Ìkànnì Wásaàpù ni Gómìnà Kwara ti ń pàṣẹ ìlú lásìkò yìí -PDP
Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP), ní ìpínlẹ̀ Kwara, ti fẹsùn kan Gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Abdulrahman Abdulrazaq, pé ṣe ló ń ṣe ìjọba Kwara nípasẹ̀ lílo àtẹ̀jíṣẹ orí ayélujára Wásaàpù, tó sì pa gbogbo àwọn iṣẹ́ àkànṣe òpópónà tó ń ṣe lọwọ́ ti gẹ́gẹ́ bíi aṣọ tó ti gbó.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí Akọ̀wé tó ń gbé ìròyìn ẹgbẹ́ náà jáde, Ọ̀gbẹ́ni Oluṣẹgun Adewara, fi síta tó tẹ akọ̀ròyìn lọ́wọ́ lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 yìí, ló ti ní kí Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq, lórí bó ṣe pa gbogbo àwọn iṣẹ́ àkànṣe òpópónà tó ń lọ ní ìpínlẹ̀ náà ti, tó sì ń bá ohun ti kò kàn án lọ́wọ́-lẹ́ṣẹ̀ kiri, pàápàá nípa òpópónà tó ń lọ lọ́wọ́ ní Èkó àti Calabar, tó pa àwọn èèyàn Kwara tó dìbò fún un tì.
Ó tẹ̀síwájú pé ohun ìyàlẹ́nu ni ọ̀rọ̀ náà jẹ́ fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, pẹ̀lú bí ọ̀rọ̀ ìpínlẹ̀ Kwara kò ṣe jẹ Gómìnà lógún mọ́, tó sì jẹ́ pé iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ ló ń wà mọ́yà kiri.
Ó ni, “ Gómìnà wa ti kó lọ sí ìlú Àbújá tipẹ́, tó sì ń ṣe ìjọba Kwara látorí àtẹ̀jíṣẹ́ lórí Wásaàpù, tí yóò sì máa ya àwọn ayédèrú fọ́tò nígbàkúùgbà tó bá wá sílé.
“ Eléyìí kò lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà mọ́ rárá, nítorí pé Abdulrasaq ti sọ ìpínlẹ̀ Kwara di akúrẹtẹ̀ níbi tí kò ti sí ètò ààbò mọ́, tí ìjínigbé ń peléke sí i lójoojúmọ́. Bákan ni ẹ̀ka ètò ìlera àti ètò ẹ̀kọ́ ti dẹnukọlẹ̀, táwọn akẹ́ẹ̀kọ́ sì ń kẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ igi gẹ́gẹ́ bí ìròyìn se gbé nípa ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Kánkán LGEA, tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Asà, ní ìpínlẹ̀ náà.
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti wáá késí Gómìnà Abdulrasaq, kó tètè padà wálé láti ìlú Àbújá tó lọ̀ọ́ jókòó sí, kó wáá lo gbogbo agbára rẹ̀ fún ìdàgbàsókè àti ìgbáyé-gbádùn àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Kwara, kó sì lo ànfààní Alága ìgbìmọ̀ Gómìnà tó jẹ́ láti fi kóre wálé.