Àṣírí tú! Ọwọ́ tẹ ayédèrú EFCC, aráàlú ló n lù ní jìbìtì n’Ìlọrin

Àṣírí tú! Ọwọ́ tẹ ayédèrú EFCC, aráàlú ló n lù ní jìbìtì n’Ìlọrin

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹni bá ṣe n tẹ́nìkan ò ṣe rí, ojú rẹ̀ yóó rí n tẹ́nìkan ò rí rí.
Akóló àjọ tó ń gbogun ti iwa ìbajẹ àti ṣiṣe owo ilu mọ́ku-mọ̀ku nílẹ̀ wa, ‘Economic And Financial Crimes Commision’ (EFCC), ẹ̀ka tìlú Ìlọrin, ni afurasí kan, Akọgun Rasheed Usman, wà báyìí. Ẹ̀sùn lílu àwọ aráàlú ní jìbìtì pẹ̀lú ìlérí pé òun yóó bá wọn gba béèlì àwọn ọmọ Yahoo méjì tó wà láhàámọ́ EFCC, tó sì n pe ara rẹ̀ ní ojúlówó òṣìṣẹ́ EFCC ni wọ́n torí ẹ̀ mú un. Ìwà tó hù yìí ni wọ́n ló ta ko ìwé òfin ilẹ̀ wa.

Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹrin, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 yìí, ni ọwọ́ EFCC tẹ Usman, lórí ẹsùn jiìbìtì lílù tí wọ́n fi kàn án ọ̀hún.

Oun tí a gbọ́ ni pé ọmọkùnrin tó ń gbé nílùú Babanla, níjọba ìbílẹ̀ Ìfẹ́lódùn, ní ìpínlẹ̀ Kwara, yìí ló ń pe ara rẹ̀ ní ojúlówó EFCC, tó sì gba ẹgbẹrun lọnà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Náírà (500,000), lọ́wọ́ obìnrin kan, Khadizah Abdul,

gẹ́gẹ́ bíi owó tí yóò fi gba béèlì àwọn ọmọ ìyá náà méjì tó wà lákàtà àjọ ọ̀hún, èyí tí wọ́n fẹ̀sùn lílu jìbìtì lórí ayélujára kàn sílẹ̀, kó tóó di pé ọwọ́ tẹ̀ ẹ́ báyìí.

Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí Usman gbowó náà tán lọ́wọ́ ìyá wọn ni kò rí àwọn ọmọ náà tú sílẹ̀, tó sì tún ń bèèrè fún ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba Náírà gẹ́gẹ́ bíi àfikún owó tó ti gbà tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ Khadizah, lẹ́yìn-ò-rẹyìn ni àṣírí ọ̀rọ̀ náà padà tú pé ayédèrú EFCC ni. Iléèwòsàn Jẹ́nẹ́rà ìlú Ìlọrin, tó wà lágbègbè Taiwo-Òkè, ni ọwọ́ ti tẹ̀ .

Bákan náà ni wọ́n ló tún ń parọ́ pé òṣìṣẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ olùkọ́ni àgbà nílùú Òró, ní ìpínlẹ̀ Kwara, Kwara State College of Education), lòun.

Àjọ náàa ní lẹ́yìn táwọn bá parí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwádìí làwọn yóò fojú Usman ba ilé-ẹjọ́.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here