IDÁN ORÍTA: ÀRÀMÀNDÀ BÍRÍÌJÌ SANWO-OLU TUNTUN NÍ ÌKẸJÀ ṢỌ ARÁ ÈKÓ DI ARÁ OKO

IDÁN ORÍTA: ÀRÀMÀNDÀ BÍRÍÌJÌ SANWO-OLU TUNTUN NÍ ÌKẸJÀ ṢỌ ARÁ ÈKÓ DI ARÁ OKO

Akeem Lasisi

– E tun ka nipa opolopo ona, afara, ile iwosan, ile-iwe, aafin ati bee bee lo ti ijoba Babajide Sanwo-Olu ti se laarin odun kinni isejoba eleekeji rẹ̀

 

Ni agbegbe Ikeja ni Ipinle Eko, orin ti yi, ilu si ti yi pada o.

Paapaa ni opin Awolowo Road si Ikeja Express, eni to ba ti de ibe ti pe, ko kun fun adura ki oun ma sonu ni.

Ki onitohun soji, ko ma sun – gege bi asa ti won maa n da.

Iru eni naa ko gbodo die nu re, ani ki o ma ba a sonu, ki awereko ma lu u ni ilu Ikeja.

Eyi da lori bi biiriji kan ti ijoba Babajide Sanwo-Olu sese ko si ibe se je aramanda.

Afara soji-masun ohun ni won n pe ni Ikeja Overpass, ti won fi sori oko oju irin Red Line.

Ikeja Overpass naa ni won fi ko T, nitori o ya ona ti oko oju irin n gba soto si eyi ti awon moto n gba.

Lai paro rara, opo eniyan to je ara Eko ni biriiji kasiara naa n so di ara oko.

Ti eniyan ba ba ti de adugbo naa tipe, to ba wa sako, ti ko tete beere ona, to ni oun ko sese de Eko, oun kii se ara oke ni Ikeja, onitohun a da ara re lebi.

Idi ni pe awon ona keekee kan ti eniyan maa n ba jade ni agbegbe Ijoba Ibile Ikeja Local Government Area ni biriiji gbankogbi naa ti yi kadara won pada.

Lati jade si ona Iyana-Ipaja tabi Agege bayii, a ni lati gun afara agbayanu yii, yato si yiya bara si awon koro-koro ti a n to nigba kan.

Sugbon ti oju awako ati awon arinse ba ti wa da si idan ti biriiji yii je, fanda-fanda ni oluware yoo maa yan, ti okan re yoo si maa kan saara si Sanwo-Olu.

Ki a ma paro, ka ma se’ke, afara Ikeja Overpass nla yii je okan pato ninu opo aseyori malegbagbe gomina naa.

Sibesibe, ti a ba n wo itesiwaju to ti ba Eko laarin odun kan seyin ti Sanwo-Olu bere isejoba eleekeji re, a yoo ri i pe kii se keremi.

Bi o se n se oniruuru ona lo n se afara moto ati ti elese.

Niwon igba to wa je pe arise ni arika, ti arika je baba iregun, ijoba naa ti so pe ti a ba ka a ni meni, meji, ona eedegberin o le meji (172) ni oun ti pari laarin odun kan seyin o, ti eyi si ja si ona kilomita to le ni 177.

O wa fi kun un pe, pelu aijafira, ise n lo lowo lori ona to je igba o le ni aadota ati meta – 253.

Bi awon yii se n lo lowo naa ni ise afara to maa n gbon owo julo ko duro.

Oludamoran Pataki lori oro Ohum Amudagbasoke ba Ilu (Special Adviser on Infrastructure), Alagba Olufemi Daramola, lo so eyi di mimo lojo Jimoo, ojo keta osu karun-un odun yii.

O se alaye naa lasiko to n ba awon oniroyin soro lori aseyori Ijoba Sanwo-Olu pelu Igbakeji re, Dokita Obafemi Hamzat.

Pelu idunnu ati ifowosoya ni Daramola se ran awon ara ilu leti pe ise si n lo ni pereu lori awon akanse ise miiran, to si mu u da won loju pe, laipe lai jinna, Sanwo-Olu yoo se awon ise naa ni asepe.

Lara awon wonyi ni afara ti yoo so Ojota ati Opebi po (Opebi-Link Road); ti Abiola-Onijemo Link Road, ti yoo so College Road ati awon adugbo bii Ajayi Street, Ogba po mo Aruna/Obawole/Iju-Ishaga ni Ifako-Ijaiye.

Olubadamoran Pataki naa fi kun un pe lara awon ise pataki to tun n lo lowo ni ona Babafemi Dada (onibiriiji) lo si Yinka Folarin-Jamiu Lawal-Shalom Academy Road ni Ijoba Ibile Alimosho; ati awon pataki miran bee ni agbegbe LASU, Iba, Baruwa, Amuwo Odofin, Popona Badagry, Mazamaza, Eti-Osa ati Epe Alaro, Omo Ogunmodede.

Ko tan sibe o. Daramola so pe ise si n lo witiwiti lori atunko osibitu awon omode Massey Street Children’s Hospital, eyi ti yoo ni beedi ogojo o din mewaa (150) ati

ile iwosan gbogbo gboo nla ti General Hospital, Ojo.

Ijoba tun n ba ise lo ni pereu lori kiko ile ise panapana ti Kosofe ati Ijede Fire Stations; ile awon akekoo ti Students’ Union Arcade ni Ojo; kiko abala ikawe Faculty of Management Sciences Complex Phase 1, ile ikawe ti Central Library Phase 2A, atunko ilegbee awon akekoo ti Nigerian Law School Hostel, Lagos Campus to fi mo atunko alasodoge enu abawole ifafiti nla ti Eko, iyen Remodelling of the University of Lagos Main Gate.

Daramola tun menuba ise to n lo kaakiri LASU Business School, LASUSTECH, ati ni Alausa pelu Onikan.

Ohun nla kan ti yoo tun mu inu awon omo Eko dun gidi ni bi ijoba Sanwo-Olu se n so ilu di tuntun ni awon ibi pataki kan. Lara awon yii ni isodoge aafin Oba Ilu Eko – Renovation of Iga Iduganran – ati kiko amusapejuwe aafin Oba Badagry iyen Prototype Oba’s Palace, ni Badagry, nibi ti Sanwo-Olu tun ti n ba ise lo laiweyin lori kiko ile igbafe oniyara meji le laadota 52-Bedroom Hotel ati ibudo awon eniyan pataki-pataki ti VIP Chalets, ni Badagry bakan naa.

 

 

 

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here