Agbófinró!, ọwọ́ òfin ni ẹ fi mú àwọn tó tún fẹ́ koná ogun láàrin Ifẹ̀ àti Mọdákẹ́kẹ́ -IPDM

Agbófinró!, ọwọ́ òfin ni ẹ fi mú àwọn tó tún fẹ́ koná ogun láàrin Ifẹ̀ àti Mọdákẹ́kẹ́ -IPDM

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní olójú ò ní-ín lajú ẹ̀ sílẹ̀,kí tàlùbọ̀ ó yí wọ̀ọ́,èyí ló mú bí ẹgbẹ́ kan tó jẹ ti àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ọmọ bíbí ìlú Iléefẹ̀ àti Mọdákẹ́kẹ́, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ifeland Peace & Development Movement (IPDM), ti bu ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn adàlúrú kan ṣe ṣekú pa àwọn àgbẹ̀ láàrin ìlú méjèèjì ní kòpẹ́kòpẹ́ yìí.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ náà, Sọji Awogbade àti Akọ̀wé wọn, Adedayọ Ojo, fi síta ni wọ́n tí sọ pé ṣe làwọn èèyàn ọhún ya wọ abúlé Tòrò, Abà Páànù àti Wánísanni, tí wọ́n sì pa àwọn àgbẹ̀ níbẹ̀ láì ṣẹ̀ wọ́n lẹ́ṣẹ̀ kankan.

Wọ́n ní nínú ìwádìí àwọn ló tún fi di mímọ̀ pé kò sí ìlú kankan láàrin Ifẹ àti Mọdakẹkẹ tó rán àwọn adàlúrú náà niṣẹ, ìwà búburú inú ara wọn ni wọ́n gbé jáde láti fi da omi àlàáfíà ìlú méjèèjì rú.

IPDM sọ síwájú pé ohun kan ṣoṣo tó lè wá ojútùú sí ìwà ọ̀daràn náà ni kí àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò ṣe ojúṣe wọn nípa ṣíṣàwárí àwọn tí wọn ń jẹ nídìí mọ̀dàrú yìí, kí wọn sì fojú wọn bá ilé-ẹjọ́ fún ìjìyà tó tọ́ sí wọn láì fi ti ipò tàbí ẹni tí wọ́n jẹ́ láàrín ìlú ṣe rárá.

Ẹgbẹ́ náà ké sí àwọn alákòóso Ìfẹ Development Board, (IDB) àti Modákéké Progressive Union, (MPU), láti bẹ̀rẹ̀ sí í bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà ọ̀daràn tí àwọn mọ̀dàrú náà ń hù, kí wọ́n sì máa kéde àlàáfíà fún àwọn ọmọ ìlú wọn, nítorí nínú àlàáfíà nìkan ni ìgbé ayé ìrọ̀rùn wà.

Ṣaájú ni alága ẹgbẹ́ kan nílùú Ileefẹ, ‘Ifẹ Intellectuals’, Ọmọọba Ademuyiwa Adeniran, ti fẹ̀sùn kan àwọn ará Mọdákẹ́kẹ́ pé wọ́n ti fi agbára gba abúlé bíi ọgọ́rùn-ún lọ́wọ́ àwọn.

Ó ní bí wọ́n ṣe ń pa àwọn èèyàn àwọn ní wọ́n ń jí wọn gbé, tí wọ́n sì ń gba dúkìá wọn. Ó ní láàrin oṣù Kẹwàá sí oṣù Kejìlá, ọdún 2023 nìkan, àwọn èèyàn Mọdákẹ́kẹ́ gba abúlé Toro, Yekere, Alápẹ, tí wọ́n sì yí orúkọ wọn padà kúrò ni Ifẹ̀ sí Mọdákẹ́kẹ́.

Ademuyiwa sọ síwájú pé yíyọ tí ẹkùn àwọn ń yọ, bíi ti ojo kọ́ o, ìwà sùúrù tí Ọọ̀ni Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi ní ló ń ká àwọn lápá kò. Wọ́n wáá ké sì ìjọba láti tètè wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ náà.

Ṣùgbọ́n nígbà tó ń fún àwọn ‘Ifẹ Intellectuals’ lésì, Alága ẹgbẹ́ Mọdakẹkẹ Think Tank (MTT), Olóyè Kọla Ọlabisi àti Akọ̀wé, Ọ̀gbẹ́ni Fẹmi Ọladoṣu, sọ pé irọ́ tó jìnnà sóòọ́tọ́ ni gbogbo nǹkan tí ẹgbẹ́ náà n gbé pòòyì ẹnu.

MTT ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ wọn kò yàtọ̀ sí ti ẹni tó fẹ́ gba ogún ológún (sweat) mọ́ tiẹ̀ tó wá ń wá àtamọ́ mọ́ àtamọ̀ láti fi ọ̀nà èrú gba nǹkan tí kì í ṣe tirẹ̀. Ó ní gbogbo àwọn tí inú wọn kò dùn sí lfẹ̀ àti ìṣọ̀kan tó wà láàrin ìlú Ifẹ àti Mọdákẹ́kẹ́ báyìí ní wọ́n ń dáná ọ̀tẹ̀.

Ẹgbẹ́ náà sọ síwájú pé bí èdè àìyedè bá wà láàrin àwọn kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Iléefẹ̀ àti Mọdákẹ́kẹ́, kò lẹ́tọ̀ọ́ kí wọ́n so irunmú pọ̀ mọ́ tìpàkọ́, ẹni tí wọ́n bá jọ ń fa wàhálà ni kí wọ́n jọ dojú kọ ara wọn.

Wọ́n wáá ké sí ọ̀ga àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lórílẹ̀-èdè yìí láti pàṣẹ fún kọmíṣánnà ọlọ́pàá l’Ọ́ṣun láti ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, láti ṣàwárí àwọn agbátẹrù àti aríjẹ-nídìí-mọ̀dàrú tí wọ́n ń pọnmi òkè rú todò , tí wọ́n sì ń pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé lẹ́kun láàrin ìlú méjèèjì.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here