Ìgbìmọ̀ àpapọ̀ ọba níìpínlẹ̀ ògùn ní kí Olú Owódé lọ rọọ́kún nílé

Ìgbìmọ̀ àpapọ̀ ọba níìpínlẹ̀ ògùn ní kí Olú Owódé lọ rọọ́kún nílé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀,wọ́n ní bí a bá ṣòògùn ẹ̀tẹ̀ ,ọmọ ìyà ẹni la fi í dánwò, kí ọmọ baba le ròyìn ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù.
Ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba ní ìpínlẹ̀ Ògùn, ní abẹ́ adarí Aláké ti ìlú Ẹ̀gbá, Ọba Adédòtun Àrèmú Gbádébọ̀ ti ní kí Ọba Kọ́láwọlé Sówèmímó, Olú Owódé ti ìlú Owódé lọ rọọ́kún nílé fún oṣù Méjì.

Ìgbésẹ̀ yìí wáyé lẹ́yìn àsìkò díẹ̀ tí Ọba Sówèmímọ́ fi owó kọ́ ọrùn olórin Fújì, Wàsíù Àyìndé níta gbangba níbi ayẹyẹ kan.

Ìfofin de Ọba Sówèmímó náà wáyé lẹyìn ìpàdé olóoṣoṣù tí ìgbìmọ̀ àwọn lọ́balọ́ba ìpínlẹ̀ náà lọ́jọ́ Ẹtì.

Alága ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba náà, Olówu tí ìlú Òwu, Ọba Ọ̀jọ̀gbọ́n Saka Matemilola ní fífi òfin de Ọba náà wáyé lẹ́yìn tí àwọn Ọba ti gbé aṣemáṣe tí Ọba náà ṣe yẹ̀wò.

Olówu ní aṣemáṣe náà lòdì sí ìwà àwọn ọba nípínlẹ̀ Ògùn àti sí àṣà ilẹ̀ Yorùbá.

Nínú ọ̀rọ̀ tó bá akọròyìn sọ, Oba Kọ́láwọlé Sówèmímó ní òun gbà pé òun jẹ̀bi.

Ó ni òun kò mọ̀ pé ìwà bẹ́ẹ̀ kò dáára gẹ́gẹ́ bí ọba.

Ọba Kọ́láwọlé Sówèmímó ní òun faramọ́ ìdánidúró olóṣù méjì náà àti pé òun tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ gbogbo ìgbìmọ̀ àwọn lọ́balọ́ba nípínlẹ̀ Ògùn àti Ẹ̀gbá lápapọ̀ lórí ìwà tí òun hù.

Bákan náà ló bẹ àwọn ọmọ Nàíjíríà láti máa bínú sí ìwà ìbàjẹ́ tí òun ṣe.

Ó ṣàlàyé pé ” Ìpinu àwọn ìgbìmọ̀ tẹ́lẹ̀ ni láti dá òun dúró fún oṣù mẹ́ta nítorí bí òun ṣe ná owó fún eléré kan. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bi òun léèrè pé kí ni òun ní láti sọ, ó ní òun mọ̀; òun sì gbà pé òun jẹbi, ìdí rèé tí wọn fi din ìrọ́ọ́kún nílé òun kù sí oṣù méjì”.

“Ọba Sówèmímọ́ ní òun kò ní nǹkan láti sọ, ju pé ọmọ tí a bá nífẹ̀ sí ni a má ń bá wí. Ó ní ohun tí àwọn ìgbìmọ̀ Ọba sọ ní òun tẹ̀lé.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here