí àwọn ẹbí àwọn tí yóò mú wọn padà sílé. Wọ́n ní ó ti pẹ́ táwọn ti ń kojú àwọn ìṣòro yìí, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀.

Ẹnìkan tó jẹ́ ẹbí ọkàn lára àwọn èèyàn náà ṣàlàyé, pé bó ṣe rí gẹ́lẹ́ ni àwọn olùgbàtọ́jú náà sọ yẹn. Ó ní owó ńlá ni àwọn aláṣẹ iléèwòsàn àìsàn ọpọlọ yìí ń gbà, èyí tó kéré jù ni Ìdajì mílíọ̀nù náírà (#500,000). Obìnrin náà sọ pé nígbà mì-ín, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (#700,000) ni wọ́n gbà. Ó ní bí ẹni tí wọ́n bá fẹ́ẹ́ tọ́jú bá ṣe pẹ́ sí lọ́dọ̀ wọn ni wọ́n ṣe ń bu owó sísan. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú owó tí wọ́n ń gbà, ó ló ṣeni láànú pé ìyà ni wọ́n fi ń jẹ àwọn àkàndá ẹdá tó nílò ìtọjú.

Alukoro àwọn aláṣẹ iléèwòsàn ọpọlọ Árò náà, Ajíbọ́lá sọ̀rọ̀, ó sọ pé ọ̀rọ̀ abẹ́nú lásán ni; pé ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò kan ará ìta ló ṣẹlẹ̀. Ó ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò tó ohun táwọn akọrọ̀yìn ń gbé jáde rárá, nítorí ohun táwọn ti paná rẹ̀ ni.

Ṣáá, ọ̀gá ọlọ́pàá téṣàn Láfẹ́n̄wá, l’Ábẹ́òkúta, DPO Enatufe Omoh, fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀. Omoh ṣàlàyé pé dókítà kan ṣoṣo ni àwọn àkàndá ẹ̀dá náà gé jẹ, tó sì fara ṣèṣe. Ó ní kò sẹ́ni tó kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, báwọn kan ṣe ń gbé e kiri.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here