Ẹgbẹ́ òṣèré fòfin dé àwọn kan lẹ́yìn ikú Junior Pope
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn òṣèré ìyẹn Actors Guild of Nigeria (AGN), Emeka Rollas Ejezie ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òṣèré tíátà Obumneme Odonwodo tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Junior Pope ti jáde láyé.
Rollas fìdí ìpapòdà Junior Pope múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí Facebook lọ́jọ́rú, ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kẹrin.
Ṣáájú ni Rollas ti kọ́kọ́ kéde pé Junior Pope ṣì wà láyé lẹ́yìn tí ìròyìn ikú rẹ̀ gba orí ayélujára.
“Kò sí ohun tí Ọlọ́run kò lè ṣe. Junior Pope wà láyé. Ó ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn,” Rollas kọ sí ojú òpó ayélujára rẹ̀.
Àmọ́ nínú àtẹ̀jáde tuntun tó fi sórí Facebook, Rollas ní ìdùnnú tó wọ òun lẹ́wù nígbà tí Junior Pope gbé apá ló jẹ́ kí òun fi ìkéde náà síta.
Ó ní ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún àwọn pé ayọ̀ àwọn kò pé tí àwọn tún fi gba ìròyìn ìbànújẹ́ mìíràn.
“Ìdùnnú ló mú mi kọ́kọ́ fi ìkéde mi síta nígbà tó mi ọwọ́. Ilé ìwòsàn méjì ni wọ́n ti gbìyànjú láti jí Junior Pope àmọ́ pàbó ló já sí.”
“A ti padà pàdánù rẹ̀.”
Ó ṣàlàyé pé àwọn ti rí òkú ọ̀gbẹ́ni Friday àmọ́ àwọn ṣì ń wá àwọn èèyàn mẹ́ta mìíràn.
Ṣáájú ni ìròyìn ti gba orí ayélujára pé ọkọ̀ ojú omi tí Junior Pope wọ̀ rì sínú odò River Niger nígbà tí òun àtàwọn míì ń bọ̀ láti oko eré.
Lẹ́yìn náà ni ìròyìn míì tún gba orí ayélujára pé nígbà tí wọ́n gbé Junior Pope mọ́ṣúárì ni àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ ní ẹ̀mí ṣì wà lára Junior Pope.
Yàtọ̀ sí Junior Pope, àwọn òṣìṣẹ́ mẹ́rin ló pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàm̀bá náà, tí wọ́n sì ti rí òkú èèyàn kan láàárín wọn.
Ẹgbẹ́ AGN gbé ìgbésẹ̀
Ẹgbẹ́ àwọn òṣèré, AGN ní àwọn ti fòfin dè ṣíṣe eré ní etí odò tàbí lórí omi látara ìjàm̀bá tó wáyé náà.
Bákan náà ni wọ́n sọ pé kí wọ́n má ya eré fíìmù kankan ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kẹrin láti fi ṣẹ̀yẹ ìkẹyìn fún àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn.
AGN ní àwọn ti fòfin dè fíìmù “Another Side of Life”. Fíìmù yìí ni Junior Pope àtàwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ lọ yá ní ìpínlẹ̀ Delta kí wọ́n tó ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ wọn.
Àtẹ̀jáde tí ẹgbẹ́ fi léde tún fi kún pé òṣèré kankan kò gbọdọ̀ bá Adamma Luke ṣiṣẹ́ títí di ìgbà kan ná. Adamma Luke ni ó ni eré tí àwọn Junior Pope lọ ṣe.
Wọ́n gbàdúrà kí Ọlọ́run tẹ́ àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn sí afẹ́fẹ́ rere bí wọ́n ṣe ń wá òkú àwọn tó ṣì nínú odò tí wọ́n rì sí.
Ní ọjọ́ tí ìjàm̀bá okọ̀ ojú omi náà wáyé ni Junior Pope fi fídíò kan sórí ayélujára nípa bí àwọn òṣèré ṣe máa ń fi ẹ̀mí ara wọn wéwu láti wá oúnjẹ oòjọ́ wọn.
Fídíò náà ń ṣàfihàn bí Junior Pope àtàwọn yòókù rẹ̀ ṣe wà nínú ọkọ̀ ojú omi lórí odò River Niger láì wọ aṣọ ààbò.
Ó ń sọ nínú fídíò náà pé òun ní ọmọ mẹ́ta, òun sì ni yóò tọ́jú wọn, tí òun máa rè wọ́n dàgbà.
Níbẹ̀ ló ti ń bẹ awakọ̀ ojú omi náà pé kó ṣe jẹ́jẹ́ nítorí òun nìkan ni àwọn òbí òun bí.