Àwọn Olùwóde nílùú Ìbàdàn ṣe ìfẹ̀hónúhàn alátakò sí ìlérí Ààrẹ Tinubú

Àwọn Olùwóde nílùú Ìbàdàn ṣe ìfẹ̀hónúhàn alátakò sí ìlérí Ààrẹ Tinubú

Ọlámídé Motúnráyọ̀

Ní Ọjọ́ Ajé Mọ́ńdè ọ̀ṣẹ̀ yìí, àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn nílùú Ìbàdàn ló tú síta láti ṣe ìwọ́de fi tako bí ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ ṣe gbòde káàkiri lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà. Ìwọ́de yìí kìí ṣe àkọ́kọ́, irúfẹ́ ìwọ́de yìí ti wáyé ní àwọn ìpínlẹ̀ bíi Niger àti Kano nínú oṣù yìí.

Ìwọ́de náà bẹ̀rẹ̀ ní agbègbè Mọ́kọ́lá nílùú Ìbàdàn si àwọn agbègbè mìí ní ìrètí pé ohùn wọn yóò dé òkè lọ́dọ̀ Ìjọba.

Ariwo ebi wà ní ìlú, ebi ń pa wá ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aráàlú mú bọ ẹnu, tí wọ́n sì ń nàka àbùkù sí Ààrẹ Bọ́lá Ahmed Tinubú pé ìlérí tó ṣe lásìkò ìpolongo ṣáájú ètò ìdìbò fún àwọn aráàlú kọ́ ló ń mú wá sí ìmúsẹ yìí. Bákan náà, ni wọ́n jẹ́ kó yé ìjọba pé ìfọ̀kànbalẹ̀ kò sí mọ́ nítorí ebi ti fẹ́ ṣe wọn lése.

Wọ́n lọgun pé gbogbo ìgbésẹ ìjọba Tinubú ló mú ìnira dání, tí kò sì fi ibi kankan tẹ́ aráàlú lọ́rùn láti ìgbà tó ti bọ́ sórí àlééfà ni ìnira, ebi, àti àìríjẹ ti dé”

Ọ̀kan lára àwọn olùfẹ̀hónùhàn sọ pé ìlérí tí ìjọba tí a dìbò fún ṣe ni pé àwọn yóò ran ará ìlú lọ́wọ́, wọn yóò sì sa gbogbo agbára wọn láti mú inú àwọn èèyàn dùn ṣùgbọ́n ó ṣe ni láànú pé láti ìgbà tí ìjọba yìí ti bọ́ sórí àlééfà níbí oṣù mẹjọ díẹ̀ sẹ́yìn ni ìnira, ebi, àìríjẹ ti bá aráàlú.

Olùfẹ̀húnúhàn mìí sọ pé “ìlànà tuntun tí ìjọba gbé wá báyìí ń mú ara ni aráàlú. Ó tẹ̀síwájú láti sàlàyé pé “Òṣìṣẹ́ ìjọba ni òun, tí òun sì wà ní ipele Kejìlá, àmọ́ tí òun kò ní nǹkan rere tí òun lè tọ́ka sí látàrí bí nǹkan ṣe gbówólórí ti ó sì le koko. Ó fi Bàbá rẹ̀ sàkàwé, ó ní nígbà tí ayé rọrùn fún mùtúmùwà tí Bàbá òun wà ní ipele kẹwàá lẹ́nu iṣẹ́ ni ó tí gbé nǹkan rere ṣe.”

Olùfẹ́húnúhan mìíràn ní gbogbo oúnjẹ pátá ló ti gbé owó lórí, tí ara sì ń ni gbogbo aráàlú lásìkò ìjọba yìí. Ó fẹ̀sùn kan ìjọba pé lásìkò tí wọ́n ṣe ìponlogo, wọn kò sọ pé bi nǹkan yóò ṣe rí rèé.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here