Bí Ọba Agbábìàká Ọsọ́lọ̀ ti ìlú Ìsọlọ̀ l’Ékòó se papòdà
Ọlámídé Motúnráyọ̀
Kábíyèsí Ọba Kàbírù Agbábíàká, Ọsọ́lọ̀ ti ìlú Ìsọlọ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ Ìsọlọ̀ ní ìpínlẹ̀ Èkó ti jáde láyé; lẹ́yìn ádùrá ìtúnu ààwẹ̀ ní Ọjọ́rú nílùú Èkó.
Ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ni Kábíyèsí Agbábíàká í ṣe kí ó tó jáde láyé. Ìwádìí fi yé wa pé Ọba Ọsọ́lọ̀ tó wàjà yìí jẹ́ ọba alayé tí kì í ṣe aládàníkànjọpọ́n, tí ó ṣì fi ayé rẹ̀ sin ìlú Ìsọlọ̀ àti ìpínlẹ̀ Èkó títí tí ọlọ́jọ́ fi dé. Ọba Agbábíàká ti fi ipa rere lélẹ̀ léyì táwọn èèyàn kò le gbàgbé láéláé.
Alága ìjọba ìbílẹ̀ Ìsọlọ̀, Họnọrebu Ọlásojú Adébáyọ̀ ló fìdí ìṣẹlẹ̀ yìí múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta. Ó sọ pé “Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó Babájídé Sanwó-Olú ló fún òun láṣẹ láti kéde ìpapòdà Ọba Ìsọlọ̀, Kábíyèsí Kàbírù
Àlàní Adélàjà Agbábíàká Adéọlá Olúṣi Kẹta lọ́jọ́ kẹwàá oṣù Kẹrin ọdún 2024 yìí”.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Babájídé Sanwó-Olú ń ṣèdárò Ọba Agbábíàká tó wàjà lọ́jọ́ ọdún ìtúnu ààwẹ̀. Sanwó-Olú sọ pé ”pẹ̀lú ìbànújẹ ọkàn ni òun fi gba ìròyìn ìpapòdà Ọsọ́lọ̀ ti ìlú Ìsọlọ̀.
Gómìnà Sanwó-Olú kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́ àti àwọn èèyàn Ìsọlọ̀ lórí ìpapòdà Ọba Agbábíàká. Kí Elédùà tẹ́ ẹ sí afẹ́fẹ́ rere, kí orúkọ rere tí ó fi sílẹ̀ má bàjẹ́ láéláé.”