Afurasí tó máa ń jí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ nílé ìjọsìn kó sí gbaga ọlọ́pàá Ekiti

Afurasí tó máa ń jí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ nílé ìjọsìn kó sí gbaga ọlọ́pàá Ekiti

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọjọ́ gbogbo ni ti olè,ọjọ́ kan ni ti olóhun.
Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkìtì ti tẹ ọkùnrin kan tó máa ń jí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì lásìkò ìjọsìn.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Sunday Abutu ló fi ọ̀rọ̀ náà léde nínú àtẹ̀jáde kan tó fi ṣọwọ́ sí àwọn akọ̀ròyìn.

Abutu sọ pé ọwọ́ tẹ afurasí náà lẹ́yìn tó ti jí fóònù méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ijọ Christ Apostolic Church kan ní Ayegbaju-Ekiti.
Ọlọ́pàá ní “afurasí náà lọ sílé ìjọsìn ọ̀hún, ó díbọ́n bíi ọ̀kan lára àwọn olùjọ́sìn láti ṣọ́ àwọn olùjọ́sìn ọ̀hún dáadáa kó tó jí fóònù méje lasiko ti wṣn n kọ orin ìyìn.

“ Afurasí ọhun jẹ́wọ́ nínú ifọrọwanilẹnuwo pé ó ti ṣe díẹ̀ tí òun ti ń ṣọṣẹ lagbegtbe Oye àti Ayegbaju-Ekiti, ilé ìjọsìn sì lóun máa kọlù.

“ Ó jẹ́wọ́ síwájú sí pé òun ti jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ nílé ìjọsìn Redeemed Christian Church of God àti New Reality Christian Center, nílùú Oye-Ekiti yìí kan náà .”

Ìwádìí ọlọ́pàá fi hàn pé ìlú Èkó ni afurasí náà máa ń fi àwọn ẹ̀rọ ìléwọ́ tó bá jí ránṣẹ́ sí níbi tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan yóò ti lu àwọn fóònù náà ní gbànjo, tí yóò sì fi owó rẹ̀ ránṣẹ́ padà sí lórí ayélujára.

Ẹ̀wẹ̀, ọlọ́pàá ti gba àwọn fóònù méje tó jí gbẹ̀yìn lọ́wọ́ rẹ̀, wọ́n sì ti késí àwọn tó ni àwọn fóònù náà kí wọn wá gbà á.

Abutu parí àtẹ̀jáde rẹ̀ pé afurasí náà yóò fojú balé ẹjọ́ láìpẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti parí ìwádìí lórí ẹsùn tí wọ́n fi kàn án.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here