Kò sí mò̩dàrú nínú ipò Olúbàdàn – Seyi Makinde
Fẹmi Akínṣọlá
Báakú làá dère, èèyàn ò sunwọ̀n láàyè.
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ , Seyi Makinde, ti kéde ìpapòdà Olúbàdàn kejiìlélógójí ti ilẹ̀ Ìbàdàn, Kábíyèsí alá yélúwa, Ọba Dr. Moshood Lekan Balogun Alli Okunmade Kejì.
Gómìnà Mákindé kéde èyí nínú àtẹjáde kan ti ó buwọ́lù ni alẹ́ Ọjọ́bọ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹta ọdún yìí.
Àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé wí pé Kábíyèsí darapọ̀ mọ́ àwọn baba ńlá rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́bọ̀ ní ilé ìwòsàn UCH ti ìlú Ìbàdàn.
Gómìnà Makinde ṣàpèjúwe Ọba Balogun gẹ́gẹ́ bí èèyàn tí iwa rẹ wu ni lórí púpọ̀.
Bákan náà ló ní Balógun ṣe iṣẹ tó lààmì-laaka ní ilẹ̀ Ìbàdàn láàrin Ọdún méjì tó lò lórí àlééfà gẹ́gẹ́ bí Olúbàdàn.
Mákindé nínú ìwé ìkẹ̀dun rẹ́, kí ìgbìmọ̀ àpapọ̀ olóyè Olúbàdàn (Olubadan-in-Council) Ìgbìmọ̀ lọ́ba lọ́ba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, àwọn ará ìlú Ìbàdàn àti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lápapọ̀.
Nínú ọ̀rọ̀ ibanikẹdun rẹ̀, Makinde ṣàpèjúwe ìpapòdà Ọba Balogun gẹ́gẹ́ bí Ìrókò ńlá tó ṣubú.
Ó ní ìṣèjọba rẹ̀ fihàn wi pé ó ní ìrírí púpọ̀ eléyìí tí ó sì jẹ́ kó tayọ nínú àwọn Ọba tó ti jẹ ṣaájú ni ilẹ̀ Ìbàdàn.
Ó kí ìdílé Ọba Mashood Lekan Balogun kú ara fẹ́raku, tó sì gbàdúrà pé kí Ọlọrun forí jin àṣìṣe Kábíyèsí ọ̀hún.
Ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin ni Kábíyèsí lò láyé, kí wọ́n tó gbeṣẹ̀`.
Ẹ̀wẹ̀, a ti gbọ́ pé ìsìnkú Ọba Balogun yóò wáyé ní ìlànà ẹlẹ́sìn mùsùlùmí lónìí ọjọ́ Ẹtì.
Olúbàdàn ṣẹ̀ṣẹ̀ lo ọdún méjì lóríi àlééfà ni kí ọlọ́jọ́ tó dé.
Mọ̀lẹ́bí kan tó fi ọ̀rọ̀ tó àwọn akọ̀ròyìn létí sọ pé, ní agboolé Olúbàdàn ní Alli-Iwo, ni ìsìnkú náà yóó ti wáyé láago mẹ́rin ọ̀san.
Ọ̀pọ̀ ọmọ, ìyàwó àti ọmọ ọmọ ló gbẹ́yìn Olúbàdàn.