Ọlákùlẹ́hìn! Olúbàdàn tuntun yọjú kúlẹ́, àìlera Ọ̀ba kìí ṣe t’ọlọ́jọ́–Aṣípa

Ọlákùlẹ́hìn! Olúbàdàn tuntun yọjú kúlẹ́, àìlera Ọ̀ba kìí ṣe t’ọlọ́jọ́–Aṣípa

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní a kìí mọ ìyá
Ọṣọ́ ju Ọṣọ́ ,nífèsì ọ̀rọ̀ Aṣípa ilẹ̀ Ìbàdàn lórí ipò ìlera Ọba Ọlákùlẹ́hìn Owólabí,a jẹ́ pé ó ṣeéṣé kí ètò ìgbéṣẹ̀ yíyan Olúbàdàn tuntun ó yá báyìí, bí Àgbà oyè tí ipò Olúbàdàn ti ilẹ̀ Ìbàdàn sún kàn, Ọba Ọlákùlẹ́hìn Owólabí ti ṣe ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú díẹ̀ lára àwọn Ọba ìlú Ìbàdàn .

Lára àwọn Ọba tó ṣèpàdé pọ̀ pẹ̀lú Ọba Ọlákùlẹ́hìn Owólabí ni Òsì Olúbàdàn, Ọba Eddy Oyewole, Osi Balógun Olúbàdàn, Ọba Lateef Adebimpe, Ashipa Olúbàdàn, Abiodun Kola-Daisi; Asipa Balógun Olúbàdàn àti Ọba Kola Adegbola.

Nígbà tí ó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, Òsì Balógun Olúbàdàn, Ọba lateef Adebimpe ní, “ ó ti pẹ́ tó ti rẹ bàbá wa nípa ọ̀rọ̀ ogbó, ìyẹn ni kò
jẹ́ kí wọ́n lè bá wa ṣe ìpàdé pọ̀ .”

Oba lateef tẹ̀síwájú pé “ìgbà tí ati rí wọn ti pẹ, ó sì di dandan ká ṣe gbogbo ìpalẹmọ ìwúyè wọn, ẹni tí a ó ṣe ìwúyè fún, a gbọdọ̀ ríi, ìyẹn ló gbé wa wá.

“A sì rí pé ara Ọba Ọlákùlẹ́hìn Owólabí dá pérépéré .”

Òsì Balógun Olúbàdàn tẹ̀síwájú pé ètò ti tò láti gbà ìlú kí ètò ìwúyè Olúbàdàn titun sì bẹ̀rẹ̀.

Ìpàdé yìí ni yóó jẹ ìpàdé ìkejì tí Ọba Owólabí Ọlákùlẹ́hìn yóò ṣe pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ Olúbàdàn tí ilẹ̀ Ibaydan lẹyìn tí Ọba Mahood Lekan Balógun papòdà.

Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, Ọba Ọlákùlẹ́hìn kò tí ì fojú kan ẹnìkan kan láti ìgbà tí Ọba Mahood Lekan Balógun, tó tún jẹ́ Olúbàdàn kejìlélógójì ti papòdà.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì ló ń fojú sọ́nà láti rí Ọba Owólabí Ọlákùlẹ́hìn níta gbangba.

Ìgbésẹ̀ yìí sì ni yóó fòpin sí ọ̀pọ̀ àhesọ ọ̀rọ̀ tó ti n wáyé lórí ìyànsípò àgbà oyè náà sí ipò Olúbàdàn tilẹ̀ Ìbàdàn.
Bí ìgbẹ́sẹ̀ yíyàn Olúbàdàn tuntun bá ṣe jẹ́, Ìròyìn Òwúrọ̀ kò ní-ín jẹ́ kétí ẹ̀yin aráàlú ó di síi.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here