Makinde gbarata pé òṣìṣẹ́ wọléwọ̀de lu àwọn ẹ̀ṣọ́ ojú pópó Ọ̀yọ́ ní àlùbami

Makinde gbarata pé òṣìṣẹ́ wọléwọ̀de lu àwọn ẹ̀ṣọ́ ojú pópó Ọ̀yọ́ ní àlùbami

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti bu ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn òṣìṣẹ́ iléeẹẹ́ tó ń rí sí ètò ìwọlé àti ìjáde ní Nàìjíríà ìyẹn National Imigration Service tẹ̀ka Zone F ṣe ṣèkọlù sí òṣìṣẹ́ tó ń mójútó ètò ìrìnnà ojú pópó ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (OYRTMA).

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde tó korò ojú sí ìkọlù náà ní yóò bá agbẹjọ́rò àgbà ìpínlẹ̀ náà sọ̀rọ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ tako àwọn tó ṣe ìkọlù sí òṣìṣẹ́ náà.

Makinde ní òun máa ri dájú pé àwọn gbé ìgbésẹ̀ òfin láti fi rí ìdájọ́ òdodo gbà.

Ṣáájú ni ìròyìn gbòde pé àwọn òṣìṣẹ́ Immigration kan ni wọ́n fìyà àìtọ́ jẹ àwọn òṣìṣẹ́ àjọ OYRTMA nítorí tí wọ́n dáwọn dúró nígbà tí wọ́n gba ọ̀nà tí kò tọ́.
Ní agbègbè afárá Onipepeye Bridge Underpass lọ́nà Old Ife Road, Ibadan ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, tí àwọn òṣìṣẹ́ Immigration ọ̀hún lu àwọn òṣìṣẹ́ OYRTMA bí ejò àìjẹ látàrí pé wọ́n fi kélé òfin gbé wọn.

Gómìnà Makinde, nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sáwọn òṣìṣẹ́ OYRTMA tí wọ́n fìyà jẹ náà lọ́jọ́ Ajé ní ìwà àìtọ́ ni àwọn òṣìṣẹ́ Immigration náà hù àti pé àwọn kò ní fi àyè gba irú rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ rárá.

Ó ní ohun tí òun fẹ́ kí wọ́n mọ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fún ni bíbọ̀wọ̀ fún òfin àti ìlànà, títẹ̀lé òfin ìrìnnà láì ipò tàbí ọlá ṣe.

Ó ní kò sí ẹni tó kọjá òfin àti pé ìjọba má gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ lórí ìkọlù náà.

Ó fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé jíjẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ kò túmọ̀ sí pé kò yẹ kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún òfin tàbí ga ju àwọn ènìyàn yòókù lọ láwùjọ.

“A máa kọ̀wé ránṣẹ́ Sáwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ Immigration nítorí a kò lè gba èyí ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.”

Makinde tún ṣe àbẹ̀wò sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ Immigration ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó wà ní Agodi Gate, Ibadan níbi tó ti bá ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ náà látu ri dájú ìbáṣepọ̀ tó lóòrìn wà láàárín àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò gbogbo ní ìpínlẹ̀ náà.

Ó sọ fún ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ náà, Abdurasheed Ademola pé kí wọ́n ri dájú àwọn òsìṣẹ́ tó ṣe ìkọlù náà fojú winá òfin àti pé irúfẹ́ ìkọlù bẹ́ẹ̀ kò wáyé lọ́jọ́ iwájú.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here