Awuyewuye bẹ́ sílẹ̀ lórí àyípadà orúkọ pápákọ̀ òfurufú Minna s’órúkọ Tinubu
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kẹta ọdún 2024 ni ààrẹ Bola Tinubu ṣe àbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Niger láti ṣe ìfilọ́lẹ̀ àtúnṣe pápákọ̀ òfurufú èyí tí ìjọba ìpínlẹ̀ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ṣe, tí wọ́n sì sọ ní orúkọ rẹ̀.
Tinubu yóò tún ṣe ìfilọ́lẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe ètò ọ̀gbìn Niger State Agricultural Revolution Project àti ẹ̀ka ètò Hajj ní pápákọ̀ òfurufú náà.
Àmọ́ ṣíṣe àyípadà orúkọ pápákọ̀ òfurufú ìpínlẹ̀ Niger sí orúkọ ààrẹ ló ti ń fa awuyewuye, tí àwọn èèyàn sì ń bèèrè pé kí ló dé tí ìjọba fi ń pààrọ̀ orúkọ pápákọ̀ òfurufú náà.
‘Dr Abubakar Imam Kagara International Airport’ ni orúkọ pápákọ̀ òfurufú náà ṣáájú kí wọ́n tó yí orúkọ rẹ̀ padà.
Dókítà Abubakar Kagara ló jẹ́ ògbóǹtarigì akọ̀wé àti akọ̀ròyìn tó kọ́kọ́ kọ ìwé ìròyìn ní èdè Haúsá “Gaskiya Ta Fi Kwabo” ní ọdún 1939.
Abubakar Kagara jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òǹkọ̀wé ní ẹkùn árìwá Nàìjíríà tí ipa tí ó kó nínú ìdàgbàsókè èdè Haúsá kò kéré rárá.
Ìbéèrè tí àwọn lámèyítọ́ ń bèèrè ni pé kí ló dé tí wọ́n fẹ́ yọ orúkọ ẹni tó ti ṣiṣẹ́ takuntakun bíi ti Kagara kúrò lára pápákọ̀ òfurufú náà.
Onímọ̀ nípa ètò òṣèlú kan tí kò fẹ́ kí wọ́n dárúkọ òun sọ fún akọroyin pé tó bá jẹ́ òun ni ààrẹ Tinubu ni, òun kò ní gbà kí wọ́n ṣe àyípadà orúkọ náà sí orúkọ òun.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Niger, Mohammed Umar Bago sọ pé ìdí tí àwọn fi pààrọ̀ orúkọ náà ni láti mọrírì ipa tí Tinubu ti kó sí ìdàgbàsókè Niger, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti ilẹ̀ Adúláwọ̀ lápapọ̀ lẹ́nu ìgbà tó gba àkóso ìjọba Nàìjíríà.
Àmọ́ onímọ̀ náà ní ó yẹ kí gómìnà Bago ṣe àkànṣe iṣẹ́ ńlá kan gbòógì tó máa sọ ní orúkọ ààrẹ.
Pípáàrọ̀ orúkọ ní ẹ̀ẹmèjì láàárín ọdún kan.
Kò ì tíì pé ọdún kan, ní ọjọ́ kìíní ọdún 2023 ni Iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìrìnnà òfurufú gbé àtẹ̀jáde kan jáde pé àwọn máa ṣe àyípadà orúkọ pápákọ̀ òfurufú Minna International Airport àtàwọn pápákọ̀ òfurufú mẹ́rìnlá mìíràn ní Nàìjíríà.
Nínú àtẹ̀jáde náà ni wọ́n ti kéde pé pápákọ̀ òfurufú Maiduguri ni àwọn ti yí orúkọ rẹ̀ padà sí pápákọ̀ Muhammadu Buhari tó jẹ́ orúkọ ààrẹ àná ní Nàìjíríà.
Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n yí orúkọ pápákọ̀ òfurufú ìpínlẹ̀ Ebonyi ní ìlà oòrùn gúúsù Nàìjíríà padà sí orúkọ ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní ilé aṣòfin àgbà, Chuba Okadigbo.
“Kí ni ìdí tí wọ́n fẹ́ fi yí orúkọ pápákọ̀ òfurufú náà padà láì tíì pé ọdún kan tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ sẹ́yìn? Kí ni ipa tí yíyí orúkọ náà padà yóò ní lórí ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Niger? Èyí ni ìbéèrè tí onímọ̀ náà ń bèèrè nígbà tó ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Niger ní àwọn ti sọ ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ìpínlẹ̀ náà kan tó wà ní Zungeru ní orúkọ Dókítà Kagara nítorí ilé ẹ̀kọ́ náà bá iṣẹ́ rẹ̀ mu.
Ẹ̀wẹ̀, yàtọ̀ sí awuyewuye tó ń wáyé látàrí àyípadà orúkọ náà, Tinubu yóò tún ṣe ìfilọ́lẹ̀ àkànṣe ètò ọ̀gbìn kan ní ìpínlẹ̀ Niger.
Gómìnà Umaru Bago ti máa ń sọ wí pé ìpínlẹ̀ Niger yóò tó máa pèsè oúnjẹ tí yóò tó wọn jẹ ní ìpínlẹ̀ náà.
Àkànṣe ètò ọ̀gbìn náà tí wọ́n fi lọ́lẹ̀ náà ni Total Agricultural Support Programme (TASP) èyí tó jẹ́ àjọṣepọ̀ pẹ̀lú iléeṣẹ́ Brazil kan.
Wọ́n ní ìrètí wà pé ètò náà yóò pọnkún ìpèsè oúnjẹ àti iṣẹ́ fún àwọn aráàlú.