’Ẹ ò lẹ́tọ̀ọ́ àti yẹ fóònù aráàlú wò lójú òpópónà’’ –Ọ̀gá Ọ̀lọ́pàá

‘’Ẹ ò lẹ́tọ̀ọ́ àti yẹ fóònù aráàlú wò lójú òpópónà’’ –Ọ̀gá Ọ̀lọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní kokoko là á ránfá adití, Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ilẹ̀ wa, ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Edo, ti ṣe é léèwọ̀ fáwọn agbófinró wọn láti máa yẹ fóònù aráàlú wò, pàápàá jù lọ àwọn ọlọ́pàá tó ń dúró nírònà láti yẹ mọ́tò àti èrò tó ń lọ wò, àtàwọn tó ń ṣe pàtúróòlù kiri ìgboro.
Lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ karùn-ún, oṣù Kẹrin, ọdún yìí, ni SP Chidi Nwabuzor, tí í ṣe alukooro ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ náà fi àtẹ̀jáde yìí síta lórúkọ kọmíṣánnà ìpínlẹ̀ Edo.

kọmíṣánnà ìpínlẹ̀ Edo, CP Funshọ Adegboye, ni Nwabuzor ṣàlàyé pé ó ti gba àwọn agbófinró ìpínlẹ̀ náà níyànjú láti má ṣe gbìdánwò pé won yóò máa tú fóònù onífóònù wò gẹ́gẹ́ bíi àṣẹ tó ti òkè, láti ọ̀dọ̀ ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá, IGP Kayọde Ẹgbẹtokun, wá.

Nínú àtẹ̀jáde ọ̀hún ló ti ní, “Kọmíṣánnà ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Edo, CP Funshọ Adegboye, ti tún mẹ́nuba àṣẹ tí ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá nílẹ̀ Nàìjíríà, IGP Kayọde Ẹgbẹtokun, pa lórí bí wọ́n ṣe fòfin de títú fóònù aráàlú wò láì jẹ́ pé ilé-ẹjọ́ pa á láṣẹ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ látàrí ìwádìí ”.

Nwabuzor ní ìkìlọ̀ ńlá ni Kọmíṣánnà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Edo ṣe fáwọn ọmọ abẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe pa gbogbo ọ̀gá ọlọ́pàá agbègbè àti ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan láṣẹ láti òkè wá, àti pé èyíkéyìí nínú wọn tí kò bá dẹ̀yìn nínú ìwà tí kò bófin iṣẹ́ yìí mu yóò dá ara rẹ̀ lẹ́bi.

Tẹ́ ò bá gbàgbé, ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ níyì tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá yóó máa pé aráàlú sí àkíyèsí pé ọlọ́pàá kankan kò lẹ́tọ̀ọ́ láti dá wọn dúró nírònà láti máa yẹ fóònù wọn wò.

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ti kìlọ fáwọn agbófinró náà láìmọye ìgbà pé dúkìá àdáni èèyàn ni fóònù, wọ́n kò sì lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàdédé dá èèyàn dúró kí wọ́n máa tú gbogbo orí fóònù wọn wò. Ọlọ́pàá tó bá dá a làṣà tí ọwọ́ bá tẹ ẹ, ìyá tó tọ ni yóó jẹ́ labẹ òfin.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here