Hèèmọ́ nílùú Isẹyin ! Ajínigbé pa ọlọ́dẹ ,wọ́n jí ọ̀gá tó n ṣọ́

Hèèmọ́ nílùú Isẹyin ! Ajínigbé pa ọlọ́dẹ ,wọ́n jí ọ̀gá tó n ṣọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá
Afẹ́fẹ́ tó n dààmú oníkẹtẹpẹ ògì, àfi kí gbogbo oníyẹ̀fun ó má ṣàfira. Àbí bí àwọn ajínigbé bá lè wọnú ilé tí wọ́n ń fi ọdẹ ṣọ́, tí wọ́n sì rí onílé ọ̀hún jí gbé, àfi kí èèyàn tí kò rówó gbọdẹ kún fún ìgbìyànjú àti ádùrá dáadáa pẹ̀lú bí àwọn jàǹdùkú agbébọn ṣe wọlé tọ obìnrin kan lọ, tí wọ́n sì jí í gbé lẹ́yìn tí wọ́n yìnbọn pa ọdẹ tó ń ṣọ́ ilé náà.

Nílùú Iṣẹyin, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti wáyé nígbà tí àwọn aláìláàánú èèyàn ọ̀hún yìnbọn pa ọdẹ tó ń ṣọ ilé, tí wọ́n sì wọnú ilé lọ̀ ọ́ jí obìnrin onílé náà gbé lálẹ́ Ọjọ́bọ, ọjọ́ kẹrìndílógún (16), oṣù Karùn-ún, ọdún 2024 tá a wà yìí.

Obìnrin tí wọ́n jí gbé yìí, Abilékọ Sekinat, ló jẹ́ ìbátan fún Amòfin Àgbà Ahmed Raji tí í ṣe àgbà ọ̀jẹ̀ agbẹjọ́rò nílẹ̀ yìí.

Ọ̀kadà làwọn òbìlẹ̀jẹ́ ẹ̀dá ọ̀hún gùn lọ sílé obìnrin náà, ṣùgbọ́n ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Lexus ni wọ́n fi gbé e lọ síbi tí ẹnikẹ́ni kò tí ì mọ̀ títí tá a fi parí àkójọ ìròyìn yìí.

A gbọ́, pé àwọn agbófinró ti gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, wọ́n sì ti palẹ̀ òkú ọdẹ tí wọ́n yìnbọn pa ọ̀hún mọ́.

Àwọn agbófinró ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí láti gba obìnrin náà sílẹ̀ láàyè lọ́wọ́ àwọn ajínigbé.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here