Sunday Igboho, èmi ò mọ nǹkankan nípa ajìjàgbara Oòduà Nation tó kọlu ilé aṣòfin n’Íbàdàn o –
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ajìjàgbara fún òmìnira ilẹ̀ Yorùbá, ìyẹn Yorùbá Nation, Olóyè Sunday ‘Igboho’ Adeyemo ti sọ pé òun kò mọwọ́mẹsẹ̀ nínú rògbòdìyàn tí àwọn ajìjàgbara kan fa nílùú Ìbàdàn láàrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta.
Igboho ló sọ ọ̀rọ̀ náà nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde lójú òpó Sítágírámù rẹ̀.
Ó ní òun kò lọ́wọ́ nínú ìkọlù náà, bẹ́ẹ̀ làwọn ajìjàgbara ẹgbẹ́ òun kò ní dá irúfẹ́ nǹkan bẹ́ẹ̀ láṣá láíláí.
Igboho sọ pé “Ó ti tó mi létí pé àwọn kan tí wọ́n pe ara wọn ní ajìjàgbara Oòduà Nation gbìyànjú láti já ọọ́fìsì Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gbà.
“Yóó sì wù mí láti sọ ọ́ di mímọ̀ pé mi ò lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà rárá.
“Àti pé, kò sí ọmọ ẹgbẹ́ Odùduwà Nation kankan tí yóó jẹ́ dán irúfẹ́ nǹkan bẹ́ẹ̀ wò.
“Mo rọ ìjọba láti ṣè ìwádìí fínífíní lórí ọ̀rọ̀ náà kò sì fi ojú àwọn aṣebi àti abani lórúkọjẹ́ náà léde.”
Ṣaájú láàárọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta ni àwọn èèyàn kan ti kọ́kọ́ kọlu ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà, tí wọ́n sì gbìyànjú láti gba ibẹ̀ kí àwọn agbófinró tó ṣí wọn lọ́wọ́ iṣẹ́.
A gbọ́ pé àwọn èèyàn náà yọ àsìá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó wà nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà kúrò tí wọ́n sì fi àsìá Oòduà Nation síbẹ̀ .
Wàyí ò, ọwọ́ àwọn agbófinró ti tẹ díẹ̀ lára àwọn èèyàn tí wọ́n fura sí pé wọ́n dá rúgúdù náà sílẹ̀.