Ajìjàgbara Òduà Nation pẹ̀lú ohun ìjà olóró ya wọ ọgbà ọ́fìsì Gómìnà Ọ̀yọ́

Ajìjàgbara Òduà Nation pẹ̀lú ohun ìjà olóró ya wọ ọgbà ọ́fìsì Gómìnà Ọ̀yọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Sátidé ni àwọn èèyàn kan tí wọ́n furasí pé wọ́n jẹ́ ọmọ lẹ́yìn ẹgbẹ́ ajìjàgbara Odua Nation yawọ inú ọgbà ọ́fìsì Gómìnà Ọ̀yọ́ tó wà nílùú Ìbàdàn tó jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ náà.

Oun tí akọ̀ròyìn Òwúrọ̀ gbọ́ ni pé àwọn ajìjàgbara náà yawọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Ọ̀yọ́, tí wọ́n sì pààrọ̀ àsìá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pẹ̀lú ti Òduà Nation kí àwọn ọmọ ológun tó dé sí ibẹ̀.

Nínú fọ́nrán tó tẹ akọ̀ròyìn Òwúrọ̀ lọ́wọ́, àwọn ajìjàgbara náà ni wọ́n wọ aṣọ ológun lásìkò tí ọwọ́ tẹ̀ wọ́n.

Bákan náà ní fọ́nrán ọ̀hún tún ṣàfihàn bí ọwọ́ Ilé iṣẹ Ọlọ́pàá ṣe tẹ̀ wọ́n, tí wọ́n sì dá wọn dùbúlẹ̀ nínú ọgbà náà.

Nígbà tó ń fi di ìròyìn náà múlẹ̀, Olùdámọ̀ràn sí Gómìnà lórí ètò ààbò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Fatai Owoseni Rtd ní ọwọ́ ti tẹ afurasí mẹ́rìndínlógún lára àwọn afurasí náà.

Bákan náà O lùdámọ̀ràn sí Gómìnà lórí ìròyìn, Abosede Sodiq náà fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún múlẹ̀, ó ní bí wọ́n se yawọ inú ọgbà ọ́fìsì Gómìnà ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní yìn ìbọn sókè.

Ó ni ọwọ́ àwọn agbófinró ti tẹ púpọ̀ àwọn afurasí ọ̀hún.

“A ti ké sí àwọn aráàlú nítorí àwọn èèyàn yìí ní wọ́n múra nínú aṣọ ológun, pé kí wọ́n fura sí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ .”

Ní báyìí, ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀sọ́ aláàbò, láti olú Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá, ilé iṣẹ́ ológun ati àwọn Àmọ̀tẹ́kùn ló ti wà káàkiri agbègbè náà láti ri pé àlàáfíà jọba.

Bákan náà ni wọ́n ti gbé igi dínà àwọn ojú ọnà kan, tí wọ́n sì rọ àwọn aráàlú láti má gba agbègbè tí wọ́n gbé igi dá náà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here